Ogun kiliing: Ọmọ olóògbé ní oúnjẹ ni bàbá òun ń jẹ nínú ṣọ́ọ́bù, kí ìbọn tó bàá

Osisẹ aṣọbode

Oríṣun àwòrán, @jacobscarlene1

"Ọmọ mejidinlogun ni ọkọ wa fi silẹ, ko si ẹni ti yoo ran wa lọwọ."

Ọkan lara awọn iyawo ọkunrin ''Panel Beater'' kan, Moses Atanda, ti ọta ibọn osisẹ asọbode, Custom, ṣeesi ba ninu sọọbu rẹ nipinlẹ Ogun, Titilayo Atanda, lo sọ bẹẹ.

Ọmọ ''panel beater'' naa, Adeniyi Atanda ni ounjẹ ni baba oun n jẹ lọwọ nigba ti ibọn baa nibi to ti n ṣọọbu rẹ.

Iyawo mẹrin ni Ọgbẹni Atanda fi si aye lọ lai ro tẹlẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Titilayo ṣalaye fawọn akọroyin pe, ọpọ ninu awọn ọmọ ti oloogbe fi silẹ lọ ni wọn si wa nile iwe, nigba tawọn mii si n wa lẹnu ikọṣẹ.

Àkọlé fídíò, Yomi Fabiyi: Fíìmù ‘Owó orí ẹlẹ́wọ̀n’ jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà ìpọ́njú làá mọ ọ̀rẹ́

Titilayo sọ pe, oniṣowo pẹpẹpẹ lawọn iyawo ṣugbọn ọkọ awọn naa lo n tọju gbogbo awọn ninu ẹbi.

''A o tiẹ mọ ohun ti a le ṣe, a ko ni ohun kankan, ko si ẹni ti yoo ba wa sanwo ileewe awọn ọmọ ati ipese ounjẹ fun wọn,'' Titilayo lo sọ bẹẹ.

Titilayo ni iṣẹ ọkọ rirọ (panel beater) nikan ni ọkọ awọn n ṣe, kii ṣe awọn to maa n ṣe fayawọ ọja wọle lati orilẹede mii wọ Naijiria.

Ọkan lara awọn oloogbe naa, Gabriel Atanda sọ fawọn akọroyin pe, oun wa pẹlu baba oun ninu ṣọọbu nigba tawọn ẹṣọ aṣọbode bẹrẹ si ni yinbọn lagbegbe naa.

Àkọlé fídíò, Ìṣẹ̀lẹ̀ Kàyéèfì: Ìpáǹle tú Abass Owonikoko sí ìhòòhò ayé, kó tó gba kéú lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

O ni gbogbo igba lawọn aṣọbode ọhun maa n yinbọn lagbegbe naa, ti awọn eeyan yoo si maa wo wọn bi fiimu.

Baba mi sọ fun mi atawọn mii pe, ki a sa pamọ sinu ṣọọbu ki ọta ibọn ma baa ṣeesi ba wa.

Kete ti mo bọ sinu ṣoọbu tan ni mo rii pe ẹjẹ ti bo bo baba mi, lẹyin ti ibọn awọn aṣọbode ti ba a.

O ni awọn gbe baba oun digbadigba lọ si ile iwosan, amọ ọwọ ti bọ sori.