Hanged Policeman: Iléeṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ní ṣòkòtò ni afurasí ọ̀hún lò láti pa ara rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Ọlọpaa kan ti wọn ti mọle lori ẹsun pe o pa eniyan ti fi ọwọ ara rẹ gbẹmi ara rẹ ninu ahamọ.
Iroyin naa ni se ni ọlọpaa ọhun, pokunso ninu ahamọ ti wọn fi si nileesẹ awọn ọlọpa ọtẹlẹmuyẹ CID to wa ni Panti ladugbo Yaba, nilu Eko.
A gbọ pe ọlọpa naa, ti wọn pe orukọ rẹ ni Essien ni wọn gbe wa si ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ naa lọjọ Isẹgun to kọja lori ẹsun pe o pa ọkunrin kan nibudo ifọpo Dangote.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ dẹ́kun dídá abẹ́ fún ọmọbìnrin torí ọ̀pọ̀ ewu tó ń bẹ lọ́jọ́ iwájú nídìí rẹ̀ - Onímọ̀
- Àwọn ọlọ́kadà alákatakítí ẹ̀sìn tí wọ ìpínlẹ̀ Eko - Charly Boy
- Bàálù já lulẹ̀,o pín sí mẹ́ta,èèyàn 52 f'arapa
- Íbùdó amúnáwá to gbiná sọ Ibadan,Ṣakí àti Ìséyìn si òkùnkùn biribiri
- Ìgbẹ́jọ́ aṣaájú ìjọ Sotitobire kúrò nílé ẹjọ́ Mágísíréètì lọ sílé ẹjọ́ gíga l‘Akure
Essien, ẹni ti ọwọ tẹ pẹlu awọn eeyan mẹta miran, lawọn ọtẹlẹmuyẹ fọrọ wa lẹnu wo, ti wọn si fi sinu ahamọ fun itẹsiwaju ifọrọwanilẹnuwo wọn.
Amọ, ọtọ ni nkan ti Essien n ro lọkan nitori se lo lo sokoto to wọ sidi lati fi pokun so to si gbẹmi ara rẹ.

Oríṣun àwòrán, PoliceNG
Ọlọpa kan, lasiko to n gbarata lori isẹlẹ naa ni "Ọpọ eeyan lo maa n beere pe ki ni idi ti awọn ọlọpa se maa n ni ki afurasi bọ asọ ko to wọ inu ahamọ ti wọn ba fẹ fi pamọ si?"
"Ọkan lara idi ta fi maa n se bẹẹ ree. Afurasi to pa eeyan lee ro pe dipo ki oun la isoro igbẹjọ kọja nile ẹjọ, o kuku san fun oun lati gbẹmi ara oun, idi si ree tawa ọlọpa fi maa n ni ki afurasi bọ asọ, ko to wọ inu ahamọ."
Kọmisana ọlọpa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, si ti pasẹ pe ki wọn sewadi lẹkunrẹrẹ lori ọrọ naa, ti iwadi nipa isẹlẹ naa si n tẹsiwaju.













