Sotitobire: Iléẹjọ́ ṣún ìgbẹ́jọ́ síwájú di ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù Kẹta ọdún 2020

Ile ẹjọ giga tilu Akurẹ ti sun igbẹjọ siwaju lori ẹsun ijọmọgbe ti wọn fi kan olori ijọ Sotitobi rẹ, Alfa Babatunde.
Babatunde, lasiko ti wọn gbe de ọgba ileẹjọ, wọ agbada alawọ eweko, ati obinrin kan ninu ijọ rẹ, ti wọn jọ n jẹjọ, wa laarin awọn osisẹ ọgba ẹwọn to gbe wọn wa sile ẹjọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mò ń tọ̀ s'ára ni mo fi gba ara à mi l'óko ẹrú ní Omar
- Ìgbẹ́jọ́ aṣaájú ìjọ Sotitobire kúrò nílé ẹjọ́ Mágísíréètì lọ sílé ẹjọ́ gíga l‘Akure
- Ẹ fi èmi àti àwọn alága káńṣù APC sílẹ̀, ká yanjú aáwọ̀ wa nítùbí-ǹnùbí - Makinde bẹ iléẹjọ́
- Ìjà dópin, ogun tán lórí ìrọ̀lóyè Trump, ilé aṣòfin àgbà ní kó máa bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ
- Ọlọ́pàá tó pa èèyàn pokùnso lọ́jọ́ kejì tó dé àhámọ́ àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́
- Ẹ dẹ́kun dídá abẹ́ fún ọmọbìnrin torí ọ̀pọ̀ ewu tó ń bẹ lọ́jọ́ iwájú nídìí rẹ̀ - Onímọ̀
- Àwọn ọlọ́kadà alákatakítí ẹ̀sìn tí wọ ìpínlẹ̀ Eko - Charly Boy
Lasiko igbẹjọ to waye lọjọbọ, adajọ to n gbọ ẹjọ naa faake kọri lati gba oniduro Babatunde, to si ni ki wọn da pada si ọgba ẹwọn.

Ileẹjọ ti wa kede pe oun sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ Aje, ọjọ Kẹrindinlogun osu Kẹta ọdun 2020.
Ilẹẹjọ́ gíga Akure ti kún fọ́fọ́ fún ìgbẹ́jọ́ olórí ìjọ Sotitobire

Oríṣun àwòrán, Others
Saaju lati kọ mu iroyin wa fun yin pe, ta ba da ọjọ, ọjọ a pe, ta ba da igba, igba yoo ko, bo si pẹ titi, ogun ọdun n bọ wa ku ọla.
Ọjọbọ tun ni ọjọ ti wọn da pe lati tẹsiwaju ninu igbẹjọ ẹsun ijọmọgbe ti wọn fi kan asaaju ijọ Sotitobire, Alafa Babatunde.
Lọwọ-lọwọ bayii, pitimu nile ẹjọ kun fun awọn akọroyin, ero iworan, awọn agbẹjọro, igun olupẹjọ ati awọn ọmọ ijọ Sotitobire, ti wọn wa se atilẹyin fun asaaju ijọ wọn to n jẹjọ lọwọ, ki wọn si tun foju se mẹrin rẹ lẹẹkan si.

Bẹẹ ba gbagbe, Ọjọru ana ni wọn sun igbẹjọ naa siwaju di Ọjọbọ oni nitori pe ijọba ipinlẹ Ondo gbe ẹjọ ọhun kuro nile ẹjọ Magisireti lọ sile ẹjọ giga.
Olujẹjọ gboogi ninu ẹjọ naa, Alfa Babatunde ko si yọju sile ẹjọ lọjọbọ nitori pe wọn ti sun igbẹjọ naa siwaju amọ awọn agbẹjọro rẹ fọwọ gbaya pe yoo yọju sile ẹjọ loni.

Igba akọkọ si ree ti olujẹjọ naa yoo jọju sile ẹjọ giga nilu Akurẹ nitẹsiwaju ẹjọ naa, bi igbẹjọ naa ba si se waye loni, laa maa mu wa fun yin.
Ẹ ku oju lọna.












