Ember Month Security: Ọwọ́ pálábá àwọn ọmọ ẹlégbẹ́ òkùnkùn 15 ségí ní ìpínlẹ̀ Eko

Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn ko

Oríṣun àwòrán, Lagos Police

Ijọba ipinlẹ Eko ni ọwọ awọn ti tẹ awọn ọdaran ti wọn n da agbegbe Ikorodu ati Lekki/Ajah laamu nipinlẹ Eko.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Olumuyiwa Adejobi, ninu atẹjade to fi lede naa ni ikọ ọlọpaa to wa ni Ikorodu lo mu awọn ọdaran naa.

Adejobi ni ohun to ṣẹlẹ ni wi pe araalu kan lo ji pe awọn ọlọpaa ni aago mẹrin owurọ lati agbegbe Agunfoye,

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba ti ikọ ọlọpaa Ikorodu yoo fi de ibẹ ni ọwọ tẹ arakunrin Taiye Lasisi, ti wọn mu pẹlu ibọn ilewọ lọwọ rẹ.

Lẹyin ti ọlọpaa fi panpẹ mu tan ni wọn tu gbogbo agbegbe naa yẹbẹ yẹbẹ, ti ọwọ si tẹ awọn yoo ku.

Lara awọn mẹtala ti wọn mu naa jẹ awọn ẹlẹgbẹ okunkun Aiye, ti wọn si wọn si ti gbe wọn lọ si atimọle.

Ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn ko

Oríṣun àwòrán, Lagos Police

Bakan naa ni wọn ri awọn ohun ini gba lọwọ wọn bi ẹrọ ilewọ ati awọn ohun ini miran.

Ninu ọrọ tirẹ, Kọmisọnnna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa, ati wi pe awọn ko ni fi aye gba iwa ipa ati iwa ọdaran kankan nipinlẹ Eko.

Ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ méjì fìjà pẹẹ́ta, ẹ̀mí kan bọ́, ọ̀pọ̀ farapa

Ìjà kan to waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ meji nilu Ejigbo ti ṣokunfa iku arakunrin kan, Abeeb Abifarin ti agboole Oke Dada nilu Ejigbo nipinlẹ Osun.

Awọn ọlọpaa nilu Ondo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lọjọ isegun ni o padanu emi rẹ ninu ìjà yọbẹ y'ada laarin awọn ẹgbẹ meji nilu naa.

Bakan naa la gbọ pe ọpọ eeyan lo farapa ninu ìjà yii, tó bẹrẹ ni irọlẹ ọjọ Aje ladugbo Ori Eru laarin awọn ọmọ ẹgbẹ Lion Base Club, ti agboole Olukola ati awọn ti Isalẹ Agooji Club.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ohun taa gbọ ni pe, wọn yìnbon pa Abeeb bí ọwọ agọ meje kú iṣẹju mẹẹdogun aṣalẹ ọjọ Aje nigba ti ìjà yi bẹ sílẹ.

Awọn kan ti ọrọ naa soju ni, wọn ge apa rẹ jabọ ninu ikọlu yi.

Àdá, àáké, ati fila pupa jẹ́ diẹ lara ami idanimọ awọn ẹgbẹ okunkun ni Naijiria
Àkọlé àwòrán, Àdá, àáké, ati fila pupa jẹ́ diẹ lara ami idanimọ awọn ẹgbẹ okunkun ni Naijiria

Ara adugbo naa kan to ba awọn akọroyin sọrọ, ṣugbọn ti ko fẹ ki wọn darukọ rẹ sọ pe, ọkunrin kan t'awọn ko mọ orukọ rẹ naa tun ku lọjọ ìṣẹgun lẹyin t'awọn agbofinro pẹtu sí aawọ náà tan.

Amọ ṣa ileesẹ wa kò ti ribi fidi ọrọ bayi mu'lẹ.

Pupọ awon ilé ìtajà ni Ejigbo ni wọn sáré ti pa nitori wahala yii, ti won sì tun ti ileesẹ awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Ejigbo naa pa, ki awọn oṣiṣẹ pada sílé.

Àkọlé fídíò, 2020 in Retrospect: Ìjàmbá iná, ilé tó dàwó, ìwọ́de àti àrùn Covid-19 wà lára ìṣẹ̀lẹ̀ 2020

A tún padà gbọ pe awọn to dojú ìjà kọ ara wọn ọhun tun gbe ìjà wọn dé adugbo Sagan, Orieru, Port junction ati roundabout pẹlu nkan ija oloro titi di afẹmọju lojo Ìṣẹgun.

A kò tíì le sọ nkan to fa ìjà yi pato sugbọn finfinfin t'awọn akọroyin lagbegbe naa gbọ ni pe, owo ẹbùn ọdun to to ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira (N150,000) lo dá ìjà silẹ.

Ìdájọ́ ọwọ́ tó di lemọ́-lemọ́ n'Ibadan, ohun tó fà á rèé

eeyan kan gbe ibọn dani

Oríṣun àwòrán, Plustv africa

Ohun to n mu ki ọpọ eeyan maa dawọle idajọ ọwọ ara ẹni, taa mọ si Jungle Justice, ni ainigbagbọ to kuna ninu eto idajọ ododo ti ofin gbe kalẹ.

Eyi ni ọrọ Amofin Akeem Fadun, eekan agbẹjọro kan nilu Eko lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun to mu ki idajọ ọwọ lawujọ di lemọ-lemọ.

Kii ṣe ani-ani mọ pe awọn eeyan ni ipinlẹ Ọyọ n se gbọnmọgbọnmọ fifi idajọ afurasi sọwọ ara wọn, eleyi to si ti n kọ ọpọlọpọ eeyan ati awọn onwoye lominu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Laarin bi ọsẹ diẹ sẹyin bayii, ko din ni eeyan mẹfa ti awọn eeyan ti dana sun ninu isẹlẹ ọtọọtọ, tori pe wọn fura iwa aidaa kan tabi omiran si wọn.

Awọn adigunjale ti wọn ko ijamba ọkada

Oríṣun àwòrán, Tade Oludayo

Amofin Akeem Fadun ni ọpọ igba ni araalu maa mu ọdaran lọ si agọ ọlọpaa ṣugbọn to jẹ wi pe wọn yoo tun ri ọdaran bẹẹ nigboro lẹyin wakati tabi ọjọ diẹ.

Bakannaa lo tun pe fun eto ilanilọyẹ fun araalu lori ipenija ati ewu to wa lori idajọ ọwọ.

Eekan amofin naa fi kun un pe, ọdaran ni ẹnikẹni to ba lọwọ ninu iṣẹlẹ idajọ ọwọ labẹ ofin.

Awọn ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG

O ni nibi ti ọrọ de duro bayii, ijọba gbọdọ bẹrẹ si ni fi awọn to ba n lọwọ ninu iṣẹlẹ didana sun afurasi tabi idajọ ọwọ jofin, lati lee jẹ ifaleti fun awọn eeyan mii lọjọ miran.

Onimọ nipa ofin naa ko ṣai yannana rẹ pe, wahala iwọde #EndSARS to kọja laipẹ yii ti n fun awọn eeyan ni igboya lati hu awọn iwa kotọ.

"Wọn ti lero pe bi awọn ṣe parapọ ba ọpọ dukia jẹ, ti wọn si ṣe ọpọ iwa jagidijagan lasiko naa, ti ko si si ẹni to mu wọn sii, ni awọn ṣe lee maa hu iwa kotọ naa lọ.

Awọn eeyan to n se idajọ ọwọ

Oríṣun àwòrán, Abdulmumin Rabiu

Ijọba gbọdọ fi awọn eeyan jofin daadaa lori iwa aburu yii, lati jẹ ki araalu mọ pe iyatọ wa laarin kiko ara jọ pọ, ja fun ẹtọ labẹ ofin ati kiko ara jọ pọ hu iwa ọdaran."

Bakannaa ni Amofin Akeem Fadun tun mu aba wa pe, bi araalu ko ba ni igbagbọ ninu ilana idajọ lorilẹede yii, boya ki wọn maa gbe igbimọ kan kalẹ, lati maa tọpinpin bi awọn agbofinro ṣe n yanju awọn afurasi ti wọn ba gbe wa si ọdọ wọn.

Iha wo ni ijọba Oyo kọ si idajọ ọwọ to di lemọ-lemọ?

Ẹwẹ, nigba ti BBC News Yoruba kan si ijọba ipinlẹ Ọyọ, kọmiṣọna feto iroyin ati aṣa, Ọmọwe Wasiu Ọlatubọsun ṣalaye pe ijọba n gbe igbesẹ lati tubọ mu ki okun ati koriya wa fun awọn agbofinro lati ṣiṣẹ wọn.

Ọmọwe Wasiu Adewale Olatunbosun

Oríṣun àwòrán, Facebook/Dr. Wasiu Adewale Olatubosun

Ọmọwe Ọlatubosun ni itaniji ti bẹrẹ lori iwa kotọ yii, lati mu ki araalu mọ wahala to rọ mọ irufẹ iwa didana sun awọn afurasi.

Bakan naa lo tun rọ awọn ọlọpaa lati rii pe gbogbo afurasi ti wọn ba mu de ọdọ wọn, ni wọn foju wina ofin.

Adigunjalè méjì ko ìjàmbá ọ̀kadà lẹ́yìn ìṣẹ́ ibi n'Ibadan, ọ̀kan kú lójijì, aráàlú dáná sun èkejì

Yoruba ni ọjọ gbogbo ni ti ole, amọ ọjọ kan soso pere ni ti olohun.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa: Mọ̀ síi nípa ìró afárànma àti agbárànmọ́ fáwẹ́ẹ̀lì Yorùbá

Bẹẹ lọrọ ri fun awọn adigunjale meji kan lọjọru nilu Ibadan nigba ti wọn ja ọkunrin kan lole amọ ti ọwọ palaba wọn segi.

Atẹjade kan ti ileesẹ ọlọpa fisita lori isẹlẹ naa salaye pe deede aago mẹta aabọ irọlẹ ọjọru ni isẹlẹ naa waye si ọkunrin kan, ti wọn pe orukọ rẹ ni Tobi Adebayo, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn to wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bi ileesẹ ọlọpaa ti wi, adugbo Favours, lopopona Awolowo si Bodija nilu Ibadan ni awọn ọkunrin meji to wa lori ọkada ti sẹburu ọkọ Toyota Corolla rẹ, ti wọn si fi tipa gba foonu ati apo kan ti iwe wa ninu rẹ.

Amọ ẹnikan ti isẹlẹ naa soju rẹ ni owo to to miliọnu marun naira lo wa ninu apo naa, ti ọkunrin ọhun to jẹ olokoowo gbe lọwọ.

Atẹjade naa ni ni kete tawọn adigunjale naa sisẹ laabi ọhun tan, ni wọn fẹsẹ fẹ lori ọkada wọn amọ ti Adebayo atawọn araalu gba ya wọn pẹlu ọkọ rẹ titi to fi le wọn de adugbo dandaru.

Lojiji ni ọkada naa ja sinu koto nla kan, tawọn adigunjale naa si jabọ, bẹẹ ni ọkan ninu wọn dagbere faye loju ẹsẹ nigba ti ekeji fara gbọgbẹ, ti ara rẹ si bo falafala.

Atẹjade ileesẹ ọlọpaa naa ni, ni kete ti iroyin naa kan ọga ọlọpaa to wa ni agọ ọlọpaa Agodi lara lo morile ibi isẹlẹ naa amọ ko to de ibẹ, ẹpa ko boro mọ.

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Wo ìtàn ìyá kan ìyá kan àtàwọn olè ajọ́mọgbé tó n ta ọmọ ní Kenya

Idi ni pe awọn araalu tinu n bi, ti wọn le ni igba, ti dana sun adigunjale to fara gbọgbẹ naa, tawọn ọlọpaa si ti gbe ajoku rẹ lọ sile igbokusi.

Bakan naa ni ileesẹ ọlọpaa ni aayan ti n lọ lati tanna wadi isẹlẹ naa siwaju si.

Sugbọn isẹlẹ naa da sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ silẹ ladugbo dandaru si Mokola, tawọn osisẹ Amotekun naa si bawọn peju sibi isẹlẹ ọhun, bẹẹ ni wọn n dari ọkọ lagbegbe naa pẹlu lati dena sunkẹrẹ fakẹrẹ.

Ṣé lóòtọ́ọ́ làwọn ọlọ́ṣà tún gbẹ̀mí èèyàn kan ní Moniya, Ibadan?

Awọn igara ọlọṣa ti yinbọn pa ọkunrin ọlọdẹ kan lagbegbe Mọniya nilu Ibadan.

Arakunrin naa ti awọn ọlọpaa pe orukọ rẹ ni Isau Yisah ni wọn sọ wi pe o n ṣe ṣọ ile epo kan lagbegbe naa lasiko ti awọn ọlọṣa fi ya bo adugbo naa lọjọ Abamẹta.

Gẹgẹ bi ohun ti awọn iroyin kan sọ, awọn ọlọdẹ agbegbe naa, ninu eyi ti Yisah wa doju kọ awọn ọlọṣa naa ki o to di pe awọn ọlọṣaa naa pa Yisah lagbegbe Asanmajana ti ileepo naa wa.

Ohun ti awọn eeyan kan n sọ lagbegbe naa ni pe boya oloogbe naa da awọn kan lara awọn ọlọṣa naa mọ ni wọn ṣe pa.

Àkọlé fídíò, Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni wọ́n ti já àbálé Esra lábẹ́ àwáwí àyẹ̀wò wúndíá

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, la gbọ pe o ti fi idi iṣẹẹ idigun jale naa mulẹ ti wọn si ni iwadii ti bẹrẹ.

Gẹgẹ bi atẹjade kan ṣe sọ, wọn ti gbe oku arakunrin naa lọ sileewosan nla ijsba to wa lagbegbe Mọniya.