#Segun: Kí ló mú akẹ́kọ̀ọ́ mu òògùn apakòkòrò tóríi máàkì 167 nínú JAMB?

Oogun apakokoro

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Segun fi fídíò ara rẹ̀ sórí ẹ̀rọ ayélujára bí o ṣe ní òògùn apakòkòrò náà dùn fi mu tíì.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Oludamọran kan lati ile Ẹkọ fasiti Joseph Ayo Babalola, ọmọwe Olaniyi Cecilia Mosunmola sọ pe pupọ ninu awọn obi lo lẹbi bi awọn ọdọ ṣe n gba ẹmi ara wọn.

O fi ọrọ yii lede ni idahun si ibeere lati ọwọ akọroyin wa nipa akẹkọọ ọmọ Naijiria kan to gbiyanju lati gba ẹmi ara rẹ pẹlu bi o ṣe mu oogun apakokoro nitori ko ṣe daadaa ninu idanwo aṣewọle iwe giga JAMB.

Lori ẹrọ ayelujara, akẹkọ naa ti orukọ rẹ n jẹ Ṣẹgun gbe awọn maaki rẹ to ti gba sẹyin ninu idanwo JAMB lati igba to ti n ṣe e sita.

Iye maaki ti eniyan ni kọ ni yoo ṣe atọna iru orire ti yoo ṣe laye

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba, onimọ naa ni iwa ki awọn obi ma fi ọmọ we ọmọ tabi maa fi awọn ọmọ ṣe yẹyẹ lori ijakulẹ idanwo ma n mu ki iru awọn ọmọ bẹẹ ba ọkan jẹ.

''Obi mi niṣe la maa fi ọmọ ṣe yẹyẹ pe gbogbo ẹgbẹ rẹ lo ti lọ si yunifasiti, iwọ leleyi to wa nibi. Iru ọmọ bẹẹ a ti ro ara rẹ pin''

Dokita Olaniyi sọ pe kaka ki awọn obi da iru ọmọ bẹẹ lẹkọ tabi ki wọn ṣe iwuri fun, niṣe ni wọn a maa ko iporuru ọkan ba wọn.

Onimọ naa tẹsiwaju pe awọn akẹgbẹ akẹkọ naa ni ipa ti wọn n ko ati pe ko yẹ ki eeyan sọ ireti nu lori ijakulẹ ninu idanwo.

O wa parọwa si awọn akẹkọ lati ma ṣe ba ọkan jẹ latari ijakulẹ ninu idanwo.

''Bi eeyan ṣe ni maaki to kọ ni yoo ṣe atọna iru orire ti yoo ṣe laye. Ẹni ti ko wọle si ile ẹkọ giga lọdun yii, ti o ba di ọdun to n bọ yoo wọle''

#Segun lori ayelujara

#Segun ti gbode loju ayelujara Twitter ti awọn iriwisi ọtọọtọ si ti n ba iṣẹlẹ yii wa.

Gẹgẹ bi ohun ti Segun sọ ninu fọnran fidio kan o ni ''bayi ti ohun ti ni ẹni ti yoo ṣe onigbọwọ ẹkọ ọfẹ fun oun ni ile iwe giga ni oun ko wa rọwọ mu ninu idanwo naa.''

O fi awọn maaki to gba ninu awọn idanwo to ṣe kọja sẹyin

2015 - 189

2016 - 202

2017 - 233

O ni igba yii ti awọn eniyan fẹ ran oun lọwọ lati kawe ni oun wa gba maaki mẹtadinlaadọsan (167).

Lo ba fi ikede sita loju opo Twitter rẹ pe oun yoo gba ẹmi ara oun.

Ikede to fi sita yii lo mu oju awọn ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria to ṣe asugba rẹ lọ si ile iwosan, Oluwafayokemi ni ilu Ijebu Ode, ni ipinlẹ Ogun.

Ṣugbọn lara awọn ọrẹ rẹ ti fi si oju opo Twitter pe, ara Segun ti n balẹ bayii.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post