Plateau runaway girl: to Ekiti: Kíni ó lè mú kí ọmọbìnrin sá kúrò nílé láti ìpínlẹ̀ Plateau lọ sí Ekiti?

Ẹ wo ọmọbinrin to sakuro nile nitori Baba rẹ fẹ fi fun ọkọ tipatipa
Ọmọ ọdun marundinlogun sa kuro ni Plateau wa si Ekiti nitori igbeyawo tipatipa.
Arabinrin ọmọ ọdun marundinlogun ti fi ẹjọ baba rẹ sun lori ẹsun pe baba oun fẹ fi tipatipa fi oun fun ọkọ
- Àyọ́jọ́ ọjọ́ Òmìnira Nàìjíríà: Sanwo-Olu gbàlejò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ̣ogọ́ta, El-Rufai dá ẹlẹ́wọ̀n 25 sílẹ̀
- Ẹ lọ ṣí gbogbo ilé ẹ̀kọ́ padà ní Nàíjíríà - Ìjọba àpàpọ̀
- Àwọn ọlọ́ṣà sùn lọ nínú ọkọ̀ tí wọ́n jí, lọ́wọ́ agbófinró bá tẹ̀ wọ́n
- Wo ìgbà méje tí Donald Trump ti yẹpẹre àrùn Coronavirus
- Wike, má gbé jàgídíjàgan wá sí Ondo, APC kò ní ṣ'èèrú nínú ìdìbò gómìnà tó ń bọ̀- Kalejaye
- Àjọ EFCC ti mú ọ̀dọ́kùnrin mẹ́wàá lórí ẹ̀sùn jìbìtì lílù lórí ayélujára ní Oyo
- Ọkọ̀ ọ̀fẹ́ ní ọmọ tuntun jòjòlò tí wọ́n bí sínú ọkọ̀ òfurufú yóò máa wọ̀ títí ayé rẹ̀- Egypt Air
Iroyin ni wi pe ọmọbinrin naa kuro ni ile rẹ ni ipinlẹ Plateau wa si ilu Ekiti lati duro ti ẹgbọn rẹ lẹyin to tako igbeyawo tipatipa ti wọn fẹ ṣe fun un.
Eka ajọ awọn agbẹjọro to jẹ obinrin lagbaye, FIDA to wa ni ipinlẹ Ekiti lo fi iroyin naa lede fun awọn akọ̀royin.
Alaga Ajọ FIDA, Abilekọ Toyin Odunayo sọ wi pe awọn kọkọ pese ibugbe fun arabinrin naa nigba ti o kọkọ de si ipinlẹ Ekiti, ti ko i tii ri ẹgbọn rẹ ọkunrin to wa ba a.
'Ni igba ti a ri ẹgbọn rẹ, Hameed Adamu sọ wi pe lootọ ni baba rẹ fẹ fi fun ọkọ tipatipa.'
Alaga naa salaye pe: 'Adamu ni baba oun ti fi panpẹ ọlọpaa mu arakunrin kan ni Plateau ti wọn fi ẹsun kan wi pe oun lo fun ọmọbinrin naa ni owo lati tẹ ọkọ leti wa si Ekiti.'
'Amọ, ọjọ keji ni wọn fi ọkunrin naa silẹ, amọ baba mi ti sọ wi pe dandan ni oun yoo tun fi panpẹ ọba mu ọkunrin naa lẹẹkeji.'
Ajọ FIDA fikun pe awọn ti gbe ẹjọ naa lọ si ajọ to n risi ẹtọ ọmọniyan lorilẹede Naijiria lati da si ọrọ naa lati ẹka wọn to wa ni ipinlẹ Plateau.
Bakan naa ni Alaga ajọ FIDA naa wa rọ awọn araalu lati ma a ran ara wọn lọwọ, ki wọn si ma a tu asiri awọn eniyan ti wọn ba n fiya jẹ ọmọnikeji wọn ni ọna kọna.

















