'Àwa la pa ọ̀dọ́mọdé olówó OOU àti olólùfẹ́ rẹ̀'

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police
Olólùfẹ́ méjì jọ gba ọ̀run lọ lọjọ kan náà nílé ìwé OOU.
Oriade Adebisi, ọmọ ọdún méjìlélógún kan tó jẹ́ ọmọ fásiti Olabisi Onabanjo tó wà ní Osu, Ipínlẹ̀ Ogun ń lọ kí ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní Oru-Ijebu pẹ̀lu olólùfẹ́ rẹ̀ Julian Imaga, nigba tí àwọn mẹéjééji di àwáti.
Fún bí ọ̀sẹ̀ méji ni àwọn ọlọ́pàá fi ń wá Adebisi ati Julian to jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún. Ṣugbọn lẹ́hin ìwádìí oríṣiríṣi tí ẹka iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tí a mọ̀ sí IRT ṣe, wọ́n rí òkú àwọn méjéèji nínú igbó kan ni Oru-Ijẹ̀bu.
Ní kété lẹyin ti ọlọpaa rii pe ololufẹ mejeeji ti re ọrun àrèmábọ̀ ni ìwádìí fojú àwọn méji tí wọ́n ní o pa àwọn olólùfẹ́ mejéèji han, tí ẹ̀ka IRT si gbé wọn lẹyẹ o sọka.
Olórí IRT fi atẹjade sita ní ọjọ́ Abamẹ́ta, ti wọn fi kede awọn oniṣẹ ibi to pa ololufẹ mejeeji.
Wọn ni Muritala Babatunde, to jẹ ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ni olórí ẹgbẹ́ òkùnkùn tí a mọ̀ sí Black Axe Confraternity ló ṣe ikú pa wọ́n.
Bakan naa ni wọn kede afurasí ọmọ ọdúin méjìdínlógun kan, Taiwo Rasak pe oun ní wọ́n jọ pa awọ́n ololufẹ naa.
Muritala Babatunde sọ fún àwọn ọlọ́pàá pé inú bí òun sí Adebisi nítorí kò ka òun sí gẹ́gẹ́ bíi ọkan gbòógi nínú ẹgbẹ́ okùnkùn ní agbègbè náà.
Ó tún sọ̀ pe Adebisi máa ń fún ẹgbẹ́ kan tó jẹ́ ọ̀tá ti òun ní owó déédéé.

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police
Ìwádìí ọlọ́pàá fi hàn pé l'ọjọ́ kéjìdínlọ́gbọ̀n, oṣu karùń ùn tí Adebisi àti Julian dàwáti, ni àwọn onisẹ ibi mẹ́ta ọhun yọ ìbọn sí wọn bí wọ́n ṣe kọrí sí ìyànà Oru, ti wọ́n si fi ipá gbé wọn lọ́ inú igbó.
Ẹ̀yin ilé kan tí won kò tíì pari ni wọ́n pa wọ́n sí.
Awọn afurasí náà ní póńpó àti ìbọn ni àwọn fi pa wọ́n. Wọ́n ní kí ọjọ́ náà tó dé, àwọn ti n ṣọ ìrìn Adebísí.

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police
A gbọ́ pé àwọn ọlọ́pàá ri ọkọ̀ Crosstour olóògbé náà, bàtà rẹ̀ àti fónù rẹ̀ gbà lọ́wọ́ àwọn afurasí nàá. Wán sì tún bá ibọn tí wọ́n fi ń ṣọsẹ́ lọ́wọ́ wọn.
Wọ́n ti gbé òkú àwọn méjéèjì lọ mọ́ṣúárì jẹ́nẹ́rà tó wá ní Ìjẹ̀bú.













