Ekiti Bank Robbery: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá rí ọkọ̀ mẹ́ta gbà lọ́wọ́ adigunjalè báńkì Iyin-Ekiti

Oríṣun àwòrán, @tosinsammy_s
Ọjọ buruku, Eṣu gbomi mu lọjọ Ẹti, ọjọ keji oṣu kẹwaa ọdun 2020 jẹ niluu Iyin-Ekiti, nibi tawọn adigunjale ti yabo ile ifowopamọ WEMA ti wọn si gbe ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu owo naira lọ.
Amọ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti kede pe, oun ti ri ọkọ mẹta tawọn adigunjale naa lo, lati ṣiṣẹ ibi wọn.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu fi sita ṣalaye pe ado oloro IED, igbo, ọti ati foonu meji lawọn ri ninu awọn ọkọ naa.
- Sunday Igboho kàn ń gbé ‘Camera’ lẹ́yìn kiri, kí wọ̀n lè rò pé ó ń jà fún Yorùbá - Gani Adams
- ''Ẹ ràn wá lọ́wọ́, ọmọ 18 pẹ̀lú ìyàwó mẹ́rin ni ọkọ wa tí ìbọn ''Customs'' pa fi sílẹ̀ lọ''
- ₦750m ni Akeredolu ń gbà lóṣù fún ‘Security Vote’ àti ₦150m owó oṣù - Agboola Ajayi fèsì
- Àjọ EFCC ti mú ọ̀dọ́kùnrin mẹ́wàá lórí ẹ̀sùn jìbìtì lílù lórí ayélujára ní Oyo
- Ẹgbẹ́ tó ń fẹ́ Oduduwa Republic kọ̀wé ẹ̀hónú sí UN, EU, AU àti ìjọba Gẹ̀ẹ́sì
Ileeṣẹ ọlọpaa ni mẹwaa lawọn adigunjale naa, awọn ọkọ ti wọn si lo fi fọ banki naa ni ọkọ ayọkẹlẹ Volkswagen Golf pẹlu nọmba GED 906 AA, Acura MDX Jeep pẹlu nọmba LSR 327 CD, ati Toyota Camry to ni nọmba No GED 106 ER.

Oríṣun àwòrán, @tosinsammy_s
Ileeṣẹ ọlọpaa ni apa awọn agbofinro to n ṣọ banki naa ko ka wọn, nitori bi wọn ṣe pọ wa, ti gbogbo wọn si wọle lẹẹkan naa.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe, ko si ẹni to ba iṣẹlẹ naa lọ.
Ọgbẹni Abutu wa rọ awọn araalu lati mase foya, nitori iwadii ti bẹrẹ lati rii pe ọwọ tẹ awọn aṣebi naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
O ni awọn adigunjale naa fẹsẹ fẹ, ti wọn si fi ọkọ ti wọn gbe wa silẹ nigba tawọn ọlọpaa de ibẹ, ti wọn si kọju ija kọ wọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa Ekiti rọ awọn araalu Iyin-Ekiti pe, ki wọn fi to awọn ọlọpaa leti ti wọn ba kẹfin ẹnikan to ṣeeṣe ko wa lara awọn adigunjale naa.
Ẹnikan ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ ṣalaye fawọn akọroyin pe, ni bii aago mẹta aabọ ọsan lawọn adigunjale naa de banki ọhun.
O ni ohun ija ado oloro bii ''dynamite'' ni wọn fi ṣilẹkun ile ifowopamọ si naa, nibi ti wọn ti ji owo ko lọ.













