Tunde Bakare: Ìjà àgbà méjì! Àlàyé rèé lórí ááwọ̀ Femi Fani-Kayode àti Tunde Bakare

Tunde Bakare: Ìjà àgbà méjì! Àlàyé rèé lórí ááwọ̀ Femi Fani-Kayode àti Tunde Bakare

Oríṣun àwòrán, Ffk/ fan page

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Mínísítà fún ọ̀rọ̀ ilé iṣẹ́ ìrìnà ojú òfúrú nígbàkan rí, Femi Fani-Kayode ti tún fi ọ̀rọ̀ léde lórí aáwọ̀ tó wà láàrín òun pẹ̀lú pásítọ̀ Tunde Bakare.

Ó fi ọ̀rọ̀ náà léde lójú òpó twitter rẹ̀ pẹ̀lú àfikún pé, òun ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ìtàkurọ̀sọ pẹ̀lú Tunde Bakare àti Mogaji Gboyega Adejumọ, tó jẹ agbẹ̀nusọ fún ẹgbẹ́ ọmọ Yorùbá ti wọn ń pè ni "Yorùbá Summit Group"

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, ó ní , a ti yánju gbogbo ọ̀rọ̀ tó wà láàrin wa, a si ti fi gbogbo ọ̀rọ̀ náà sẹ́yìn bí eegun ṣe n fi asọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Ipò àpọ́nlé tí mo fi pásítọ̀ Bakare sí kò le yingin, Mó dúpẹ́ lọ́wọ́ Mogaji àti ọgbẹ́ni Dele Momodu, fún ọ̀nà ti wọn gbà láti yanjú aáwọ̀ náà.

Tunde Bakare: Ṣé lóòtọ́ ni àṣírí Pásítọ̀ wà lọ́wọ́ Femi Fani -Kayode?

Kini Femi Fani-Kayode àti Tunde Bakare jọ ń fà?

Láti bi ọjọ́ méjì ní gbómisi-omi-òto tí n lọ láàrìn àgbààgbà méjì, ti wọ́n tún jẹ́ gbájúgbajà olóṣèlú ní orílẹ̀-èdè Nàìjìríà.

Bí ọ̀ṣẹ̀ kan ṣẹ́yìn ni ìlúmọ̀ọ́ká pásìtọ̀ ìjọ The Citadel Global Community Church, Tunde Bakare ké sí àwọn ọmọ Nàìjíríà láti wá ǹkan ti yóò ràn ìtẹ̀síwájú orílé-èdè Nàíjíríà lọ́wọ́

O ní èyí yá jú kí wọ́n máa gbi egbìrìn ọ̀tẹ̀ lórí ìpinu Tinubu láti di ààrẹ lọ́dún 2023 lọ.

Ìdí rèé tí mínísítà tẹlẹ fún ìrìnà ojú òfurufú, Femi-Fani Kayode se gbé àtẹ̀jáde kan síta, tó pé àkọlé rẹ̀ ni ta lo n fun Tunde Bakare l‘ẹpọ̀n pọ̀? " Who is Squeezing Tunde Bakare's Ball?"

Femi Fani-Kayode

Oríṣun àwòrán, Facebook/Femi Fani-Kayode

Nínú atẹ́jáde náà ni Fani-Kayode ti ń bèèrè pé kí ló le ṣẹlẹ̀ sí Tunde Bakare to fẹnu sátá Bola Ahmed Tinubu ní ǹkan bi oṣù mẹ́rinlá sẹ́yìn, tó wá yí bìrí ni àsìkò yìí tó tún ń kọrin ìyìn rẹ̀?

Àmọ́ àtẹ́jáde ti Femi Fani-Kayode kọ náà, tó si fí ẹ̀dà rẹ̀ sójú òpó twitter rẹ̀ @realFFK, ni kò sí mọ́ lójú òpó twitter náà báyìí, sùgbọ́n ó sí wà lójú òpó Facebook rẹ̀:

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

FFK ni àyípadà ọkàn Bakare kò ni sàì ṣẹ̀yin ọ̀rọ̀ ilé ifówópamọ́ tí orúkọ ẹni tó ni yí pada láìpẹ́ yìí, àti àwọn ǹkankan tọ ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1990 ní ìgbésí ayé Tunde Bakare, bóyá àwọn ọmọ lẹ́yìn Tinubu si ti ń pinu láti tú àṣírí náà síta ló fàá, tí Bakare fi yi bìrí.

Bákan náà ni FFK tún fi kún pé Bakare ń ti Tinubu mọ́ àwọn ènìyàn ti kò fẹ́ lọ́run ni gẹgẹ bii oludije aarẹ lọdun 2023.

Fani Kayode ati bakare

Oríṣun àwòrán, FFK

Awọn ẹsun yii ló bọ́ sápọ̀ ìbínú Bakare, tó si fèsì sọ̀wọ̀ si olóyè ẹgbẹ́ Afẹnifẹre, Yinka Odunmakin, tó sì sàlàyé pé ki FFK wá sọ ǹkan tó bá mọ̀ nípa òun.

Bákare fikun pe kò sí ẹnikẹ́ni, bí ó ti wù kó ní ipò tàbi lọ́la, tó tí ó le sọ pé òun ni àsírí kankan ni ìpamọ́.

Gẹgẹ bí ọ̀rọ̀ Bakare kọ si Odumakin, o ni "Káàrọ̀ Yinka, mo ti ka ọ̀rọ̀ ti Femi Fani -Kayode kọ níbi ti ó ti dárúkọ rẹ̀ àti àwọn míràn.

"Jọ́wọ́ mo kan fẹ́ bẹ̀ ọ́ síi: Sọ fún ki ó tú àsírí mi atawọn nǹkan ti kò dára tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1990.

Àkọlé fídíò, 2020 in Retrospect: Ìjàmbá iná, ilé tó dàwó, ìwọ́de àti àrùn Covid-19 wà lára ìṣẹ̀lẹ̀ 2020

Bákan náà ló gbọdọ sọ̀ nípa àwọn ohun ti mo ṣe nípa ilé ifówópamọ tí orúkọ ẹni tó ni yí pada láìpẹ́ yìí, tí ó sì níṣe pẹ̀lú mi.

Ẹ̀wẹ̀, Femi Fani-Kayode naa tun ti wá fèsì, tí òun pẹ́lú sì rán Odunakin si Tunde Bakare pé ìbéérè lásán ni òun ń bèrè o.

O ni kìí ṣe pé òun ń fi idí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀. O ni "Sé a kò le bèèrè ìbéèrè ni? Ṣé òun ni Ọlọruin ni? Kíló ṣe ti kò le dáhun ibéèrè ti mo bíi?

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ lójú òpó twitter rèé:

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Amọ titi di akoko yii, oloye Bola Ahmed Tinubu, ti ọrọ Tunde Bakare da le lori ati awọn ohun ti Fani-Kayode fi fesi pada, ko sọ ohunkohun lori awọn isẹlẹ naa.