Pasuma: Ọ̀gáńlá Fújì ní ominú ń kọ òun lórí ọ̀dá àwọn ìràwọ̀ tuntun lágbo orin Fújì

Wasiu alabi pasuma

Oríṣun àwòrán, Wasiu alabi pasuma/instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Gbajugbaja akọrin Fuji ni, Alhaji Wasiu Alabi ti ọpọ eeyan mọ si Pasuma Wonder, iba wasi baba baraka ti ṣalaye pe ọrọ iyawo nini fun oun kii ṣe afi waduwadu ṣe o.

Alhaji Pasuma ṣalaye pe idi ti oun ko tii fi ni iyawo lọwọ yii naa ni pe oun fẹ ṣe ohun gbogbo bi o ti yẹ ko le baa ri bose yẹ ko ri.

Paso ni ohun lawọn obinrin to bimọ fun oun o, ṣugbọn ọrọ iyawo afẹsile ko tii yọ fun oun bayii.

Ọganla Fuji ni nigba to ba ya oun yoo niyawo ṣugbọn suuru lo gba.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba ni Ba wasi ti sọ ọrọ yii.

Bakan naa lo sọrọ lori ahesọ ọrọ to n wi pe ọjọṣepọ ifẹ n bẹ laarin oun ati gbajumọ oṣere tiata, Jaiye Kuti.

Pasuma ni ere tiata lo da awọn mejeeji pọ.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Bakan naa lo fi kun un pe ọrẹ lasan loun ati gbajugbaja oṣere tiata, Ronkẹ Ididowo ti ko si si ohun ifẹ ikọkọ kankan to pa wọn pọ.

Bakan naa lo kọminu lori ọda awọn irawọ tuntun lagbo fuji.

O ni ohun to mi oun lọkan ni bi o ṣe jẹ pe awọn ọdọ olorin ko fẹ kọ orin Fuji mọ bi ko ṣe orin takasufe, HipHop.

O fi kun un pe oun yoo sa ipa oun gẹgẹ bii aṣiwaju lati mu idagbasoke ba awọn ọdọ to ba fẹ yan orin Fuji laayo