Gracious David-West, afurasí tó fẹ̀mí ọ̀dọ́bìnrin mẹ́sàn án ṣòfò nílé ìtura PortHarcourt gbàdájọ́ ikú lónìí

David West

Ti irọ ba lọ logun ọdun, awọn Yoruba ni ọjọ kan ṣoṣo lotitọ yoo ba a.

Iroyin taa gbọ́ ni wipe ile ẹjọ ilu PortHarcourt ti dajọ iku nipa yiyẹgi fun afurasi apaayan, Gracious David West ti wọn ni o n pa awọn obinrin kaakiri ilu PortHacourt ti ọwọ si tẹ ni nkan bii oṣu melo sẹyin.

Ẹsun ipaniyan ọdọbínrin mẹsan an kaakiri awọn ile itura niluu Port Harcourt ni wọn fi kan David-West ti adajọ to da ẹjọ rẹ, Adolphus Enebeli ṣe fi lede.

Afurasi mii ti orukọ rẹ n jẹ Nimi Thankgod, oun naa gba idajọ lori ẹsun pe o tabuku oku eeyan.

Igbẹjọ naa ti n lọ fun bi ọdun kan lẹyin tawọn eeyan bẹrẹ si ni ri oku awọn ọdọbinrin kaakiri ile itura niluu Portharcourt, ọna kan naa si ni gbogbo wọn n gba ku.

Awọn ọdọbínrin mẹsan an ti afurasi David-West ṣekupa niyii:

1. Maureen Ewuru l'ọgbọnjọ oṣu keje, 2019 nile itura Hotel D/Line.

2. Wọn ri oku Jennifer Nkwocha ni Venice Hotel GRA Phase 2, Port Harcourt lọjọ kẹrinla oṣu kẹjọ ọdun 2019.

3. Ni Toki Hotel Port Harcourt wọn ti ri oku Blessing Effiong.

4. Linda Waripa ku si Avery Guest House, Oyigbo lọjọ kẹfa oṣu kẹsan an, 2019 ni Port Harcourt.

5. Dorcas Francis ni wọn rí oku tiẹ ni Imperial Hotel Trans Amadi, Port Harcourt lọjọ kẹsan an oṣu kẹsan an ọdun 2019.

6. Wọn ri oku Rose Samuel ni Lasus Steve Hotel ni Omoku lọjọ kejila oṣu kẹsan an ọdun 2019.

7. Kelechi Bridget Onuoha ku si Pachik Hotel lọjọ kẹtala oṣu kẹsan an ọdun 2019.

8. Lọjọ kejidinlogun oṣu kẹsan an ọdun 2019 ni won ri oku Patience Hamo ni Torox Guest House ni Port Harcourt.

9. Anthonia Ibe ku si TM Hotel Wimpey Port Harcourt.

Benita Etim nikan lo mori bọ.

Ọga ọlọpaa ipinlẹ Rivers lasiko naa, Dandaura ṣalaye pe yatọ si awọn obinrin mẹsan an yii, David-West tun jẹwọ pe oun tun ṣekupa obinrin kan niluu Eko, ọkan ni Owerri, omiran ni Sapele, ọkan ni ilu Aba, ọkan ni Benin ati ọkan ni ilu Ibadan.

Pẹlu mẹsan an niluu Port Harcourt, obinrin mẹẹdogun lo jẹ lapapọ ti afurasi naa sọ dero ọrun alakeji.

Àkọlé fídíò, ''Ẹ gbudọ̀ ṣe àwọn ǹkan wọ̀nyí lọ́jọ́ ìdìbò gómìnà l'Ondo bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ...'