ASUU strike: Ìjọba Nàìjíríà ti gbà láti san N30b owó àjẹmọ́nú fún ASUU

Abawole fasiti Ibadan

Oríṣun àwòrán, @ui

Àkọlé àwòrán, Oṣu mẹfa ni iyanṣẹlodi naa fi waye

Ijọba apapọ Naijiria ti gba lati yọnda biliọnu lọna ọgbọn Naira, fun ajẹmọnu awọn olukọ fasiti ni Naijiria.

Ijọba sọ pe oun yoo san owo naa diẹdiẹ laarin oṣu Karun-un ọdun 2021 si oṣu Keji, ọdun 2022.

Nibi ipade ti awọn aṣoju ijọba ati awọn adari ẹgbẹ awọn olukọ fasiti, ASUU, ti aarẹ wọn, Ọjọgbọn Biodun Ogunyemi, ṣe ni alẹ Ọjọbọ ni wọn ti kede eyi.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Punch ṣe jabọ, ijọba tun ṣelelri lati na biliọnu lọna ogun Naira, lati fi ṣe atunṣe eto ẹkọ ni Naijiria.

Gbogbo igbesẹ yii ni ireti wa pe yoo fi opin si iyanṣẹlodi oṣu meje ti ẹgbẹ ASUU wa lori rẹ.

Senator Chris Ngige

Oríṣun àwòrán, @SenChrisNgige

Àkọlé àwòrán, Chris Ngige, Minisita fun ọrọ oṣiṣẹ ni Naijiria

Ṣaaju ni iroyin sọ pe Minisita fun ọrọ awọn oṣisẹ ni Naijiria, Chris Ngige sọ pe iyanṣẹlodi naa fi aaye silẹ fun awọn oluwọde End Sars lati ma a lo awọn akẹkọọ fun iwọde naa.

Àkọlé fídíò, End SARS, End SWAT: Ó pé mi bí SARS kò ṣe sọ mí dolówọ́- Fulani Kwajafa

Ngige sọ pe lati bi ọsẹ kan ni ijsba ti n ṣiṣẹ lati fi opin si iyanṣẹlodi naa, to si sọ pe adura awsn ni pe ki ipade ti wọn ṣe naa so eso rere.