Cannabis: Akeredolu késí ìjọba Nàíjíríà láti fi òfin ti àmúlò igbó lẹ́yìn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ ẹgbẹ awọn dokita onimọ iṣegun oyinbo ni Naijiria, Adedayo Faduyile, ti fesi lori igbesẹ gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu lori sisọ gbigbin igbo ni Naijiria di nkan to ba ofin mu.
Nigba to ba BBC Yoruba sọrọ, Faduyile sọ pe lootọ ni awọn eniyan le lo igbo fun iwosan aisan kan tabi omiran, ṣugbọn asa lilo igbo lọna ti ko tọ ni a fi n sọ pe, ko yẹ ko wa ni awujọ.
"Ootọ ni nkan ti gomina Akeredolu sọ, ṣugbọn ibeere to yẹ ka bi Akeredolu ni pe, so ti da ileeṣẹ ti wọn yoo ti maa lo igbo silẹ, abi ti wọn ba bẹrẹ si ni i gbin, ta a lo fẹ lo?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nitori ko ti i si ileeṣẹ apoogun oyinbo kankan to wa ni Naijiria ti yoo nilo igbo, ti gomina n sọrọ nipa rẹ."
O tẹsiwaju lati gba gomina Akeredolu ni imọran pe, nkan to yẹ ko kọkọ ṣe ni lati da ileeṣẹ ti wọn yoo ti maa lo o silẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Laijẹ bẹẹ ko ni ṣanfaani, awọn eniyan yoo lo igbo ni ilokulo to ba pọ nilu. Eyi yoo si fa awọn iwa ti ko tọ."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìgbẹ́jọ́ aṣaájú ìjọ Sotitobire kúrò nílé ẹjọ́ Mágísíréètì lọ sílé ẹjọ́ gíga l‘Akure
- Ibùdó amúnáwá kan bú gbàmù n‘Ibadan, ni iná bá ṣẹ́yọ
- Saheed àti Fathia Balogun dìjọ ń ṣe ọjọ́ ìbí lónìí, ẹ wo àjọṣepọ̀ tó wà láàrin wọn
- Wo àtúpalẹ̀ ìlànà tuntun nípa gbígba físà Nàíjíríà tí Buhari gbé jáde
- Ọ̀pọ̀ nǹkan tí kò yé èmi àti Bàbá Wande, ló fa ìjà lórí sinimá Tolúwa Nilẹ̀ - Tunde Kelani
"Gbogbo awọn egboogi bi cocaine, heroine, ati bẹẹbẹ lọ lo ni iwulo ninu ipese awọn oogun oyinbo, ṣugbọn ilokulo wọn ni ko dara."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O ṣalaye pe, lootọ ko si aisan kan pato ti a le sọ pe igbo n wosan, ṣugbọn wọn maa n lo igbo tin-n-tin ni, gẹgẹ bi ọkan lara awọn eroja ti wọn n lo fun ṣiṣe awọn oogun naa.
Lọjọ Isẹgun ni iroyin sọ pe, gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ṣe ipade pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari lati jiroro lori gbigbin ati lilo igbo fun ṣiṣe oogun oyinbo l'orilẹ-ede Naijiria.
Oṣu Karun, ọdun 2019 ni gomina Akeredolu ti kọkọ kede pe, oun ati ọga agba ajọ to n ri si igbogun ti ilokulo oogun (NDLEA), Abdallah ti jọ kọwọrin lọ sorilẹede Thailand, lati kọ nipa aṣeyọri igbo gbingbin.
Gomina Akeredolu n tọka si i pe ipinlẹ Ondo lo n gbin igbo julọ ni Naijiria, to si yẹ ki orilẹ-ede yii o lo anfaani naa fun awọn ọmọ Naijiria.
Awọn orilẹ-ede mẹwa to n gbeero lati sọ igbo gbigbin din ọ̀rọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Yatọ si gomina Akeredolu to fẹ ki orilẹ-ede Naijiria o sọ igbo gbigbin di irinṣẹ ọrọ aje, awọn orilẹ-ede bi Lesotho, South Africa ati Zimbabwe ni awọn orilẹ-ede ilẹ Africa ti wọn ti n gbeero lati sọ igbo di ọ̀rọ̀.
Awọn yoku ni Uganda, Morocco, Ghana, Kenya, eSwatini ati Malawi.













