Tola Oyediran: Buhari, Makinde, Sanwo-Olu ń ṣèdárò Tola Oyediran ọmọ Obafemi Awolowo tó papòdà

Oríṣun àwòrán, Tribuneonline
Ọpẹ eekan lagbo oṣelu lo ti n ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbi mama Tola Oyediran tii ṣe akọbi obinrin Oloye Obafemi Awolowo to jade laye lọjọ Ẹti.
Aburo oloogbe naa, Ọmọwe Tokunbo Dosunmu-Awolowo to ba BBC Yoruba ṣalaye pe ni bii deedee aago mejila ọsan ti mama jẹ Ọlọrun nipe.
Ẹwẹ, Aarẹ Muhammadu Buhari ti kẹdun pẹlu idile oloogbe Tola Oyediran.
- Sọ̀rọ̀ sókè! Odunlade, Toyin, Ijebu dásí ìwọ́de #EndSARS, Mercy Aigbe gbébọn
- Ìdí táwọn olùwọ́de EndSARS fi kọ oúnjẹ àti ọtí ẹlẹ́rìndòdò tí MC Oluomo gbé wá rèé
- Ọkọ̀ akẹ́rù tí ìjánu rẹ̀ já ló kọlù ọkọ̀ agbépo tó fa ìjàmbá iná ní Otedola- LASEMA
- Ẹ foríjìn wá ọmọ Nàìjíríà, mó mọ̀ pé ẹ̀ ń bínú tórí a kò tètè gbé ìgbésẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ EndSARS- Osinbajo
- Omijé fẹ́ bọ́ lójú mi tí mo bá ṣàfiwé SARS tí mo dá sílẹ̀ àti SARS tó wà níta báyìí- Fulani Kwajafa
Ninu atẹjade ti oludamọran Aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin, Garba Shehu fi sita, Buhari ni ki wọn dupẹ lọwọ Eledua fun igbe aye to daara ti mama gbe nigba to wa laye.
Buhari ni oloogbe naa gbiyanju agbara rẹ lati ṣe iranwọ fawọn eeyan to layika rẹ eleyi ti awọn eeyan yoo maa fi ṣe iranti rẹ lọ laelae.
Aarẹ gbadura wi pe ki ọlọrun tẹ mama si afẹfẹ rere ki O si tun awọn ẹbi rẹ ninu.
Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo naa ti ṣapejuwe iku mama Oyediran gẹgẹ bi adanu nla fun orilẹede Naijiria.
Ninu iṣẹ ibanikẹdun to fi ṣọwọ si igbimọ alaṣẹ iwe iroyin Tribune, Makinde ni lootọọ ni mama ti ku, ṣugbọn ipa to ni lawujọ ko le parẹ laelae.

Oríṣun àwòrán, Tribune Newspaper
Bakan naa lo sọ pe awọn eeyan yoo maa ṣe iranti mama Oyediran gẹgẹ bi ẹnikan to tẹ le awọn ilana ti Oloye Awolowo la kalẹ titi to fi ku.
Makinde ko ṣalai ki aburo oloogbe, Dokita Dosunmu-Awolowo ati iyawo igbakeji aarẹ Dolapo Osinbaji pẹlu igbakeji Aarẹ rẹ ku ara fẹraku.
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu naa ko gbẹyin ninu awọn to n ṣedaro ẹn'ire to lọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
O ni adanu nla ni iku mama Oyediran jẹ fun ẹbi, atawọn ọrẹ rẹ to fi mọ ile iwe iroyin Tribune.
Sanwo-Olu ni olori to ṣee fi ọkan tan ni mama nigba aye rẹ ati pe ẹlẹyinju aanu ati onirẹlẹ eniyan ni.
- Báwo ni Donald Trump ṣè ń rí ọwọ́ mú sí nínú àkójọ èrò àwọn olùdìbò?
- Wo àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Nàìjíríà àti l'Áfíríkà tó ń wólẹ̀ àdúrà kí Trump lè wọlé ìbò ààrẹ America
- Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 181 pẹ̀lú Olùkọ́ lùgbàdì Covid 19 níléèwé aláàdáni kan nípinlẹ̀ Eko
- Ọkọ̀ akẹ́rù tí ìjánu rẹ̀ já ló kọlù ọkọ̀ agbépo tó fa ìjàmbá iná ní Otedola- LASEMA
Tola Oyediran ọmọ Obafemi Awolowo ti jáde láyé
Iku n pa ni, ilẹ n jẹ eeyan. Iroyin to n tẹ wa lọwọ lo sọ pe Tola Oyediran Awolowo ti papoda.
Ọjọ kinni oṣu kejila ọdun 2020 yii ni mama Oyediran to jẹ ọkan ninu awọn ọmọ olootu ijọ iwọ oorun guusu Naijiria nigba kan ri, Oloye Obafemi Awolowo ko ba ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọrin ọdun laye.
Oun ni omọ Awowlọwọ to dagba ju ki iku to mu un lọ.
Tola si ni alaga igbimọ alaṣẹ iwe iroyin Tribune titi ti o fi faye silẹ.
- Ohun tí ojú ìyàwó mi rí lọ́wọ́ SARS kò ṣe é fẹnusọ- Poju Oyemade
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti kéde orúkọ àwọn ọlọ́pàá tó fi ìyà jẹ àwọn olùwọ́de #EndSARS
- Ajínigbé tú ìyá àti ọmọ ọdún mẹ́ta sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba ₦1.2 mílíọ́nù owó ìtanràn
- Àjẹ́ àti Aṣẹ́wó ní ìyá Rainbow - Òjòpagogo
- Cardi B ṣàlàyé ohun tó gbé fọ́tò ìhòhò rẹ̀ d'órí ayélujára Instagram
Dokita Tokunbọ Dosunmu ṣalaye fun BBC pé Arabinrin Tola Oyediran Awolowo ko ṣaarẹ rara ki ọlọjọ to de.
O ni nkan bii aago mejila ọsan oni ni alumuntu wọle de were to mu ẹgbọn oun lọ.
Bakan naa lo ni ẹbi ṣi wa ninu irora ati iyalẹnu pe ṣe gbogbo ẹ ti pari naa ni yẹn ni asiko yii.
BBC gbadura pe ki Olorun tu ẹbi ti ọrọ kan naa ninu lasiko yii
- Wo ìgbésẹ̀ mẹ́ta tí Gómìnà Obiano gbé lórí ọ̀rọ̀ SARS ní Anambra
- Wo nọ́mbà tí o le è pè láti gba owó gbà-má-bínú tí ọlọ́pàá bá fìyà jẹ ọ́ lọ́nà àìtọ́ l'Eko
- Mo kọ̀ láti kópa nínú ìpàdé orí ayélujára Nàìjíríà yìí- Falz
- Ìjọba Nàìjíríà ti gbà láti san N30b owó àjẹmọ́nú fún ASUU
- Ẹ ṣọ́ra ní òpópónà AIT, ọkọ̀ agbépo kan ti yí dánù lọ́nà agbègbè Alagbado

















