Ìjọba Eko: Ìwàkuwà àwọn awakọ̀ ló ń fa ojú súnkẹrẹ ọkọ̀

Oríṣun àwòrán, AFP
Yoruba ni ilu ti ko si ofin, ẹsẹ ko si nibẹ, eyi lo mu kijọba ipinlẹ Eko fi n kede bayii pe awakọ to ba tapa sawọn ofin to de eto irinna loju popo, yoo ri ẹwọn ọdun mẹta he.
Adajọ agba nipinlẹ Eko, to tun jẹ Kọmisana feto idajọ, Adeniji Kazeem lo kede ọrọ yii fawọn kọlọransi awakọ pẹlu afikun pe gbogbo agbara ofin ni ijọba yoo lo lati da wọn lẹkun iwa ibajẹ loju popo.
Adeniji sọ siwaju pe ijiya ẹṣẹ awọn awakọ to ba sẹ si ofin irinna fun igba akọkọ, ni wọn yoo fi ẹwọn ọdun kan soso pere fa leti.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
"Ijọba Eko ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ifẹsẹmulẹ awọn ofin to de eto irinna loju popo, to si tun n lakaka lati mu ki ọkọ wiwa ni Eko ma mu wahala kankan lọwọ."
Adajọ agba naa ni ofin eto irinna loju popo tọdun 2015 lo laa kalẹ pe ijiya n bẹ fun awakọ to ba sẹ sawọn ofin yii:
- Kikọ lati mu ki ọkọ duro lawọn ibi to yẹ
- Gbigbe ọkọ duro lawọn ibi ti ko yẹ
- Fifi ake kọri lati duro si abala oju ọna tawọn adari ọkọ ba ni ko duro si
- Wiwa ọkọ lọna to doju kọ awọn ọkọ to n bọ tabi wiwa ọkọ ni abala ọna ti ko tọ si ọ lati gba
- Fifi ake kọri lati tẹle awọn ami to de eto irinna to wa loju popo.

Oríṣun àwòrán, AFP
Adajọ Adeniji wa mẹnuba awọn ijiya ẹsẹ to wa fun kọlọransi awakọ ti ọwọ ofin ba gba mu:
- Ẹni to ba tapa si ofin eto irinna nipinlẹ Eko fun igba akọkọ yoo padanu ọkọ rẹ fun ijọba tabi ko fi ẹwọn ọdun kan pere jura
- Ẹni to ba sẹ ẹsẹ naa ni igba keji tabi ju bẹẹ lọ yoo sare lọ fi ẹwọn ọdun mẹta jura tabi ko padanu ọkọ rẹ sọdọ ijọba
- Gbogbo awọn eeyan to ba sẹ si ofin irinna yii ni ijọba yoo fi akọsilẹ nipa wọn ati aworan wọn pamọ sori ẹrọ ayarabiaṣa.
Kọmisana feto idajọ naa wa rọ awọn ara ilu lati maa bọwọ fun ofin, ki wọn si maa fi ọwọ sowọpọ pẹlu awọn osisẹ to n se akoso eto irinna loju popo, ki alaafia lee jọba lawọn oju popo gbogbo ni ipinlẹ Eko.









