Charly Boy: Mo faramọ́ bí ìpínlẹ̀ Eko ṣe fòfin de ọ̀kadà!

Oríṣun àwòrán, Instagram
Baba isalẹ awọn ọlọkada ni ipinlẹ Eko, Charles Oputa, ti awọn eniyan n pe ni Charly boy ti sọrọ lori bi ijọba ṣe gbẹṣẹlẹ wiwa ọkada ni awọn opopona ati agbeegbe kan ni ipinlẹ Eko.
Charly Boy to bu ẹnu atẹ lu awọn ọlọkada to wa ni ita bayii, sọ wi pe oun faramọ igbeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko.
'Area fada’ fi ero rẹ han lori oju opo ikansiraẹni Instagram, lẹyin to sọ wi pe awọn eniyan n woye idi ti oun fi dakẹ lori iṣẹlẹ naa.
Pajawiri ni Charly Boy pe akori ọrọ rẹ oun, wi pe ki awọn eniyan kiyesi ara ni agbeegbe wọn, nitori pe awọn ẹlẹsin jagidijagan ti wọle si ipinlẹ Eko.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
O ni iwadii oun pẹlu olori awọn ọlọkada fihan wi pe awọn ti oun ṣe atilẹyin fun tẹlẹ, ti wọn jẹ awọn ti wọn kawe kọ ni wọn wa nibẹ bayii.
Charly Boy ni awọn ọlọkada miran, Shia ni wọn pẹlu awọn miran ti wọn ko tilẹ mọ ẹsin wọn, nitori ọna ti wọn yatọ si ti awọn musulumi miran.
Baba isalẹ awọn ọlọkada naa wa parọwa si awọn eniyan ati ijọba lapapọ lati lo awọn eniyan fun ofintoto fun eto aabo to peye ni ipinlẹ Eko ati Naijiria lapapọ.
Ọlọ́pàá fi pańpẹ́ mú ọlọ́kadà 25 lórí làáṣìgbò tó wáyé ní Iyana Ipaja
Ile iṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ti ni ọwọ sinkun ọlọpaa ti tẹ awọn ọlọkada mọkanlelogun ti wọn da rogbodiyan silẹ ni agbeegbe Iyana Ipaja ni ipinlẹ Eko.

Oríṣun àwòrán, Others
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Bala Elkana lo sọ ọrọ yii fun BBC Yoruba, lasiko to n sọrọ lori rogbodiyan to sẹlẹ laarin awọn ọlọpaa ati awọn ọlọkada ni agbeegbe naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Elkana ni awọn ọlọkada naa lo ṣe ikọlu si awọn ọlọpaa ti wọn n ṣiṣẹ ti ijọba gbe le wọn lọwọ, lati ri pe ko si ọlọkada to n gba awọn opopona ti wọn ti fofin de e ni ipinlẹ Eko, ki awọn ọlọkada ma ṣiṣẹ nibẹ.

Oríṣun àwòrán, Others
O ni igbesẹ awọn ọlọpaa amuṣẹya to ko ọkada wọn ni ibi ti wọn ti n fi ṣiṣẹ naa lo bi wọn ninu, ti wọn fi wa ṣe ikọlu si awọn ọlọpaa to n sọ opopona agbeegbe Iyana Ipaja.
Agbẹnusọ ileesẹ ọlọpaa naa ni ikọlu si awọn ọlọpaa yii ko ba ju bẹẹ lọ, ti ko ba ṣe bi awọn ṣe ran iranwọ si wọn, ti ọwọ ọlọpaa si tẹ awọn mọkanlelogun ninu awọn ọlọkada naa.

Oríṣun àwòrán, Others
Elkana ni awọn n gbe awọn ọlọkada ti ọwọ tẹ naa lọ si ile ẹjọ lati jẹjọ ẹsun ti tapa sofin ijọba, ati ṣiṣe ikọlu si awọn agbofinro ni ẹnu iṣẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Awọn eniyan to fesi loju opo Twitter naa sọ ohun ti oju wọn ri ni agbeegbe naa lasiko ti rogbodiyan yii bẹẹ silẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Amọ awọn ti ọrọ naa soju wọn sọ wi pe awọn ọlọkada naa n fẹhọnu han pe awọn ajọ amuṣẹya naa kọja ibi ti ijọ̀ba ni ki wọn ti mu awọn ọlọkada.
Ọlọ́kadà àti ọlọ́pàá wọ̀já ìjà l'Eko, ọ̀rọ̀ di bóò lọ, o yàgò fún mi

Oríṣun àwòrán, Others
Saaju la ti mu iroyin wa pe, rogbodiyan gba agbegbe Iyana Ipaja nilu Eko kan lọsan ọjọru eyi to n waye laarin awọn ọlọpaa ati awọn ọlọkada.
Gẹgẹ bi iroyin naa ti wi, awọn osisẹ ọlọpaa amusẹ nipinlẹ Eko lo n wọ inu ile ladugbo naa lati se awari awọn eeyan to ni ọkada, ti wọn si n gbe ọkada wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Isẹlẹ ọhun to bẹrẹ lopona Raji Rasaki ni Iyana Ipaja lo mu ki wahala naa fọnna soju, tawọn ọdọ si n dana sun taya mọto, bẹẹ ni wsn n gbe idi dina.

Oríṣun àwòrán, Others
Bakan naa lawọn ọdọ ọhun n na igi soke, wọn n ju okuta kaakiri lati fi ẹhonu wọn han, ta si tun n gbọ iro ibọn kikankikan ladugbo naa.
Ọpọ mọto ti okuta ba ni gilaasi wọn fọ, tawọn ero to wa loju popo, paapa awsn to fẹ wọ ọkọ ero ati awọn to ni sọọbu soju titi n sa asala fun ẹmi wọn nigba ti aawọ naa fọnna soju.

Oríṣun àwòrán, Others
Ọkan lara awọn eeyan kan to n gbe ladugbo Iyana Ipaja salaye pe, inu ile lawọn wa lai fi Ọkada awọn sisẹ, nigba ti wọn osisẹ amusẹya ọhun wọ inu ile kan lọ lati gbe ọkada to wa nibẹ sita.

Oríṣun àwòrán, Others
Yanpọn-yanrin naa si ni ọwọja rẹ tan de awọn agbegbe to mule ti wọn bii Abule Ẹgba, tawọn ọlọpa amusẹya naa si n da afẹfẹ tajutaju si wọn loju.
Bẹẹ ba gbagbe, ijọba ipinlẹ Eko ti fofin de fifi ọkada ati kẹkẹ Maruwa se isẹ se lawọn oju popo kan nijọba ibilẹ mọkandinlọgbọn nipinlẹ naa.













