Restructuring in Nigeria: YCE fẹ́ pè fún ìbò lórí àtúntò Naijiria pẹ̀lú ẹkùn yóòkù

Ẹgbẹ awọn agbagba ni ilẹ Yoruba, YCE ti kede igbaradi wọn, lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹkun to ku ni Naijiria fun atunto.
Awọn agbagba naa sọrọ ni ilu Ibadan nigba ti adari wọn, Adajọ agba 'Demola Bakre (retd.) ba awọn oniroyin sọrọ.
Bakre ni idibo awọn ọmọ Naijiria lati mọ ipinnu wọn lori atunto orilẹede Naijiria ni ọna abayọ, kii ṣe ki a fi ojojumọ ma a yi ofin orilẹede Naijiria pada.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọlọ́pàá f'ẹsẹ̀ fẹ́ẹ l'Eko lẹ́yìn tó ki ìbọn bọ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ lẹ́nu tó sì yìn ín
- Iyabo Ojo sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ abẹ tó ṣe, Nkechi Blessing ra ǹkan irinsẹ fún arọ
- Ọjọ́ ìdájọ́ déé! Wọ́n dájọ́ ikú nípa yíyẹgi fún David West tó ń pa àwọn obìnrin ní PortHarcourt lónìí
- Ẹ gbà mí o! Bí mo ṣe ń dàgbà ni ǹkan ọmọkùnrin mi ń tóbi síi àmọ́ obìnrin ni mi'
- Àwọn tó jí mi gbé ti fẹ́ẹ̀ pa mí, kí àwọn ọlọ́pàá tó dóòlà mi - Agbẹjọ́rò Bisola Ajayi
''Ofin Naijiria ti ọdun 1999 ṣe eke nipa sisọ wi pe awọn ọmọ Naijiria lo kọ ọ, nigba ti o jẹ wi pe awọn eniyan perete lo parapọ gbe ofin naa kalẹ.''
''Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ko gbọdọ fi falẹ mọ, nipa gbigbe abadofin ti yoo fayegba awọn ọmọ Naijiria lati dibo boya wọn fẹ atuntọ Naijiria abi bẹẹ kọ.''
Ẹgbẹ awọn agbagba nilẹ Yoruba naa ni o kọ awọn lominu, pẹlu bi aarẹ Buhari ati ijọba rẹ ṣe kọ eti ikun, si ibeere awọn eniyan fun atunto orilẹede Niajiria.
Bakan naa lori ijinigbe to wọpọ ni ilẹ Yoruba, YCE ni asiko ti to fun awọn gomina lati ṣiṣẹ ni kiakia, lori ikọ Amọtẹkun ki wọn le tete bẹrẹ iṣẹ.
Ninu ọrọ rẹ, Bakre ni ọwọ awọn gomina ni ilẹ Yoruba ni ọrọ naa kusi, nitori awọn Ile Igbimọ Asofin ni ipinlẹ kọọkan ti buwọlu abadofin naa, ti wọn si ti bẹrẹ igbanisiṣẹ lati koju ijinigbe lagbegbe wọn.
Apẹẹrẹ awọn orilẹede to ti ṣe ibo lati yapa kuro lara ajọ kan ni Ilẹ Gẹẹsi .ti wọn kuro ni Ajọ Ilẹ Yuroopu (EU), lẹyin ti awọn eniyan dibo( referendum) lati kuro.














