Human Trafficking: Iṣẹ́ tíṣà ni wọ́n sọ pé màá ma ṣe ní Dubai, oko ọmọ ọ̀dọ̀ ni mo ba ara mi ní Oman

Temitope kawe jade ni fasiti ni orilẹ-ede Naijiria, to si ti n ṣe iṣẹ aje diẹdiẹ ko to o di pe o gbiyanju lati lọ si ilẹ okeere.
Àkọlé àwòrán, Temitope kawe jade ni fasiti ni orilẹ-ede Naijiria, to si ti n ṣe iṣẹ aje diẹdiẹ ko to o di pe o gbiyanju lati lọ si ilẹ okeere.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Arabinrin Temitope (kii ṣe orukọ abisọ rẹ) sọ ohun gbogbo ti oju rẹ ri lasiko to ti ipasẹ awọn eniyan kan lọ ṣiṣẹ nilẹ okeere.

Temitope kawe jade ni fasiti ni orilẹ-ede Naijiria, to si ti n ṣe iṣẹ aje diẹdiẹ ko to o di pe o gbiyanju lati lọ si ilẹ okeere.

Lasiko to n kopa lori akanse eto BBC Yoruba, Temitope ni oun ti n ta ounjẹ ni Naijiria lẹyin ti oun pari ileewe giga, ki wọn to sọ fun oun pe, awọn eniyan kan wa to lee gbe oun lọ silu oyinbo, lati le ri owo kojọ.

Akanse eto naa lori Facebook BBC Yoruba ree:

O ṣalaye pe ainitẹlọrun, awọn ọrẹ ti eniyan n ba arin, ati aini aato fun igbe aye ẹni lo maa n jẹ ki ọpọlọpọ bọ si ọwọ awọn to n muniṣowo ẹru.

Iṣẹ aje ati ọna lati la lo gbe Temitope lọ si ilẹ okeere lẹyin to sinru ilu tan, ko to o di pe o bọ sọwọ awọn to fi awọn to sọ pe awọn yoo ba wa iṣẹ olukọ nilu Dubai, ti yoo si maa gba owo gọbọi.

Àkọlé fídíò, Human trafficking: Iṣẹ́ irun ṣíṣe ló di iṣẹ́ aṣẹ́wó

Ẹyin o rẹyin ni wọn tun sọ fun pe ilu miran, Omar, ni awọn yoo mu u lọ. O gba lati tẹ le wọn, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe oko ọmọ ọdọ ni wọn ta a si l'ọhun.

Oriṣiriṣi nkan bi ki wọn o maa fi ọwọ gba nidi ati ọmu ni oju rẹ ri. O sọ ọ debi pe ọkọ ọga rẹ maa n fi ibalopọ lọ ọ.

O sọ pe majele ni wọn yoo fun ẹnikẹni to ba gba lati ba ọkọ ọga rẹ lopọ jẹ.