Iléesẹ́ ológun: Amẹrika, Italy ń tìwá lẹ́yìn láti sẹ́gun Boko Haram

Oríṣun àwòrán, @NigeriaAirforce
Olori ileesẹ ologun ofurufu nilẹ Naijiria, Ọgagun Sadique Abubakar ti kede pe oun ti digba dagbọn lọ fi ijoko si ẹkun ila oorun ati iwọ oorun ariwa Naijiria, gẹgẹ bi asẹ ti aarẹ orilẹede yii, Muhammadu Buhari pa.
Ilu Kano ni Abubakar ti sisọ loju ọrọ yii pẹlu afikun pe ileesọ ologun ofurufu ilẹ yii tun n reti baalu mejila miran lati orilẹede Amẹrika yatọ si baalu mejidinlogun ti ijọba apapọ ra fun ileesẹ naa.
Abubakar ni orilẹede Italy ati Amẹrika ko da awọn da ogun ti awọn n gbe ti Boko Haram, ti wọn si n se atilẹyin alailẹgbẹ fun wọn loore koore.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mo fẹ́ ọkọ mi torí bó se ń kọrin, kìí se torí owó - Ìyàwó Aràrá
- Mo fẹ́ kí àyẹyẹ ìgbeyàwó mi dùn ni mo se bú sẹ́kún - Ọkọ ìyàwó ẹlẹ́kún
- Samuel Ladoke Akintọla jẹ́ Agbẹjọ́rò àti Akọ̀ròyìn tí ọ̀rọ̀ dá lẹ́nu rẹ̀
- Hubert Ogunde rèé, baba àwọn òsèré tíátà
- Ìyàtọ̀ wà nínú ìlépa àwọn òṣèré tíátà ayé àtijọ́ àti ìsisìnyí-Papalolo
"Ijọba apapọ naa ko kawọ gbera lori ọsẹ ti Boko Haram n se, tori o ti se atunto ileesẹ ologun ofurufu, ti ko si si idi kankan fawọn ọmọ ogun ofurufu lati mase run tapa titan wọn si ogun Boko Haram."
Olori ilees ọmọ ogun ofurufu tun fikun pe orilẹede Italy naa yoo fi baalu ijagun kekere mẹfa ransẹ sawọn laipẹ.

Oríṣun àwòrán, @NigeriaAirforce
Ko sai waa rọ awọn eeyan to ri jajẹ sẹku lawujọ, lati dide se atilẹyin tiwọn naa fun awọn ẹka ileesẹ ologun ilẹ wa, ki ogun Boko Haram lee di afiẹyin, ti eegun n fi asọ.









