ALGON Oyo: Àwọn alága káńṣù APC fẹ́ kí ẹjọ́ ọ̀hún tẹ̀síwájú

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, @MakindeMedia

Ijọba ipinlẹ Oyo ti gbe igbesẹ lati pari rogbodiyan to n waye ni itubi inubi, laarin rẹ ati awọn alaga Kansu, to ni ki wọn lọ rọkun nile.

Agbẹjọro fun ijọba, Akin Onigbinde lo sọ ọrọ naa niwaju adajọ Mashud Abass, nibi igbẹjọ to n lọ lọwọ lori họwuhọwu to bẹ lẹyin idaduro awọn alaga ọhun.

O ni ijọba ti pinnu pe ki wọn lọ yanju ọrọ naa laarin ara wọn, ki alaafia lee jọba nipinlẹ Oyo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Onigbinde sọ fun adajọ naa pe, wọn yoo pada si ile ẹjọ ti wọn ba kuna lati pari aawọ laarin ara wọn.

Ṣugbọn awọn agbejọro fun awọn alaga ijọba ibilẹ ti wọn da duro, Niyi Akintola ati Kunle Sobolaju sọ pe, igbesẹ yii ko tẹ awọn lọrun.

Wọn ni ile ẹjọ gbọdọ da ẹjọ naa nu, ki wọn to lee pari aawọ naa ni itubi inubi.

Ami idamọ ẹgbẹ awọn alaga ijọba ibilẹ

Oríṣun àwòrán, Oyo Algon

Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro mejeji, adajọ Mashud Abass ki awọn agbẹjọro ku iṣẹ takuntakun, to si ni ki wọn lọ yanju ẹjọ naa laarin ara wọn, ki wọn si tun ri daju pe alafia jọba nipinlẹ Oyo.

Àkọlé fídíò, Sanya Adegbaye blind Yoruba teacher: Torí kí ojú mi lè là ni gbogbo owó Kòkó bàbá mi run sí

Ile ẹjọ ọhun wa sun ẹjọ naa si ọjọ kejila Oṣu Keji ọdun 2020, lati mọ ibi ti ọrọ de duro, bi bẹẹkọ, oun yoo tẹsiwaju lati gbọ ẹjọ naa.

Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Karun un ọdun 2019 ni gomina Seyi Makinde yọ awọn alaga ijọba ibilẹ naa bi ẹni yọ jiga, to si yan awọn alaga fidihẹ.

Sugbọn awọn alaga naa fẹ fi tipatipa pada ṣẹnu iṣẹ eyi to da rogbodiyan silẹ.