Abass Akande: Obesere lóun ló kàn lẹ́yìn olóògbé Barrister àti Kollington nínú iṣẹ́ orin Fuji

Abass Akande Obesere

Oríṣun àwòrán, Facebook/Abass Akande Obesere

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajugbaja olorin Fuji, Abass Akande ti ọpọ mọ si Obesere ti ja gudugbẹ ọrọ lulẹ lori eto ori redio kan niluu Ibadan, nipinlẹ Oyo.

Ninu ifọrọwerọ lori eto redio ọhun ni Obesere ti sọ pe oloogbe Sikiru Ayinde Barrister ati Alhaji Ayinla Kollington nikan lo jẹ baba fun oun ninu iṣẹ orin Fuji.

Obesere sọ pe oun gan an ni ipo agba ninu orin Fuji kan lẹyin oloogbe Barrister ati Kollington.

Abasido gẹgẹ bi orukọ inagijẹ rẹ mii ṣalaye pe Eleduwa da oun gẹgẹ bi ọga, o ni bakan naa si ni Oba Aṣẹda fi ohun ti oun yoo maa fi ṣe ipo olori jinki oun.

''Mo le bura pe were kan lo kilọ fun mi lọjọ ti mo fẹ gba pe ẹni to wa lẹyin mi ju mi lọ. Were naa n rin lọ loju titi nigba to sọ fun mi pe n o gbọdọ gba, ọdun 2007 lọrọ yii ṣẹlẹ,'' Obesere lo sọ bẹẹ.

O ṣalaye pe oun ko kọkọ fẹ gba ipo ọba orin Fuji nitori ede-ai-yede to wa laarin awọn olorin ṣugbọn oun gbaa lẹyin ti oun tun ero pa lori rẹ.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Nigba to sọrọ lori igba to bẹrẹ ere Fuji, o ni lọdun 1983 iyẹn bi ọdun mẹtadinlogoji sẹyin loun bẹrẹ si ni maa ri owo nibi iṣẹ orin Fuji.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Obesere ko ṣai sọ nipa oba orin oloogbe Ayinde Barrister, o ni Sikiru Ayinde ti papoda ni tootọọ ṣugbọn orukọ rẹ ko le parun laelae.

''Ko tiẹ dabi ẹni pe Barrister tiẹ ku rara, nitori gbogbo igba laye si n gbọ orukọ rẹ,'' Obesere lo woye bẹẹ.

O ni oun ti n ṣe akitiyan pẹlu awọn eeyan mii lati gbe eto kan kalẹ lati maa fi ṣe iranti oloogbe Barrister gẹgẹ bi eto ti wọn maa fi n ranti olorin Afro, Fela Anikulapo Kuti lọdọọdun.

Obesere tun mẹnu ba awo rẹ to jade laipẹ to pe akori rẹ ni ''Standout,'' o ṣalaye pe oṣu meje gbako loun fi ṣiṣẹ lori awo naa.

Skip Instagram post, 3
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 3

''Lasiko konle o gbele coronavirus ni mo bẹrẹ iṣẹ lori awo naa tori mo mọ pe awọn eeyan yoo mujo jo lẹyin ti covid-19 ba kasẹ nilẹ,'' Obesere lo sọ bẹẹ.

Ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu keje ọdun 2020 yii ni Obesere gbe awo orin ọhun jade.