Coronavirus update in Nigeria: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 181 pẹ̀lú Olùkọ́ lùgbàdì Covid 19 níléèwé kan nípinlẹ̀ Eko

Akekoo

Oríṣun àwòrán, Google

Akẹkọọ mọkanlelọgọsan pẹlu olukọ ileewe aladani lo ti lugbadi arun Coronavirus ni ipinlẹ Eko lorilẹ-ede Naijiria.

Agbegbe Lekki ni ipinlẹ Eko ni iṣẹlẹ naa ti waye ni ile iwe aladani to jẹ eleyii ti awọn akẹkọọ n gbe ninu rẹ.

Kọmisọnna fun eto ilera nipinlẹ Eko, Akin Abayomi lo fi iroyin naa lede pe iwadii lo jẹ ki wọn tete mọ wi pe arun Coronavirus lo n ba awọn akẹkọọ naa fihan.

Àkọlé fídíò, Ogbomsho shooting, End Sars, End SWAT: Isiaka fi ọmọbìnrin kan àti ìyàwó tó lóyún sínú síl

Abayomi ni ninu eniyan 441 to wa ni ileewe naa, ni 181 ninu wọn ti ko arun Covid-19 ọhun.

Bi iwadii ṣe bẹrẹ ni pe, akẹkọọ to wa ni ipele SS1 lo ṣe aisan ni Ọjọ Kẹta, Oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ti wọn si ran an lọ sile lẹyin ti wọn kọkọ fun un ni itọju ni ileewe naa.

Lẹyin naa ni wọn wa ṣe ayẹwo fun awọn akẹkọọ, ti o si fihan gbangba pe ọmo. naa ti lugbadi arun Coronavirus.

Ayẹwo siwaju si fihan pe awọn ọgọsan miran pẹlu rẹ ti lugbadi arun naa ni ileewe ọhun.

Nibayii, ijọba ti gbe igbesẹ lati ri wi pe arun naa ko tan kalẹ si ni ileewe naa.''Ofin konile-o-gbele oḷọjọyipo ti wa ni ileewe naa, ti awọn Ajọ to n risi ajakalẹ arun nipinlẹ Eko si ti wa ni ileewe naa lati bojuto awọn to lugbadi arun ọhun.

''Awọn akẹkọọ ati olukọ ti wọn ti ni arun Covid-19 naa lo ti wa ni yara iyasọtọ lọwọlọwọ, ti wọn si ti n gba itọju.''

Awọn akẹkọọ to wa ni iyasọtọ naa ko ni lee lọ si ileewe, paapaa akẹkọọ to ba ṣe aisan ni ileewe ni a n gbe lọ si yara iyasọtọ, ki a le mọ daju wi pe kii ṣe arun Covid-19, ki wọn ma ba koran awọn araale.

O ni: '''inu mi dun wi pe awọn akẹkọọ to lugbadi arun naa ko fi ami han, bẹẹ si ni ko buru pupọ lara awọn to fi ami han lara wọn'

'Bakan naa ni wọn si ti pe awọn obi awọn ọmọ naa lati le fi ọkan wọn balẹ, ki wọn si gba wọn ni iyanju pe, ki wọn ma mikan nitori alaafia ni awọn ọmọ naa wa.

Kọmisọnna fun eto ilera naa kesi awọn eniyan lati ni lọkan wi pe arun Coronavirus si n ba ọpọlọpọ eniyan finra, nitori naa ki wọn mu ilera ara wọn lọkunkundun.

Nàìjíríà ṣí àwọn ilé ìwé padà; Ìdánwò WAEC á bẹrẹ lẹyìn ọdún Iléyá!

Oríṣun àwòrán, other

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Ẹ lọ ṣí gbogbo ilé ẹ̀kọ́ padà ní Nàíjíríà - Ìjọba àpàpọ̀

Nigeria schools reopening: October 4 làwọn ilé ẹ̀kọ́ yóò di ṣíṣí padà

Minisita feto ẹkọ, Adamu Adamu ti kede pe ki awọn ile ẹkọ lorilẹ ede Naijiria di sisi pada.

Minisita feto ẹkọ ni Naijiria, Adamu Adamu ti kede lọjọ Ẹti pe ki gbogbo ile ẹkọ di sisi pada.

Minisita, ẹni to kede bẹẹ nibi ipade akọroyin kan to waye lọjọ Ẹti ni ọjọ kejila osu Kẹwa ọdun 2020 ni ilẹkun awọn ile ẹkọ naa yoo di sisi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa lo rọ awọn ọga ile ẹkọ, olukọ ati awọn akẹkọọ lati tẹle awọn ofin to dena arun Coronavirus lasiko tawọn ile ẹkọ naa ba di sisi pada.

Ìjọba àpapọ̀ kéde ọjọ́ tí ìdánwò NECO, NABTEB àti BECE yóò bẹ̀rẹ̀

Saaju la ti sọ fun yin pe, ijọba apapọ ti kede pe idanwo aṣekagba ile iwe girama ti ajọ NECO n dari rẹ yoo waye laarin ọjọ karun un, oṣu kẹwaa si ọjọ kejidinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 2020.

Bẹẹ lo tun kede pe idanwo ti ajọ NABTEB n ṣakoso rẹ yoo waye laarin ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹsan an si ọjọ karundinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2020.

Minisita to n ri si eto ẹkọ, Emeka Nwajuiba lo kede awọn ọjọ idanwo naa lẹyin ipade ọlọjọ meji to waye pẹlu awọn alakoso ajọ to n dari awọn idanwo ọhun ni Naijiria.

Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ to n ri si eto ẹkọ, Ben Goong, fi lede, wọn ni idanwo aṣewọle si awọn ile iwe ijọba apapọ, Unity Schools naa yoo waye lọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹwaa.

Bakan naa ni wọn ni idanwo BECE fun awọn akẹkọọ ni ipele kẹta akọkọ nile iwe girama yoo waye laarin ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹjọ si ọjọ Keje, oṣu kẹsan an.

O pari atẹjade ọhun pe iforukọsilẹ fun idanwo NECO ṣi n lọ lọwọ titi di ọjọ kẹwaa, oṣu kẹsan an, ọdun 2020.

Àkọlé fídíò, Oronpoto Animation: Akin Alabi ní kò dára bí eré aláwòrán fáwọn ọmọdé ṣe jẹ́ aláwọ̀ funfun

Ìjọba àpapọ kéde ọjọ ìwọlé àwọn akẹkọọ onípele ìdánwò àsekágbá WAEC

Ijọba ni eyi yoo fun awọn akẹkọọ onipele idanwo ni ọsẹ meji lati fi gbaradi de idanwo wọn.

Wọn ní idanwo aṣekagba oni iwe mẹwaa yoo bẹrẹ ni ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2020 ti a wa yii

Nàìjíríà ṣí àwọn ilé ìwé padà; Ìdánwò WAEC á bẹrẹ lẹyìn ọdún Iléyá!

Oríṣun àwòrán, other

Bi ẹ ko ba gbagbe ajakale arun coronavirus lo mu ki wón sun idanwo aṣekagba yii siwaju titi di asiko yii nitori pe awọn orilẹ-ede agbaye gbe awọn ile iwe ti pa ki ajakale arun naa ma ba a maa tan kalẹ.

Loni ojó kẹtadinlọgbọn, oṣù keje yii ni ijoba apapọ ati awọn Kọmiṣọnna ipinle merindinlọgbọn Naijiria ati aṣoju ẹgbẹ awọn Olukọ ati ẹgbẹ awọn Onile iwe Aladani kaakiri ipinlẹ

Naijiria fẹnuko lori igbesẹ yii lẹyin ti wọn se ipade papọ lori ayelujara.

Wọn ni kete ti ọdun Ileya ba ti pari ni ki awọn akẹkọọ onidanwo pada sile iwe koowa wọn.

Gbogbo wọn ló fẹenuko pẹlu ijọba pe awọn yoo pese ohun to yẹ ki awọn akẹkọọ le wa ni alaafia nile iwe lasiko idanwo naa pẹlu iranlọwọ wọn ile iwe.

Ijoba apapọ tun ti pe ipade miran ni ọla lori awọn igbesẹ ti ile iwe kọọkan a gbe ki ọsan eto ẹkọ le so didun.

Ipade to maa waye lọla, ọjọ kejidinlọgbọn, osu keje yii yoo mu awọn asoju ajọ idanwo NECO, NABTEB, NBAIS ati awọn to yẹ dani lati fẹnuko lori awọn ọjọ idanwo gbogbo

Akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, others

Oyo school reopening: Kí ló dé tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo kéde fífagilé Sáà ètò ẹ̀kọ́ kẹta fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́

Ijọba ipinlẹ Oyo ti buwọlu igbesẹ ti yoo mu ki gbogbo akẹkọọ pada si ileewe ni ipinlẹ naa.

Ijọba gbe igbesẹ naa ni ibi ipade ajọ amuṣẹya ti ipinlẹ ọhun to waye ni Ọjọ Iṣẹgun, lẹyin ti wọn ti ileewe pa nitori ajakalẹ arun Coronavirus.

Ijọba Oyo ni awọn gbe igbesẹ yii fun irọrun awọn akẹkọọ lo mu ki awọn ṣe gbe igbese naa, ki saa naa le lọ ni irọwọ-rọsẹ.

Ninu atẹ tabili fun bi ẹkọ yoo ṣe ri ni saa yii, ni wọn ti fagile saa kẹta fun saa 2019 si 2020.

Nitori naa, esi idanwo ti wọn ṣe kọja ni saa eto ẹkọ kini ati saa eto ẹkọ keji ni wọn yoo lo lati fi ṣe idanwo fun wọn.

Awọn akẹkọọjade to wa ni ileewe alakọbẹrẹ (Primary 6), ti girama kekere (JSS3), ti girama agba (SSS3) yoo bẹrẹ isinmi lati Ọgbọnjọ, Oṣu Keje yii, ti wọn yoo si pada si ileewe nigba ti idanwo wọn ba bẹrẹ.

Akẹkọọ ipinlẹ Oyo

Oríṣun àwòrán, others

Ijọba fikun un pe idanwo 'The Basic Education Certificate Examination' yoo waye ni Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Kẹjọ.

Nigba ti idanwo 'Competitive Entrance Examination' ni awọn ileewe imọ sayẹnsi yoo waye ni Ọjọ Kọkandinlogun, Oṣu Kẹjọ.

Bakan naa ni wọn tun ni pe idanwo igbaniwọle si JSS1 yoo waye ni Ogunjọ, Oṣu Kẹjọ, nigba ti idanwo si awọn ileewe ẹkọṣẹ ti ijọba yoo waye ni Ọjọ Kejidinlọgbọn, Oṣu Kẹjọ.

Awọn akẹkọọ SS3 yoo bẹrẹ idanwo WAEC wọn ni kete ti Ajọ WAEC ba ti fi ọjọ idanwo naa lede.

Ijọba fikun un pe esi idanwo saa eto kini ati ti saaeto ẹkọ keji fun ọdun 2020/21 yoo bere ni Ọjọ Kọkanlelogun, Oṣu Kẹsan an ati Ọjọ Kejidinlogun, Oṣu Kejila, ọdun 2020.

Àkọlé fídíò, Olofa ina: ẹ parí òwe yìí pé ìgbà tí ara bá tu ìgbẹ́ láà ri eṣú....

Wọn ni awọn gbe igbesẹ lati wọfile saa eto ẹkọ kẹta to yẹ ki awọn akẹkọọ lo tẹlẹ fun anafani wọn ni.

Nitori pe ko yẹ ki ajakalẹ arun Coronavirus gba asiko awọn akẹkọọ tan lodun 2020.

Koda, ijọba ti ṣeto ilana aatẹlẹ fun awọn Olukọ lasiko yii ki ọsan le so didun fun awọn akẹkọọ ipinlẹ Oyo

Àkọlé fídíò, Funmi Adewara: Tele Medicine' ní a fi ń ṣàyẹ̀wò èèyàn ìdá ọgọtá láti dènà ìtànkálẹ̀ Covid