Ìjọba Naijiria: Ọ̀rọ Olusẹgun Ọbasanjọ kò jọ wá lójú mọ́

Oríṣun àwòrán, @Atiku
Ijọba orilẹede Naijiria ti bu ẹnu atẹ lu ọrọ ti Olusẹgun Ọbasanjo sọ laipe yii pe ki se ọrọ ti awọn le fi esi si.
Aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹri, Olusegun Obasanjo laipe yii sọ wi pe oun ko sẹnurọ ninu idibo 2019 ati wi pe Aarẹ Muhammadu Buhari gbọdọ fi ipo silẹ ni idibo ọdun 2019.
Agbẹnusọ fun Aarẹ Buhari, Garba Shehu lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ni Abuja, sọ pe ko nii se pẹlu awọn ẹnikeni ti Ọbasanjọ ba dibo fun lọdun 2019.
Shehu ni igba akọkọ ko ni yii ti Olusegun Ọbasanjo yoo ma se segesege lati sọ ẹni ti yoo se alatilẹyin fun ninu idibo ọdun 2019.








