Kíni ìdí tí àwọn obìnrin tó wà nípò kò fi lágbára?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọrọ ariyanjiyan wi pe awọn ọkunrin wa nipo to lagbara lawujọ ju awọn ọkunrin lọ kii se ọrọ ẹyin.
Amọ ti awọn obinrin ba tun wa ni ipo to yẹ ki wọn wa tan, wọn a ma a fi ẹtọ wọn dun wọn.
Iwadii fihan wi pe, ọpọlọpọ orilẹede lo n gbiyanju lati ri wi pe ibasepọ to dan mọran wa laarin awọn ọkunrin ati obinrin, ati wi pe ori ko jori laarin akọ ati abo wa ni ibamu.
Amọ lọpọ igba ti awọn orilẹede wọn yii ba yan obinrin si ipo tan, wọn ko ni fun wọn ni owo to yẹ fun wọn gẹgẹbi ipo ti wọn dimu bii ti awọn akọ ẹgbẹ wọn.

Oríṣun àwòrán, @aishambuhari
Ni ọpọlọpọ orilẹede ni agbaye awọn obinrin wa ni ipo giga lẹnu isẹ wọn ati ni isejọba orilẹede wọn.
Awọn orilẹede ti wọn ti yan obinrin si ipo agbara
- Obinrin mẹfa laariin awọn adajọ mẹwa lo wa ni orilẹede France, amọ owo osu wọn kere sii ni.
- Lorilẹede Slovenia, Romania ati Latvia, obinrin jẹ meje laarin awọn adajọ mẹwa.
- Ni Bulgaria ati Namibia awọn obinrin lo wa ni ipo giga ni ile isọ iroyin wọn.
- Ni Rwanda ati Ethiopia, idaji awọn asofin ile igbimọ asofin lo jẹ awọn obinrin.
- Idaji awọn onimọ nipa imọ ẹrọ ni orilẹede Malaysia jẹ obinrin.
- Dokita onimọ ijinlẹ mẹfa ninu mẹwa jẹ obinrin lorilẹede New Zealand, ti marun ninu mẹwa awọn onimọ ẹrọ jẹ obinrin.
Bakan naa. awọn onimọ gbagbọ wi pe ohun to fa idagbasoke awọn obinrin lawujọ ni wi pe awọn ẹbi ati idile ti bẹrẹ si ni bu iyi kun awọn obinrin ati wi pe awọn obinrin ti bẹrẹ si ni ja fun ẹtọ wọn, ti wọn si n se daradara ni awọn isẹ ti wọn yan laayo.








