Obalende Building Collapse: Gbogbo àwọn to há sọ́bẹ́ ilé tó wó la mọ̀

Àkọlé fídíò, Ìya Emma oní POS ṣẹ̀ṣẹ̀ rékọjá lọ síbí ilé yẹn ni àtọmọdé, ó sì wó pa wọ́n - Láńlọọ̀dù Obalende

Igbakeji alaga ẹgbẹ awọn Lanlọọdu ni agbegbe Odo nibi ti ile alaja mẹta ti wo ni Obalende, Eko sọ fun BBC Yoruba pe bi mọlẹbi ni gbogbo awọn to n gbe ni Obalende.

O ṣalaye bi iṣẹlẹ̀ naa ṣe ṣakoba fun ọpọlọpọ idile. Ṣe ni arabinrin Ebun Ekemode n darukọ awọn to ba iṣẹlẹ naa rin ni kọọkan.

O menuba pe: "Gbogbo awọn to ṣẹlẹ si ko seyi ti ko lẹjẹ lọrun ninu gbogbo wọn.

Awọn to n ta ounjẹ, ọmọde to wọle lọ kirun, awọn oṣiṣẹ to n kọle gan gbogbo wọn lo ku sabẹ ile naa".

O fọn ipe si ijọba pe nibayii, gbogbo ipele ile kikọ ni ki ijọba maa wa yẹwo lati rii daju pe kii ṣe ayederu ohun elo ni wọn n lo.