Sikiru Ayinde Barrister, Barry wonder gbajúmọ̀ olórin Fuji tó ṣiṣẹ́ sọ́jà, tẹ̀wé-tẹ̀wé àti akọ̀wé iléèṣẹ́

Sikiru Ayinde Barrister ṣiṣẹ ologun, ko to o di olorin Fuji patapata. Koda, o ja nibi ogun Biafra.

Oríṣun àwòrán, Twitter/@AyindeBarrister

Iku n pani, ilẹ n jẹyan. Oni lo pe ọdun mẹwaa geerege ti ilumọọka olorin Fuji, Alhaji Sikiru Ololade Ayinde Balogun Barrister jade laye.

Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kejila, ọdun 2010 ni Barrister dagbere faye ni ile iwosan kan nilu London.

Ẹbi. ọrẹ ati awọn ololufẹ rẹ ni wọn n ṣeranti Barrister lonii.

Ibẹrẹ igbe aye Sikiru Ayinde Barrister?

Ogbeni Salawu Balogun, alapata ẹran lo jẹ baba to bi Sikiru Ayinde Barrister nigba ti iya rẹ jẹ oniṣowo pẹẹpẹẹpẹ.

Wọ̀n bi Barrister ni ọjọ kẹsan-an, oṣu Keji, ọdun 1948 sinu ẹbi Salawu Balogun nilu Ibadan.

Iṣẹ alapata ẹran ni baba rẹ n ṣe, iya rẹ si jẹ oniṣowo.

Àkọlé fídíò, Barister lo bi gbogbo oníṣẹ́ fújì -Oṣupa

Sikiru Ayinde lọ si ile ẹkọ alakọbẹrẹ Muslim Mission School, ati Model School ni Mushin, nipinlẹ Eko.

Lẹyin naa lo k nipa bi iwe titẹ ati awọn iṣẹ ọfiisi mii nile ẹkọ giga Yaba Polytechnic.

Lati ọdọ ni Ayinde Barrister ti bẹrẹ orin kikọ pẹlu ẹka ori 'Were'. Asiko awẹ Ramadan ni wọn ma n kọ iru orin yii lati ile kan si ile mii.

Sikiru Ayinde Barrister ṣiṣẹ ologun, ko to o di olorin Fuji patapata. Koda, o ja nibi ogun Biafra.

Oríṣun àwòrán, Twitter/@AyindeBarrister

O siṣẹ atẹwe nileeṣẹ to n ṣe ọti, Nigeria Breweries. Lẹyin naa lo ṣiṣẹ akọwe nileeṣẹ ologun Naijiria lasiko ogun abẹle.

O jẹ ọmọ ogun labẹ idari Ọgagun Adeniran, o si jagun nilu Akwa, Abagana ati Onitsha.

Nigba to pada de lati oju ogun, wọn gbe e lọ si olu ileeṣẹ ologun to n ṣe ifimufinlẹ, ni Apapa nilu Eko, ko to o tun lọ si Army Resettlement Centre ni Oshodi.

O kuro ninu iṣẹ ologun, lo fi di olorin Fuji patapata, to si da ẹgbẹ akọrin rẹ 'Supreme Fuji Commanders' silẹ.

Irianajo rẹ gẹgẹ bi olorin Fuji

Lọdun 1966, Sikiri ayinde Barrister gbe rẹkọọdu orin rẹ akọkọ jade. Lasiko naa, ibi ariya ni oun ati awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ ti ma n kọrin ni awọn agbegbe Ebute Meta, ati fun awọn ololufẹ rẹ ni Mushin.

Ayinde Barrister lasiko to n kọrin nibi ariya kan nilu Eko lọdun 1976. Ololufẹ rẹ kan si n na a lowo loju agbo.

Oríṣun àwòrán, Twitter/@AyindeBarrister

Àkọlé àwòrán, Ayinde Barrister lasiko to n kọrin nibi ariya kan nilu Eko lọdun 1976. Ololufẹ rẹ kan si n na a lowo loju agbo.

O pada gbe awọn rẹkọọdu mii jade labẹ ileeṣẹ African Songs Ltd, ko to o da ileeṣẹ ti ẹ, Silky-Oluyole Records, silẹ.

Nigba ti yoo fi di ọdun 1980, Ayinde Barrister ati orin Fuji ti di itẹwọgba laarin gbogbo ẹsin to wa ni Naijiria.

Lọdun 1982, ija nla waye laarin Kollington Ayinla, to jẹ ọrẹ rẹ, ati olorin Fuji mii.

Ọrẹ ni Ayinde Barrister ati Ayinla Kollington nigba aye rẹ.

Oríṣun àwòrán, Twitter/@AyindeBarrister

Àkọlé àwòrán, Ọrẹ ni Ayinde Barrister ati Ayinla Kollington nigba aye rẹ.

Barrister gbe orin kikọ de ilẹ okeere, to si ṣe ariya ita gbangba ni awọn ilu bi London lọdun 1990 ati 1993. Eyi lo bi orin Fuji Garbage.

Orin Fuji ti Sikiri Ayinde Barrister kọ nigba aye rẹ jẹ akojọpọ Apala, Sakara, Awurebe ati awọn mii.

Aworan yii ṣafihan Ayinde Barrister nibi ayẹyẹ to ti gba ade gẹgẹ bi olorin Fuji to dara julọ lọdun 1977. Ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ni lasiko naa.

Oríṣun àwòrán, Twitter/@AyindeBarrister

Àkọlé àwòrán, Aworan yii ṣafihan Ayinde Barrister nibi ayẹyẹ to ti gba ade gẹgẹ bi olorin Fuji to dara julọ lọdun 1977. Ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ni lasiko naa.

Orin rẹ si ma n da lori aṣa, ikilọ iwa, ibọwọ f'agba, oṣelu ati igbokegbodo eeyan laye.

O si tun ma n fi orin ki awọn gbajumọ ni awujọ.

Ọpọlọpọ ami idanilọla ni Ayinde Barrister gba fun iṣẹ orin kikọ. Lara wọn ni idanilọla pẹlu Member of the Order of the Federal Republic (MFR), ti Aarẹ Olusegun Obasanjo fun lọdun 2006.

Awọn rẹkọọdun orin ti Sikiru Ayinde Barrister gbe jade nigba aye rẹ ni

  • Ejeka Gbo T'Olorun (1966)
  • Vol.1: Waya Rabi
  • Vol.2: Alayinde Ma De O
  • Vol.3: Mecca Special
  • Vol.4: Itan Anobi Rasao
  • Vol.5: E Sa Ma Mi Lengbe
  • Vol.6: Ori Mi Ewo Ninse / Majority Boy (1975)
  • Vol.7: Ile Aiye Dun Pupo / Love In Tokyo (India Sound) (1975)
  • Vol.8: Fuji Exponent (1976)
  • Vol.9
Sikiru Ayinde Barrister ṣiṣẹ ologun, ko to o di olorin Fuji patapata. Koda, o ja nibi ogun Biafra.

Oríṣun àwòrán, Twitter/@AyindeBarrister

Àkọlé àwòrán, Sikiru Ayinde Barrister ṣiṣẹ ologun, ko to o di olorin Fuji patapata. Koda, o ja nibi ogun Biafra.
  • Vol. 10 (African Songs, 1977)
  • Bisimilai (African Songs, 1977)
  • Omo Nigeria (African Songs, 1977)
  • Olojo Eni Mojuba (Siky Oluyole, 1978)
  • Our Late Artistes (Siky Oluyole, 1978)
  • London Special (Siky Oluyole, 1979)
  • Fuji Reggae Series 2 (Siky Oluyole, 1979)
  • Eyo Nbo Anobi (Siky Oluyole, 1979)
  • Awa O Ja (Siky Oluyole, 1979)
  • Fuji Disco (Siky Oluyole, 1980)
  • Oke Agba (Siky Oluyole, 1980)
  • Aiye (Siky Oluyole, 1980)
  • Family Planning (Siky Oluyole, 1981)
  • Suru Baba Iwa (Siky Oluyole, 1981)
  • Ore Lope (Siky Oluyole, 1981)
  • E Sinmi Rascality (Siky Oluyole, 1982)
  • Iwa (Siky Oluyole, 1982)
  • Ise Logun Ise (No More War) (Siky Oluyole, 1982)
  • Eku Odun (Siky Oluyole, 1982)
  • Ijo Olomo (Siky Oluyole, 1983)
  • Nigeria (Siky Oluyole, 1983)
  • Love (Siky Oluyole, 1983)
Àkọlé fídíò, Florence Onwuasoanya: Mo jẹ́ àsèjẹ, mo mu àgbo tí kò ṣe e fẹnu sọ kí ń lè gbé ọmọ jó ṣùgbọ
  • Barry Special (Siky Oluyole, 1983)
  • Military (Siky Oluyole, 1984)
  • Appreciation (Siky Oluyole, 1984)
  • Fuji Vibration 84/85 (Siky Oluyole, 1984)
  • Destiny (Siky Oluyole, 1985)
  • Superiority (Siky Oluyole, 1985)
  • Fertiliser (Siky Oluyole, 1985)
  • Okiki (Siky Oluyole, 1986)
  • Inferno(Siky Oluyole, 1996)
  • America Special (Siky Oluyole, 1986)
  • Ile Aye Ogun (Siky Oluyole, 1987)
  • Maturity (Siky Oluyole, 1987)
  • Barry Wonder (Siky Oluyole, 1987)
  • Wonders At 40 (Siky Oluyole, 1988)
  • Fuji Garbage (Siky Oluyole, 1988)
Àkọlé fídíò, Africa Eye: Wo ìtàn ìyá kan ìyá kan àtàwọn olè ajọ́mọgbé tó n ta ọmọ ní Kenya
  • Fuji Garbage Series II (Siky Oluyole, 1988)
  • Current Affairs (Siky Oluyole, 1989)
  • Fuji Garbage Series III (Siky Oluyole, 1989)
  • Music Extravaganza (Siky Oluyole, 1990)
  • Fuji Waves (Siky Oluyole, 1991)
  • Fantasia Fuji (Siky Oluyole, 1991)
  • Fuji Explosion (Siky Oluyole, 1992)
  • Dimensional Fuji (Siky Oluyole, 1993)
  • New Fuji Garbage (Siky Oluyole, 1993)
  • The Truth (Siky Oluyole, 1994)
  • Precaution (Siky Oluyole, 1995)
Àkọlé fídíò, Kollington ṣàlàyé bí orin Fuji ṣe bẹ̀rẹ̀ gan an ní Nàiìjíríà
  • Olympics Atlanta '96 cassette (Siky Oluyole, 1996)
  • Olympics '96 London Version cassette (Zmirage Productions, 1997)
  • with Queen Salawa Abeni Evening Of Sound cassette (Zmirage Productions, 1997)
  • Barry On Stage cassette (Siky Oluyole, 1997)
  • Mr. Fuji (Barry Black, 1998)
  • "Millennium Stanza" (Fuji Chambers, 2000)
  • "Controversy" (2005)
  • ' REALITY ' ( 2008).
  • Superiority

A ko le sọ daju pe gbogbo orin to kọ niyii. O ṣe e ṣe ki awọn mii wa ti a ko mọ.