Aminat Abiodun: Òun ni Iyalode kẹtàlá, tó sì ń gun àkàsọ̀ láti ọdun 1971

Oloogbe Aminat Abiọdun ati Oloogbe Abdulazeez Arisekọla Alao

Oríṣun àwòrán, Kola Carew

Oloye Aminat Abiọdun ti wa saye, to si ti di ero ọrun bayii, amọ o yẹ ka mọ iru eeyan ti obinrin takun-takun yii jẹ nigba aye rẹ.

Akọkọ, odun ni iyalode taa ba n sọrọ eto oselu, kii se aimọ fun oloko awọn oloselu, tori pe o jẹ ọkan gboogi lara awọn to lẹnu lori bi eto oṣelu ṣe n lọ nipinlẹ Ọyọ.

Gẹgẹ bi iyalode, oun ni oloye Obinrin ti o ga julọ ni igbimọ lọbalọba ilẹ Ibadan ni igba aye rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Adebisi Idikan: Òun ló gba Ìbàdàn sílẹ̀ lọ́wọ́ ìyà owó orí sísan

Awọn kan ti ẹ maa n pe Iyalode Aminat Abiọdun ni Ọbabinrin ilẹ Ibadan.

Ati owo, ọrọ ati agbara ni Iyalode ilẹ Ibadan fi ṣ'ọla., to si ri aye gbe ko to jẹ Ọlọrun nipe lọjọ ogbo rẹ.

Gẹgẹ bi Iyalode, o jẹ aṣoju awọn obinrin ninu igbimọ Olubadan.

Aminat Abiọdun ni iyalode kẹtala ti o jẹ ni ilẹ Ibadan. O si bẹrẹ si ni i gun akasọ oye l'ọdun 1971.

Aminat Abiodun, Iyalode Ibadan

Oríṣun àwòrán, Olatunji Babatunde

Àkọlé àwòrán, Gẹgẹ bi iyalode, ohun ni oloye Obinrin ti o ga julọ ni igbimọ lọbalọba ilẹ Ibadan

O bẹrẹ lati ori oye Jagun Iyalode, ko to o di pe o jẹ oye Iyalode lọdun kẹrindinnlọgbọn to bẹrẹ ọrọ oye ìlú.

Ni ọdun 2007 ni Alhaja Aminat Abiọdun gun ori oye iyalode ilẹ Ibadan, lẹyin iku Iyalode to gbesẹ, Oloye Wuraọla Akintọla.

Gbajugbaja oniṣowo pataki ni Iyalode Abiodun nigba aye yẹ.

Alagbara ati ajafẹtọ araalu ni gẹgẹ bii awọn aṣiwaju rẹ bi Iyalode Ẹfunṣetan Aniwura ati Humani Alaga.

Ko si si ibi ti o lọ ti kiiṣe ari-ma-lee-lọ awo pada sẹyin ni wọn n woo nitori ẹwa rẹ.

Ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹjọ, oṣu Kejila, ọdun 2018 ni Iyalode ilu Ibadan, Oloye Aminat Abiọdun jade laye.

Aminat Abiọdun, Iyalode ilẹ Ibadan jade laye

Iroyin ti o tẹ BBC News Yoruba lọwọ ṣalaye pe ni owurọ ọjọ naa ni Iyalode Abiọdun ju awa silẹ.

Gẹgẹ bii iroyin ti o tẹ BBC News Yoruba lọwọ ṣe sọ, ni ọjọ aiku ni wọn yoo sin oku Iyalode Ilẹ Ibadan, Aminat Abiọdun ni ilana ẹsin Musulumi

Àkọlé fídíò, Papalolo ní ìlépa owó ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn òṣèré tíátà àtijọ́ àti ìsisìnyí