Ogun PDP; Wàhálà tó n wáyé lórí ẹni tí yóò dúpò gómìnà kò tí ì d'ópin

Aworan Seneto Buruji Kashamu

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/Senator-Buruji-Kashamu

Àkọlé àwòrán, Lẹyin eto idibo abẹle PDP, ni Adeleke Shittu gba lati jẹ ki Buruji Kashamu di oludije ẹgbẹ.

Ede aiyede to n waye lori ẹni ti yoo dije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, ni ipinlẹ Ogun ko ti i dabi ẹni pe yoo dopin laipẹ.

Eyi ribẹ nitori bi Alaga ẹgbẹ naa, Ọmọọba Uche Secondus, ṣe gbe asia ẹgbẹ naa fun Họnọrebu Ọladipupọ Ọlatunde Adebutu gẹgẹ bi oludije ẹgbẹ naa, l'olu ile ẹgbẹ PDP to wa ni Abuja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lati igba ti eto idibo abẹle ẹgbẹ naa ti waye l'oṣu Kẹsan an, nitori idibo abẹle ọna meji to waye.

Igun akọkọ to jẹ ti Sikirullahi Ogundele, eyi ti awọn adari ẹgbẹ faramọ dibo yan Ladi Adebutu gẹgẹ bi oludije, nigba ti igun ti Adebayọ Dayọ n dari yan Adeleke Shittu ni oludije ti wọn.

Àwòran Ladi Adebutu

Oríṣun àwòrán, Facebook/LadiAdebutu

Àkọlé àwòrán, Igun akọkọ to jẹ ti Sikirullahi Ogundele, eyi ti awọn adari ẹgbẹ faramọ dibo yan Ladi Adebutu gẹgẹ bi oludije

Lẹyin eto idibo naa ni Adeleke Shittu gba lati jẹ ki Sẹnetọ to n ṣoju ẹkùn idibo Ila Oorun Ogun, Buruji Kashamu di oludije ẹgbẹ.

Lori igbesẹ ti Secondus gbe yii, amugbalẹgbẹ fun Kashamu lori eto iroyin, Austin Oniyokor sọ fun akọroyin BBC Yoruba, Yẹmisi Oyedepo, pe Buruji Kashamu ni ajọ eleto idibo INEC da mọ gẹgẹ bi oludije fun ipo gomina ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ogun.

Àwòran ìpolongo Sínátọ̀ Buruji Kashamu àti dókítà Reuben Abati

Oríṣun àwòrán, Facebook

Àkọlé àwòrán, Igun to daramọ Buruji Kashamu naa ti mu ọjọ ti wọn yoo gbe asia ẹgbẹ́ fun un.

Ati wi pe "wọn gbe asia ẹgbẹ fun ko sọ pe oun ni oludije. Asọ lasan ni wọn gbe fun, tori ofin ko da a mọ.

To ba wa a ṣeeṣe fun lati mu asọ naa lọ si ọdọ INEC lati sọ ọ di oludije tabi ile ẹjọ, ki wọn sọ ọ di tikẹẹti oludije fun."

Àkọlé fídíò, Saheed Oṣupa, Taye Currency sọ ibùdó ìpolongo ìdìbò Atiku di ibi àríyá

Nigba ta a bi boya ede aiyede wa ninu ẹgbẹ PDP l'Ogun, o sọ pe awọn kan ninu ẹgbẹ l'Abuja lo to ro pe awọn tobi ju ofin lọ, ohun lo mu wọn ti wọn fi n gbe igbesẹ to tako ofin.

"Ajọ INEC paapa ti sọ pe asẹ ti ile ẹjọ pa pe ipade ita gbangba ti Onimọ Ẹrọ Adebayọ Dayọ ṣe ni awọn faramọ. Wọn ko gba tikẹẹti lọwọ ẹni kan fun ẹnikan.

Pe awọn eniyan n dibo fun ẹgbẹ, eyi ko tumọ si pe ẹgbẹ gbọdọ maa ṣe nkan ti ko tọ ọ. Ẹgbẹ PDP l'Ogun lodi sofin lo fa gbogbo wahala yii, lẹyin idajọ ile ẹjọ.