Cannabis: Akeredolu, Ọgá NDLEA lọ kọ nípa gbíngbin igbo ní Thailand

igbo ati Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Akeredolu gbàgbọ́ pé ànfàní ńlá ni ṣíṣe ọ̀gbìn igbó yóò jẹ́ fún orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Gómìnà Akeredolu ti ipinlẹ Ondo oun ọga agba ajọ to n ri si igbogun ti ilokulo oogun (NDLEA), Abdallah ti jọ kọwọrin l orilẹede Thailand lati kọ nipa aṣeyọri igbo gbingbin.

Nigba ti BBC kan si Agbẹnus fun gomina Akeredolu, o ni bẹẹ ni ọga oun ati ọga ajọ NDLE wa ni orilẹede Thailand lọwọlọwọ.

Eto naa bẹrẹ lọjọ aje ọsẹ yii eyi to da lori ọna ti a le gbe gbin, gba iwe aṣẹ ati kikore igbo.

Nibi eto naa, Akeredolu ni oun dupẹ lọwọ ijọba ilẹ Thailand fun igbesẹ yii. O ni ipinlẹ Ondo ni wọn mọ si ipinlẹ to gbooro ju pẹlu gbingbin igbo.

Àkọlé fídíò, 'Bí ìrẹsì tèmi Ayinde bá ń pàkùta, kò tọ́ sẹ́nu aláàrù Barrymaade'

O ni " A wa lati kọ im nipa bi igbo gbingbin ṣe le ṣanfani fun ipinlẹ Ondo ati orilẹede Naijiria lapapọ gẹgẹ bi orilẹede Thailand ṣe ṣe e gẹ́lẹ́.

O ni fun iwosan ni wọn n lo igbo fun, ko si yẹ ki wọn maa lo o ni ilokulo.

Lara ẹkọ ti wọn lọ kọ yii, wọn ṣe ibẹwo si ibudo iṣewadii lori igbo ni fasiti orilẹede naa nibi ti gomina Akeredolu ti ni oun fẹ ki wọn ṣiṣẹ pọ pẹlu ipinlẹ Ondo.

Ọdun to kja ni oludije fu ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Action Congress, Omoyele Sowore naa da aba fifọwọ si ofin ti yoo gba tita igbo lọ silẹ okere lati Naijiria dipo ki wọn maa jo oko ọgbin Igbo.