Police arrest: Kà nípa ohun mẹ́wàá tí o ní láti ṣe bí ọlọ́pàá bá mú ọ

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG
Ileeṣẹ ọlọpaa ti bọ sita pẹlu awọn igbesẹ to yẹ fun araalu lati gbe lasiko ti awọn ọlọpaa ba fẹ mu wọn.
Ọrọ itaporogan laaarin araalu ati ọlọpaa lasiko ti wọn ba fẹ mu wọn ti di yanpọnyanrin ni ọpọlọpọ igba, koda o ti ja si iku fun ọpọ ti awọn miran si ti di alaabọ ara.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ileeṣẹ ọlọpaa ti wa fi si oju opo Twitter rẹ, igbesẹ ti o yẹ fun araalu ni gbigbe lasiko ti awọn ọlọpaa ba fẹ mu wọn.
"Nnkan lee di ariwo ati yanpọnyanrin lasiko ti awọn ọlọpaa ba fẹ mu eniyan. Koda o lee tọka si eniyan gẹgẹ bii onijagidijagan ẹda tabi ki o fun ọlọpaa ni ero pe onitọhun n gbimọran ati sa mọ ọlọpaa lọwọ ni."
Awọn igbesẹ ti ileeṣẹ ọlọpaa la silẹ niyi o:
Ma ṣe lo agidi lati lasiko ti ọlọpaa ba fẹ mu ọ:

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG
Boya igbesẹ ọlọpaa ba ofin mu tabi ko ba ofin mu, jọwọ ara rẹ silẹ fun wọn lai fa wahala rara.
Fi irẹlẹ beere idi ti ọlọpaa fẹ fi mu ọ:
Ẹtọ rẹ ni lati mọ. Bi awọn ọlọpaa naa ko ba si tun ṣe afihan ara wọn, beere fun idanimọ wọn ati ibi ti wọn ti wa.
Ọlọpaa ni aṣẹ lati ṣe awọn nnkan wọnyii:
- tu ile, aṣọ atawọn nnkan ini miran.
- ni oju opopona marosẹ, ọlọpaa lee ṣe ayẹwo ọkọ rẹ bi o ba wa ninu rẹ lasiko ti wọn da ọ duro.
- ọlọaa lee ni ki o kọ iwe 'wa wi tẹnu rẹ' (statement). Amọṣa, ẹtọ rẹ ni lati kọ jalẹ paapaa ti o ba ri pe kikọ iru iwe bẹẹ lee ko ọ sinu wahala.
- ọlọpaa lee ni ki o ṣe awọn ayẹwo kanbi ririn lori oju ila to gun kan. Eyi wa lati mọ boya o mu ọti tabi ogun oloro.
- ọlọpaa lee fi panpẹ ọba si ọ lọwọ bi wọn ba rii pe onijagidijagan ni ọ tabi o ṣeeṣe ki o fẹ salọ.
Jẹ ki ọlọpaa mọ ipo ailera rẹ lẹyin ti wọn ba mu ọ.

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG
Eyi ṣe pataki nitori bi o ba nilo itọju. Paapaa julọ awọn ti aisan semi-semi, ẹjẹ ruru, itọ ṣuga ati warapa n ba finra.
Beere fun iwe aṣẹ ofin lati mu ọ.
(amọṣa kii ṣe gbogbo ipe ọlọpaa lo nilo iwe aṣẹ ofin lati mu ọ) labẹ ofin ilẹ Naijiria, agbara pupọ n bẹ lọwọ ọlọpaa lati mu s ni ọpọ igba.
Rọ ọlọpaa naa lati gba ọ laye ki o pe ẹbi tabi ọrẹ rẹ kan tabi agbẹjọro rẹ ni kete lẹyin ti wọn ba mu ọ lati lee dena kiko ẹbi rẹ laya soke.
Bi o ba gba ki ọlọpaa naa o ṣe ayẹwo rẹ, beere fun iwe ofin to de ayẹwo naa.
(amọṣa kii ṣe gbogbo ipe ọlọpaa lo nilo iwe aṣẹ ofin lati yẹ ọ wo)
O lee beere pe ki o kọkọ yẹ ọlọpaa naa wo ki o to yẹ ọ wo
Eyi wa lati rii pe wọn ko di ẹru ti kii ṣe tirẹ le ọ lori.
Ma ṣe da ọlọpaa lọwọ duro bi wọn ba n fẹ mu elomiran.
O ko mọ bi ẹru ọran ti onitọhun da ṣe wuwo to.
Tẹle ọlọpaa naa de agọ wọn.
Eyi yoo fihan pe ọwọ rẹ mọ.














