Orílẹ̀èdè Canada fọwọ́ sí kí wọ́n máa fi igbó sararindin

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ yìí ni orílẹ̀èdè Canada di orílẹ̀èdè tí yóò f'òfin se àtìlẹ́yìn kí àwọn ènìyàn rẹ̀ máa fi egbòogi olóró igbo se fàájì ara.
Bákan náà ní Australia, puerto Rico, Poland àti Czech Republic, Croatia ti Macedonia, wọ́n ń lò ó gẹ́gẹ́ bí ògùn òyìnbó.
Gẹ́gẹ́ bí àjọ ìsọ̀kan àgbáyé ṣe sọ ọ́, orólẹ̀èdè Nàìjíríà ni orílẹ̀èdè kẹta tó m'ókè jù nínú àwọn tó ń m'ugbó ní gbogbo àgbáyé.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Sùgbọ́n nílẹ̀ yìí, o léè f'ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ẹ̀dógún gbára bí wọ́n bá ká igbó mọ́ ọ lọ́wọ́.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
''Igbó máa ń mú mi ronú kíákíá''
Chuks, jẹ́ ọ̀dọ́ ọmọ Nàìjíríà kan tó ń gbé nílu Eko ó sì jẹ́ amugbó
Ó ní òun kò lè rántí ní pàtó ọdún tó bẹ̀rẹ̀ sí ni lo òògùn olóró yìí.
Marijuana ni àwọn olóyìnbó ń pe egbò igi igbó yìí, àwọn ọmọ Nàìjíríà a sì máa pè é ní Igbo. Ewéko gbígbẹ Cannabis ni o di ewé Marijuana.
Ó ní " bi òun kò bá mu oògùn lọ̀jọ kan, oúnjẹ kò kí ń hu ú jẹ kò ní fi se ẹni tó fi oúnjẹ náà ọ̀ ọ́.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀èdè míì ló ka igbó sí egbò igi olóró èyí tí kò tọ̀nà láti lò nítorí àwọn tọ́rọ̀ kàn ti tojú bọ̀ ọ́ pé bí o bá lò ó, ẹ̀hìn rẹ̀ kò dára rárá.
Dókítà Daniel Ajayi tó jẹ́ ọ̀gá àgbà nílé ìwòsàn tí wọ́n ti ń rí sí ààrùn ọpọlọ ní ìpínlẹ̀ Eko.
Ó ní àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ti wò ó fínífíní wọ́n sì rí i pé Cannabis jẹ́ ọ̀kan lára àwọn oògùn tó lè fa ààrùn ọpọlọ tó wọra fún ènìyàn. senior registrar for di Federal Neuro-Psychiatric Hospital for Lagos. E say sabi pipo don check am see say Cannabis na one of di drugs wey fit cause serious mental palaa for pesin.












