Femi Fani-Kayode; Ìrọ́ ní o, mi ò fí ìyà jẹ ìyàwó tí mo kọ̀ sílẹ

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/@REAL_FFK
Minisita fun eto irina ọkọ ofurufu tẹlẹri ni Niajiria, Fẹmi Fani-Kayode ti bu ẹnu atẹ lu fidio to n ja ranyin lori ayelujara pe oun lu iyawo oun.
O ni ọgbọn ni iyawo oun da to fi n ṣe fidio oun tori pe o n ba a wi lẹyin to ka iwa nọbi mọ ọ lọwọ.
Fani Kayode fi iroyin lati tako fidio naa lede loju opo ikansiraẹni Instagram rẹ.
O ni irọ patapata ni fidio ti ileeṣẹ iroyin Sahara Reporters safihan rẹ, nitori ohun ko gbe ọwọ soke na iyawo oun ri.
O ni ohun to ṣẹlẹ ninu fidio naa ni wi pe oun gba foonu lọwọ iyawo oun nibi to ti n ka aworan ati ohun oun silẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Fani Kayode ṣalaye wi pe oun sọ ọrọ si lori pe oun hu iwa aitọ lati igba de igba.
O kesi awọn to ba wo fidio naa lati gbọ ohun ti oun n sọ daradara.
''Ọrọ ti mo n sọ ninu fidio naa fihan pe nko naa, mo gba foonu lọwọ rẹ ni lati dawọ kika ohun mi silẹ''.
''Mi o naa iyawo mi ri, amọ wahala rẹ ti pọju, ti ko si fẹran alaafia rara''
Bakan naa, Fani Kayode sọ loju opo Twitter rẹ̀ pe lẹyin ọjọ melo kan ti oun ka iyawo oun mọ ori bẹẹdi pẹlu ọkunrin mii.
O ni ọrọ to jade lẹnu oun ninu fidio naa ye eeyan to to si rọ awọn eeyan lati wo fidio ọhun daadaa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Amọ, ninu fidio naa ni iyawo rẹ to kọ silẹ ọhun ti n pariwo pe lati owurọ ni o ti n fi iya jẹ oun, ti oun ko si sọrọ.
Bakan naa ni o fẹsun kan ọkọ rẹ pe ko ye e fi iya jẹ oun mọ.
Laipẹ yii ni Femi Fani-Kayode sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn tó sọ pé ó ń múra ìgbéyàwó pẹ̀lú Halima Yusuf lẹyin to kọ iyawo rẹ silẹ.













