Alaafin: Ó wu àwọn ìyàwó mi ni wọ́n fẹ́ mi, èmi kọ́ ni mo dẹnu ìfẹ́ kọ wọ́n

Alaafin

Oríṣun àwòrán, alaafin_oyo/Instagram

Alaafin ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi, sọ pe oun ko kọnu ifẹ kọ obinrin kankan ri.

Ọba Adeyẹmi, ninu ifọrọwanilẹwo kan to ṣe pẹlu iwe iroyin Punch sọ pe, o wu awọn iyawo oun lati fi oun ṣọkọ nitori pe oun ran wọn lọ sileewe.

O sọ pe ''mo sọ fun wọn pe ki wọn ma a lọ, ṣugbọn wọn sọ pe awọn ṣa a fẹ duro ti mi l'aafin gẹgẹ bi iyawo mi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Alaafin Ọyọ: Asiri agbara bibi ibeji lọpọ igba

"Eyi to gboye imọ ijinlẹ to kere ju lọ ni iwe ẹri agba nileewe gbogboniṣe, Higher National Diploma (HND).''

Ọba alaye naa ṣalaye pe koda, ọrẹ ni iyawo oun akọkọ jẹ pẹlu aburo oun obinrin. Aburo rẹ naa lo si fi awọn mejeeji mọ ara wọn.

Àkọlé fídíò, Itan Ilu gangan

Alaafin ni ọpọlọpọ awọn ọdọbinrin ni Olori, ti awọn eniyan si maa n wo o pe kini awọn obinrin naa n ri ti wọn fi n fẹ ẹ.

Amọ Ọba Adeyẹmi ni Ọlọrun ran oun lọwọ lati tọ awọn iyawo oun, ati lati maa dari wọn lai jẹ wi pe igbeyawo naa tuka, tabi ki ija orogún o da ile oun ru.

Awọn orekelẹwa ayaba Alaafin tilu Oyo

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oba Lamidi Adeyemi III

''Mi o mọ bi wọn ṣe n lepa tabi dẹnu ifẹ kọ obinrin. Ohun kan ni pe, mo mọ bi mo ṣe n jẹ ki obinrin o pẹ lọwọ mi, paapa obinrin to rẹwa.''