EndSARS Ogbomosho: Gómìnà Makinde f'òkò kan pẹyẹ méjì nílé àwọn tó kàgbákò ìwọ́de EndSARS àti ààfin Soun

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Loju opo Twitter gomina Seyi Makinde, o jẹ ko di mimọ pe oun ti ṣe ibẹwo si idile mẹta ti awọn ọdọ mẹta ti ṣalabapade iku nitori iwọde EndSARS.
"A bẹrẹ igbesẹ yii nipa ṣiṣe moriya fun awọn idile naa fun adanu wọn a si tun ṣeleri lati ṣe ju bẹẹ lọ fun wọn".
"A ba gbogbo awọ́n to padanu eeyan lasiko iwde EndSARS kẹdun. Gẹgẹ bi ijọba, ako ni sare gbagbe ohun to ṣẹlẹ lẹnu ọjọ diẹ sẹyin yii to ja si iku Isiaka Jimoh, Ganiyu Moshood ati Adeoye Taiwo.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Bakan naa, gomina fidi ọrọ mulẹ pe oun ti ṣe ibẹwo si aafin Soun ti Ogbomoso to si ni oun ti jẹjẹ lati fun Kabiyesi ni Ọgrun miliọnu naira lati bẹrẹ atunṣe gbogbo nkan to bajẹ lasiko ti awọn olufẹhonuhan yabo aafin.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ṣé lóòtọ́ ni gómìnà Seyi Makinde fún Soun Ogbomoso ní N100 Miliọ̀nù láti tún ààfin ṣe?

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Lẹyin ọjọ meji ti awọn ọdọ ilu Ogbomoso yabo aafin lati lọ fẹhonuhan, a gbọ iroyin pe gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti ṣebẹwo si aafin Soun.
Iroyin to n tan kalẹ kan ṣugbọn ti a ko tii le fidi rẹ mulẹ tun sọ pe gomina Makinde paṣẹ lọgan pe ki wọn fun Soun ti Ogbomoso, Oba Jimoh Oyewumi ni Ọgọrun miliọnu naira lati tun aafin ṣe nibi ti awọn olufẹhonuhan EndSARS ti ba ọpọlọpọ nkan jẹ ni ọjọ Aiku ọjọ kọkanla oṣu kẹwa ọdun 2020.
Nigba ti BBC Yoruba kan si agbẹnusọ aafin Soun Ogbomoso, Toyin Ajamu sọ pe lootọ ni gomina ti ṣabẹwo si aafin ni nkan bii aago mọkanla owurọ si mejila lati wa ba wọn kẹdun iṣẹlẹ to ṣẹlẹ.
Lori ọrọ pe boya gomina Seyi Makinde fun Kabiyesi ni ẹbun owo ọgọrun miliọnu naira, Toyin Ajamu ni oun ko le sọ boya wọn fun Kabiyesi ni owo tori ko ṣe oju oun.
"Mi o mọ nipa iyẹn. Gẹgẹ bi alakoso ipinlẹ Oyo, ohun gbogbo to ba bajẹ o (gomina) ni lati ni atunṣe si i, boya o wa ran eeyan lati ri Kabiyesi ni kọrọ lati ṣe iyẹn, mi o le sọ".
Ọgbẹni Toyin to jẹ akọwe Kabiyesi ni Kabiyesi fi ọrọ sita lati rọ awọn ọdọ ki wọn ma ṣe jagidijagan tori gẹgẹ bi gomina ṣe s pe ainiṣẹ lo n fa ọpọlọpọ nkan bayii torinaa Kabiyesi rọ gomina lati pese iṣẹ fun awọn ti ko niṣẹ lọwọ.
"Ifẹhonuhan wa lab ofin ṣugbọn ki eeyan ṣe e ni alafia ni nkan to tọ".
O fi kun un pe ikọlu ti awọn ọdọ ṣe si aafin jẹ ohun to dun ni gan o si jẹ nkan iyalẹnu ṣugbọn ibinu o ṣe nkankan tori pe atawọn ọmọ to ba nkan jẹ, ati gbogbo ọmọ Ogbomoso, ọmọ Kabiyesi ni gbogbo wọn".
Gbogbo igbiyanju lati gbọ latẹnu ọfiisi gomina Seyi Makinde lori ọrọ owo naa titi di bi a ṣe n sọrọ yii ko tii so eso rere.
Wọ́n kò pa ẹnikẹ́ni sí ààfin Ṣọun Ogbomosọ, òkú tí àwọn ọdọ́ gbé wa ni ọlọ́pàá wọ́ jáde- Agbẹnusọ Ṣọ̀un
"Alaafia ti pada si aafin Ṣọun Ogbomọṣọ, koda aafin ni gbogbo wa sun mọju."
Eyi ni esi ti Agbẹnusọ fun Sọun Ogbomọṣọ, Ọgbẹni Toyin Ajamu lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori rogbodiyan to wa ye ni aafin naa lọjọ Aiku.
O ṣalaye pe alaafia ni aafin wa ki awọn ọdọ naa to yawọ aafin.
"Wọn ti bẹrẹ idarudapọ laarin ilu tẹlẹ, emi ati awọn oloye si lọ sibẹ lati pẹtu si wọn ninu l'orukọ kabiesi, amọ wọn ko ti ẹ jẹ ki a sọrọ.
Niṣe ni wọn n ju okuta si agọ ọlọpaa."
- Ààrẹ Buhari ṣèpàdé pẹ̀lú Ọ̀gá Àgba iléèṣẹ́ ọlọ́pàá lórí #ENDSARS, ẹ wo àbájáde ìpàdé wọ́n
- Gomina Kano tí ní kí olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ lọ rọ́kún nílé nítori o bu Ààrẹ Buhari lórí #EndSars
- #EndSARS: Pe nọ́mbà wọ̀nyìí láti fẹjọ́ ọlọ́pàá SARS sùn
- Sagamu: Ìkọlù wáyé bí ará ìlú ṣe gbéná wòjú ọlọ́pàá torí ikú agbábọ́ọ̀lù
- Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ l'Ogbomọṣọ, àwọn ọ̀dọ́ kọlu ààfin Ṣọun
- Adájọ́ pàṣẹ kí wọ́n fi ọlọ́pàá tó lọ́wọ́ nínú ikú Kolade Johnson sí àhámọ́
O ni ohun to mu awọn lọ sibi ti wọn ti n fa wahala ni pe lọ ni pe awọn ọlọpaa n pariwo si aafin lati wa a ba awọn ọdọ naa sọrọ gẹgẹ bi ọmọ ilu, nitori wọn n gbiyanju lati dana sun agọ ọlọpaa ni.
"Ṣugbọn, gbogbo igbiyanju wa lati da wọn lẹkun, to fi mọ awọn ikede ti a ṣe lori rẹdio, ni ko wọ wọn leti."
Agbenusọ Sọun fi kun un pe ko ti i ju iṣẹju mẹwaa ti wọn bẹrẹ ipade pẹlu minisita fun ọrọ ọdọ, Sunday Dare, to wa ba ẹbi ọmọkunrin ti ibọn ba lọjọ Satide, Jimoh Isiaka kẹdun, ti awọn ọdọ naa fi kọlu aafin, ti wọn si bẹrẹ si ni ju okuta sinu aafin.
O ni wọn ba nkan to pọ jẹ ni aafin.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Bdayo90
Lori iroyin to n lọ pe eeyan bi mẹjọ ni ọlọpaa fi ibọn pa, Ọgbẹni Ajamu sọ pe wọn o pa ẹnikẹni ninu aafin, ati pe oku ti awọn ọdọ naa gbe wa si aafin ni awọn ọlọpaa n wọ jade pada ninu fidio kan to wa lori ayelujara.
"Eeyan meji si lo ku, kii ṣe mẹjọ tabi mẹwaa ti wọn n pariwo.
"O ṣeeṣe ko jẹ aṣita ibọn lo ba awọn to ku, nitori pe awọn ọmọ kekere ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹwaa si mẹẹdogun ni ibọn ba.
Boya ibi ti wọn ti n woran ija laarin awọn ọlọpaa ati awọn to n ṣe iwọde ni ibọn ti ba wọn.
Ẹni ori yọ ipade di ile ni ọrọ da nilu Ogbomosho nibi ti awọn ọdọ kan ti yabo aafin Soun Ogbomoso.
Àwọn ọ̀dọ́ yabo ààfin, Ṣọun Ògbómọ̀ṣọ́ àti mínísítà sá àsálà fẹ́mi wọn
Lọwọlọwọ bo ṣe n kan wa lara ni pe awọn kan ti yabo aafin Soun Ogbomoso, Oba Oladunni Oyewumi Ajagungbade kẹta ti wọn si ti ba ọpọ dukia jẹ.
Iroyin sọ pe ṣe ni wọn kọkọ ṣe ikọlu si agọ ọlọpaa kan ni tosii aafin Soun ki wọn to raaye wọle si wọn lara.
- Gomina Kano tí ní kí olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ lọ rọ́kún nílé nítori o bu Ààrẹ Buhari lórí #EndSars
- EndSARS: Wo ohun táwọn gbajúgbajà tó n darí ìwọ́de ìfopinsí FSARS n sọ
- Ààrẹ Buhari kí Akeredolu kú orííré bí ó ṣe jáwé olúborí nínú ìdìbò sípò gómínà
- Tani Akeredolu tó wọlé láti tukọ̀ ìṣàkóso ípìnlẹ̀ Ondo lẹ́ẹ̀kejì yìí?
BBC Yoruba kan si akọwe aafin Soun Ogbomoso, Arakunrin Totin to si jẹ ko di mimọ pe ẹni ori yọ o dile ni tori awọn n sa asala fun ẹmi awọn.
Bakan naa ni Minisita fun ọrọ awọn ọdọ Naijiria, Sunday Dare, to wa laafin Soun lasiko iṣẹlẹ yi fi han pe tootọ ni iṣẹlẹ yi waye.

Oríṣun àwòrán, Twitter/@afobaje1000
Loju opo Twitter Sunday Dare to jẹ ọmọ bibi Ogbomoṣo, ni awọn janduku ya bo aafin Soun ti wọn si da ipade igbimọ ilu tawọn n ṣe lọwọ, ru.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
O ni bi wọn ṣe n sọ oko ni wọn n fọ ilẹkun ati gilaasi ninu aafin naa.
Gẹgẹ bi a ti ṣe gbọ awọn ọdọ ti kọkọ ṣe iwọde lọ si aafin naa lati fẹhonu han lori iku Isiaq Jimoh ti wọn yinbọn pa nibi iwọde ENDSARS lọjọ Abamẹta.

Oríṣun àwòrán, Twitter/@IsaacIfeoluwa9
Nigba ti awọn ọdọ yi de aafin, wọn ko ba nkan jẹ ṣugbọn ko pẹ si igba ti wọn kuro lawọn janduku kan yabo aafin lasiko ti Minsisita ati Soun n ṣe ipade.
Bo tilẹ jẹ pe a ko le sọ boya ẹnikẹni farapa nibi rogbodiyan naa, awọn iroyin ati aworan, ati fidio to wa lori ayelujara n sọ pe awọn kan ku.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Bdayo90
Gómìnà Seyi Makinde bá ẹbí Isiaq Jimoh tó kàgbákò ikú òjijì dárò
Gomina Seyi Makinde to n tukọ ipinlẹ Oyo ti kẹdun iku ọmọdekunrin ti wọn yinbọn lu lasiko iwọde ENDSARS to waye nilu Ogbomoso.
Makinde ni Jimoh Isiaq pada ku lẹyin ti wọn gbe e lọ si ile iwosan fasiti Bowen University ni Ogbomosho.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Seyi Makinde
Yatọ si Jimoh, Makinde tun ba awọn mọlẹbi Abdulrasaq Olawale, Oluwadamilare Gbohunmi ati awọn marun un mii ti wọn farapa kẹdun.
O ni awọn wọnyi n gba itọju lọwọ ni ile iwosan .
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Igba akọkọ ree ti ẹnikankan labẹ ijọba yoo gba pe ibọn ba Jimoh Isiaq.
O ni iṣẹlẹ yi jẹ eyi ti ko yẹ ko waye ati pe oun ti kan si Kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Oyo lati tọ pinpin ohun to fa iṣẹlẹ yi.
Ṣaaju ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo sọ fun BBC pe awọn ko yin ibọn lu awọn oluwọde ati wi pe afẹfẹ gaasi tajutaju lasan ni awọn yin lu awọn to yabo agọ ọlọpaa
Makinde ni iwọde ENDSARS ṣafihan bi nkan ko ṣe rọgbọ lawujọ mọ to si tun ni o mu ki eeyan maa ṣeemọ bi agbara ko ti ṣe si lọdọ Gomina ti wọn pe ni alaṣẹ ijọba ipinlẹ.
Ni bayi o ti wa pinnu lati kan si awọn mọlẹbi ọmọdekunrin ti wọn yinbọn pa yi to si ni oun yoo ri i pe iwadii ọfintoto waye lori awọn to mọ nipa iku rẹ.

Ọmọkùnrin tí wọ́n yìnbọn fún ni Ogbomosho ti dágbere fáyé
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, agbẹjọrò tó wà lórí ọ̀rọ̀ yìí, Hussein Afolabi nígbà tó bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ sàlàyé pé, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo sọ pé àwọn kò yin ìbọn tàbi tajútaju fún àwọn olùwọ́de.
Agbẹ́jọrò náà ní gẹ́gẹ́ bi àgbẹnusọ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ Ipinlẹ Oyo ni, Olugbega Fadeyi ṣe sọ, ó ni area Commander ti òun pè sàlàyé pé, kìí ṣe ọlọ́pàá ló yìn ìbọ̀n nílú Ogbomosho.
O ní: ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé agbẹnusọ ọlọ́pàá padà sọ fún àwọn akọròyìn pé, wọ́n yin tájútaju sí wọ́n, èyí túmọ̀ sí pé ǹkankan wà níbl tí wọ́n kò sọ.
- Àwọn Ọba Yorùbá kan rèé tí wọ́n rọ̀ lóyè, tí ọba míràn jẹ lójú ayé wọn
- Ìpalẹ̀mọ́ aráàlú àti agbófinró fétò ìdìbò dójú ọ̀gbagadè ní Ondo
- Wo bí ìwọ́de #ENDSARS tí Toyin Abraham ṣe nípínlẹ̀ Oyo ṣe lọ
- Ọlọ́pàá f'ẹsẹ̀ fẹ́ẹ l'Eko lẹ́yìn tó ki ìbọn bọ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ lẹ́nu tó sì yìn ín
- Ìbò aráàlú pẹ̀lú ẹ̀yà yókù lá fi yanjú àtúntò Nàíjíríà - YCE
- Ìdí tí Gúúsù Akure, Owo àti ìwọ̀orun Ondo yóò fi sọ ẹni tí yóò jáwé olúborí nínú ìbò gómìnà Ondo
Níbayìí Afolabi ni ǹkan ẹyọ kan ti àwọn ń bèrè fún ni pé kí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá mú ẹni tó ṣe irú iṣẹ́ ibi náà jáde
Hussein Afolabi ní kìí ṣe Isiaq nìkan ko ni ọlọ́pàá yìn níbọ̀n, àwọn méjì míràn wà ní ilé ìwòsàn níbi ti wọ́n ti n gba ìtọ́jú
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5
Ó fi kun un pé gbogbo ìgbésẹ̀ tó yẹ ni ò ń gbé lọ́wọ́ láti túṣu désàlẹ̀ ìkòkò ọ̀rọ̀ náà.
Hussein ni ṣe ariwo ti awọn eeyna n pa naa kọ ni yii lasiko yii.
O fi idaniloju han pe gbogbo iwadii to yẹ ni wọn yoo ṣe bayii.

Oríṣun àwòrán, Twitter/iam_wandeyinka
Ogbomosho Shooting: Irọ́ ni pé a yìnbọ̀n lú olùwọ́de EndSars - Ọlọ́páà
Oju opo Twitter n gbana jẹ lori iroyin to gbode pe awọn ọlọpaa yinbọn lu arakunrin oluwọde kan lọjọ Abamẹta.
Iroyin naa jẹ eyi to ti mu iriwisi orisirisi wa latari fọnran fidio arakunrin kan tawọn oluwọde n gbe digba digba pẹlu ẹjẹ lara rẹ.
BBC ko ribi fidi otitọ fọnran fidio yii mulẹ ṣugbọn iroyin to tẹwa lọwọ lọdọ awọn to wa ni Ogbomosho ni ikọlu waye laarin awọn oluwọde ati ọlọpaa.
Ẹri ti a gbọ wi pe ikọlu waye ni eyi to han ninu fidio kan ti gbajumọ ori ayelujara Lekan King Kong fi sita nibi ti awọn oluwọde ti n figbe ta pe ọlọpaa n yinbọn lu awọn.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Iwọde naa jẹ ọkan lara awọn eleyi to n waye jakejado Naijiria lati fi pe fun iwọgile ikọ ọlọpaa FSARS ti ara ilu ni wọn dẹgun le awọn pupọ.
Nigba ti BBC Yoruba pe ago alukoro ọlọpaa ipinlẹ Oyo Fadeyi Olugbenga lati fi mọ nkan to n ṣẹlẹ gaan, o ni ko si ohun to jọ bẹ.

Oríṣun àwòrán, Twitter/tonaishere
''A kan tu awọn oluwọde ka nigba ti wọn fẹ yabo ileeṣẹ ọlọpaa ni Ogbomosho ni. A ko yinbọn bẹ si ni ko si ẹni ti ibọn ba tabi to ku''
Fadeyi ṣalaye siwaju pe awọn oluwọde naa fẹ fipa bori awọn ọlọpaa ni ṣugbọn awọn ko gba fun wọn.
O ni lọwọ bayi, alafiaa ti pada si ilu Ogbomosho.
















