Ìbálópọ̀ nínú ọkọ̀: Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko tako ìsesí yìí

Tọkọ taya

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ipinlẹ Eko ti tako ọrọ ile isẹ ọlọpa apapọ wi pe kii se ẹsẹ lati ni ibalopo ninu ọkọ ayọkẹlẹ ni ita gbangba.

Kọmisọnna ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Imohimi Edgal to fi eyi lede ninu atẹjade bu ẹnu atẹ lu ọrọ ti Ọga ọlọpaa Abayọmi Shogunlẹ sọ ni Ọjọ Isẹgun pe awọn ọmọ Naijiria lẹtọ labẹ ofin lati ofin lati ni ibalopọ ninu ọkọ ni ojutaye.

Edgal ni ile isẹ eto idajọ ni ipinlẹ Eko ti gba ile isẹ ọlọpaa ni imọran wi pe ohun itiju ati ohun to ba ni loju jẹ ni ki akọ ati abo ma a ba ara wọn ni ibalopo ni ita gbangba.

O fikun wi pe iwe ofin ipinlẹ Eko to nii se pẹlu iwa aito lawujọ sọ wi pe ẹni to ba wu iru iwa bẹẹ lawujọ yoo fi ẹwọn ọdun meji si mẹta jura gẹgẹbi iwe ofin to niise pẹlu iwuwasi lawujọ to wa ni Section 134 (a) ati section 136 ti iwe ofin ipinlẹ Eko.

Kọmisọnna ọlọpaa ipinlẹ Eko naa wa parọwa si awọn araalu ni ipinlẹ Eko lati se akiyesi ofin wọnyii, ki wọn ma ba A lu ofin ibalopo ni gbangba ni ọjọ iwaju.

Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ nínú ìbálópọ̀ nínú ọkọ̀ - Ọlọ́pàá

Igbakeji Kọmisana Ọlọpaa (ACP), Abayọmi Shogunlẹ lo kede loju opo ikansira ẹni Twitter rẹ pe kii se ẹsẹ rara fun awọn akọ ati abo lati ni ibalopọ ninu ọkọ nita gbangba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Òkè Ìdànrè: Òkè tó kéré jùlọ jẹ́ ẹsẹ̀ bàtà 3000

Shogunlẹ, ẹni to bo ọrọ yii loju boro, lasiko to n dahun ibeere kan ti ẹnikan ju si loju opo naa, fi kun pe, bi o tilẹ jẹ pe iwa ibalopọ ninu ọkọ ko sẹ si ofin Naijiria, sibẹ, awọn gbedeke kan rọ mọ isẹlẹ yii.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Gẹgẹ bo se wi, lara awọn gbedede naa ni iwọnyii:

  • Ibiti wọn ba gbe ọkọ naa si lati ni ibalopọ ko gbọdọ j ibudo ijọsin
  • Awọn akọ ati abo to fẹ ni ibalopọ ninu ọkọ naa ni ọjọ ori ọkọọkan wọn gbọdọ le ni ọdun mejidinlogun
  • Adehun to gunmọ gbọdọ ti wa laarin akọ ati abo to fẹ ni ibalopọ saaju lati se bẹẹ
  • Awọn mejeeji to fẹ ni ibalopọ ninu ọk gbọdọ jẹ akọ ati abo.

Shogunlẹ ko sai fi kun pe ti ẹnikẹni ba dun ikoko m ọmọ Naijiria kankan lori igbesẹ naa lẹyin ti wọn ba ti tle awọn ilana ofin to rọ mọ sise bẹẹ, ki wọn yara kan si ohun kia-kia.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Sugbọn lati igba ti Shogunlẹ ti n sọrọ yii, ni awn ọmọ Naijiria ti n gba ọrọ naa mọ ara wọn lọwọ, ti wn si n fi ero wọn han nipa rẹ loju opo Twitter wọn bẹẹ naa ni wn n fesi si ohun ti Shogunl sọ loju opo Twitter rẹ.

Bi awọn eeyan kan si se faramọ abala ofin naa ni awọn kan ta ko ofin yii

@Ibukun_olu, o ni bi o tilẹ jẹ pe ko si ofin kankan to tako ibalopọ ninu ọkọ loju taye, sibẹ, wọn lee gbe awọn eeyan to ba da asa yii wo pẹlu ẹsun aini iwa ọmọluabi.

O ni abala ojilerugba o din mẹsan ofin iwa ọdaran ilẹ wa lo sọrọ nipa awọn iwa kotọ lawujọ. O si wa lọwọ ileẹjọ lati sọ boya nini ibalopọ ninu ọkọnita gbangba jẹ iwa kotọ , paapa, taa ba wo wo ọkọ ti wọn lo jẹ dukia adani.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

@OsaAOsula, o dup pupọ lọwọ Shogunlẹ fun alaye to se lori ọrọ yii, amọ o wa n beere pe ki wa ni itumọ sisi ara silẹ lọna aitọ?

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

@PatrickOkouzi, iwa nini ibalopọ ninu ọkọ ni ita gbangba lee sokunfa ijamba ọkọ tabi iwa ajẹbanu, ko si yẹ ka gbaa laaye.

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5