Ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀: Wọ́n bá òkú afẹ̀sùnkan nínú ilé ìgbáfẹ́

Oríṣun àwòrán, @Asiwaju_limited/Twitter
"Ó digbere, mo maa ku laipẹ. O digba." ni ọ̀rọ̀ ikẹyin tí Michael Asiwaju ti àwọn ọmọbirin kan fi ẹsun ifipabanilopọ kan lori Twitter fi si oju opo Twitter tirẹ ni ọjọ Kejila oṣu kinni ọdun yii.
Ọrọ to mu idagbere rẹ yii wa nigba naa gba gbogbo ori ayelujara kan ni ọsẹ to kọja lẹyin ti oun ati awọn ọmọbirin kan n ta ohun sira lorii pe o fipa ba wọn lo pọ.
Nigba naa lo fi aworan awọn ọmọbirin ti o fẹsun kan pe wọn n bẹ oun lati bawọn ṣe ere ifẹ ki oun baa le fun wọn lowo han.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ileeṣẹ ọlọpaa Ipinlẹ Eko ni, ọrọ yii ki i ṣe lasan nitori wọn ti ba oku arakunrin naa ninu ile igbafẹ kan ni agbegbe Festac l'Eko nibi ti wọn ti funra pe o gbẹmi ara rẹ pẹlu oogun oloro Sniper ni.
Asiwaju ti inagijẹ rẹ n jẹ Mike Cash ni ileeṣẹ to n ṣe ijoko, Asiwaju Royal Furniture to wa ni Ojo, nilu Eko.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa Ipinlẹ Eko ni wọn n ṣe iwadii pe o ṣeeṣe ko jẹ pe o gbẹmi ara rẹ ni 'tori igo Sniper meji ti wọn ba ninu yara rẹ ninu ile igbafẹ naa.
Oga ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Edgal Imohimi ti ni ki awọn ọlọpaa gbe oku naa lọ mọṣuari, ki awọn ọlọpaa to n ṣe iwadi ipaniyan ati awọn to n lo imọ sayẹnsi si bẹrẹ iwadii lori ọrọ naa.
Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí













