Bisola Ajayi: Àwọn ọlọ́pàá dóòlà agbẹjọ́rò tí wọ́n jígbé ní Port Harcourt

Ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n gbogun ti ijinigbe nipinlẹ Rivers, ti doola agbẹjọro, ẹni ọdun mẹẹdọgbọn kan, Bisola Ajayi lọwọ awọn ajinigbe.
Ọjọ Aiku to kọja ni iroyin jade sori ayelujara pe, awọn ajinigbe ti gbe agbẹjọro obinrin kan, Bisola Ajayi, nipinlẹ Rivers.
Ile rẹ to wa ni agbegbe Rumuokwurusi, nijọba ibilẹ Obio-Akpor, nilu Port Harcourt ni wọn ti ji i gbe lọjọ kẹrin, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020.
Kọmisanna ọlọpaa ni Rivers, Joseph Mukan, sọ fun awọn akọroyin pe oru Ọjọru, ọjọ keje, oṣu Kẹwaa, ni awọn ọlọpaa yabo igbo kan ni Okomoko, Etche, ti ko ju irinajo iṣẹju mọkandinlọgbọn lọ si papakọ ofurufu ilu Port Harcourt.
Nibẹ ni wọn ti doola Bisola, ati ọkunrin kan, Paul Nyulaku.
Nyulaku ni wọn kọkọ jigbe lọjọ naa, ki wọn to fi ọkọ ayọkẹlẹ rẹ, gbe Bisola.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ti awọn ọlọpaa doola rẹ, Bisola sọ pe iwaju ẹbi rẹ ni wọn ti gbe e, ti wọn si gbe e lọ si ibi ti oun ko mọ.
Wọn sọ fun un pe awọn ti pa gbogbo ẹbi rẹ, ti wọn si beere fun aadọta miliọnu Naira, owo itusilẹ rẹ. Ṣugbọn nigba ti yoo fi di ọjọ keji, wọn ti sọ ọ di miliọnu lọna igba Naira.

Oríṣun àwòrán, Bisola Ajayi
Bisola sọ pe oun dupẹ lọwọ Ọlọrun pe awọn ọlọpaa tete doola oun, nitori pe wọn ti pinnu lati pa a nigba ti iroyin ijinigbe rẹ ti n tan kiri.
Ẹnikeji ti awọn ọlọpaa doola, Nyulaku, ni awọn ajinigbe naa kọkọ gbe ni nkan bi aago mẹfa irọlẹ ọjọ Aiku, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹwa.
Nibi to ti lọ fun ọrẹ rẹ kan ni nkan, ni awọn ọkunrin kan to wọ aṣọ ọmọ ologun ti dena de e.
"Wọn sọ fun mi pe ọlọpaa ni awọn, ki wọn o to fi ipa wọ inu ọkọ mi. Wọn fun mi mọlẹ. Bi mo ṣe n gbiyanju lati gba ara mi silẹ, ni awọn fi ibọn gba mi, ti ara mi si n sẹjẹ.
"Wọn lu mi pupọ, titi mo fi ṣe bi ẹni pe mo ti daku. Nigba naa ni wọn to o gbe mi lọ si ibi ti mi o mọ."
Nyulaku sọ pe ogun milọnu Naira ni wọn beere fun lọwọ oun, ti wọn si n finna mọ ko le tete sọ fun mọlẹbi rẹ lati san owo naa.

Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ rivers, Mukan sọ pe ọkan lara awọn ajinigbe naa, Chinedu Chigbu, ẹni ọdun mọkandinlogoji, fi ara pa lasiko ti awọn ọlọpaa doju ija kọ wọn. Wọn gbe e lọ sile iwosan, amọ o pada ku.
Awọn ajinigbe to ku sa wọ inu igbo, amọ awọn ọlọpaa ba ibuba wọn jẹ, wọn si tun ko ibọn aK-47 kan, ibọn magasinni kan, ati ọgọrun ọta ibọn.













