Farting offense: Ọkùnrin yasó nínú ọkọ̀ Uber rí ẹ̀wọn he ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sí

Oríṣun àwòrán, Twitter/Uber Uk
Eleduwa ko daa akitan iso ni wọn maa n wi nilẹ ku otu o jiire. Ọrọ ko ri bẹẹ fun ọkunrin ti wọn fẹsun iwa kan kan lẹyin to yaso ninu ọkọ Uber.
Ileeṣẹ iroyin Bristol Live lorilẹede Uk fẹsun kan ọkunrin pe o yaso o si tun ṣe ikọlu fun awakọ Uber nitori pe oun fi ẹhonu han.
Agbẹjọro Anthony Bignall sọ fun ileẹjọ Bristol Crown pe iwa ti ọkunrin hu kudiẹ kaato.
- Irọ́ ni pé wọ́n hú òkú Kolawole Gold lórí pẹpẹ ìjọ ọkọ mi- Bisola aya Sotitobire
- Ẹ wo èrò bìbà níbi ìwọ́de #EndSARS ní ìlú Ibadan
- Wo bí àwọn jàndùkú ṣe yabò àwọn olùwọ́de #ENDSARS ní Alausa l'Eko àti Abuja
- Èèyàn 179 ló tún ṣẹ̀ṣẹ̀ ní àrùn Coronavirus ní Nàìjíríà
- Wo ìdí tí Tẹni, ọ̀dọ́mọdé olórin obìnrin kìí fi ń ṣí ìhòhò rẹ silẹ̀
- Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ l'Ogbomọṣọ, àwọn ọ̀dọ́ kọlu ààfin Ṣọun
Lọdun 2019 ni iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ nigba ti James Mallett to n gbe ni Kingswood yaso nibi to joko si lẹyin ọkọ pẹlu awọn eeyan mẹta mii niga ti wọn n lọ si ile ijo lalẹ.
Ileẹjọ ni idunkoko mọ fun awakọ Uber naa, Aleksander Bonchev ti to gẹẹ nitori awọn ero mii naa ti ṣe ikọlu fun un lẹyin wa.
Olupẹjọ James Scutt ṣalaye fun ileẹjọ pe awakọ Uber ọhun Bonchev sọ fun Mallet pe ko kuro ninu ọkọ oun.
O ni lẹyin naa ni Mallet bẹrẹ si ni ba Bonchev ja ti o si fọwọ ba a lori.
Ti were ba sun kan ogiri, were naa yoo pada, adia fun awakọ Uber to fesi pada pẹlu ẹṣẹ loju Mallet ti o si kan an mọlẹ.
Obinrin kan to wa pẹlu Mallet ni wọn sọ pe o fa a kuro nibi tawọn mejeeji ti jọ fija pẹta.
Olupẹjọ ni Ọgbẹni Mallet tun huwa ipa si awọn agbofinro nibi iṣẹlẹ naa.
Ṣugbọn agbẹjọro Mallet sọ fun ileẹjọ pe onibara oun kii ṣe onijagidijagan.
Lẹyin ọ rẹyin, ileẹjọ dajọ ẹwọn oṣu mẹfa fun Mallet pẹlu iṣẹ ilu fun ọjọ diẹ.
Iṣẹlẹ naa si tun mu awakọ Uber naa padanu iṣẹ rẹ lẹyin ti ko le lọ sibi iṣẹ nitori o farapa nibi iṣẹlẹ naa.
- Wo àwọn ojúṣe àti èèwọ̀ fún ikọ̀ ọlọ́pàá SWAT tó gba iṣẹ́ lọ́wọ́ SARS
- Ìjàmbá ọkọ̀ akérò àti tírélà pa èèyàn mẹ́rin lọ́nà mọ́rosẹ̀ Ore sí Benin
- Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé tó wáyé nibi ìwọ́de ENDSARS Nàìjíríà
- Ẹgbẹ́ Agbẹjọ́rò NBA ti kéde pé àwọn yóò ṣojú awọn Olùwọ́de #EndSARS lọ́fẹ̀ẹ́ nílé ẹjọ́
- Ọlọ́pàá mẹ́sàn án tó farapa nínú ìjàmbá ọkọ̀ Akure t'éèyàn méjì ti kú sì wà nílé ìwòsàn















