Àwọn ọlọ́pàá tó mú Evans 'ajọ́mọgbé' gbá igbega

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn ọlọ́pàá márùnlélógójì lábẹ́ ìdarí Abba Kyari tí wọ́n ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìdáhùn ní kíákíá sí ìpè pàjáwìrì (ITR unit) gba ìgbéga tuntun látàrí ìṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ti ṣe fún àjọ ọlọ́pàá pàápàá jùlọ nípa mímú àwọn ògbóǹtarìgì olè àti ajínigbé.
Ọ̀kan nínú ohun tí ó gbajúgbajà tí ó sọ àwọn ikọ̀ náà di ìlúmọ̀ọ́ká ni mímú Chukwudidumeme Onuamadike tí púpọ̀ èèyàn mọ̀ sí Evans ajínigbé.
Àmọ́ṣá, onírúurú àṣeyọrí ni àwọn ikọ̀ yìí ti ṣe sẹ́yìn, tó fi mọ́:
Gbígba ìyáa mínísítà fún ètòìṣúnáorílẹ̀èdè yìí nígbà kan rí, Ọ̀mọ̀wé Okonjo Iweala

Oríṣun àwòrán, Facebook/Abba kyari
Ikọ yìí bákan náà ló mú Godogodo tó ń dá ìlú Ìbàdàn rú

Oríṣun àwòrán, Facebook/Abba kyari
Ọmọ ìyá mẹ́ta tí ọmọ ọ̀dọ̀ jí gbé àwọn iko yìí bákan náà ló mú u

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bákannáà ni wọ́n lọ́wọ́ nínú bí wọ́n ṣe rẹ́yìn ògbójú ajínigbé tó ń jẹ́ Henry Chibueze tí àwọn ènìyàn mọ sí Vampire

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwárí àwọn ọ̀daràn tó bọ́ lọ́wọ́ ọlọ́pàá nipinle Kogi
Láìpẹ́ yìí, àwọn ikọ̀ yìí kan náà ni wọ́n ṣe àwárí àwọn ọ̀daràn tó bọ́ lọ́wọ́ ọlọ́pàá nípínlẹ̀ Kogi, tí wọ́n sì ń wá ojútùú sí ìkọlù àwọn adigunjale tó wáyé n'ilu Offa ni ìpínlè Kwara tí wọn sì ti mú àwọn kan tó nisẹ pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Oríṣun àwòrán, Abba kyari/facebook page












