Obasanjo: Ìdùnnú ọmọ Nàìjíríà ló jẹ́ mí lógún ní 2019

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ nigba kan fun Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti sọ pe, ko si ọrọ ko gbona ko tutu lori ibi ti oun fi si lori eto idibo ọdun 2019.
Ọbasanjọ, ninu atẹjade kan ti oluranlọwọ rẹ lori eto iroyin, Kẹhinde Akinyẹmi fi sita sọ pe, Ọbasanjọ sọ ọrọ naa nibi ipatẹ ọja ilẹ Afrika to waye fun igba akọkọ nilu Cairo l'orilẹede Egypt,.
Ọbasanjọ ṣalaye pe oun tako ohun ti awọn ileeṣẹ iroyin kan fi sita nipa ọrọ ti oun sọ nibi ipade awọn ọmọ bibi ilẹ Owu, to waye nilu Iwo nipinlẹ Ọṣun laipẹ yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìbejì Oníbẹ̀mbẹ́ Òru tí kò yara wọn lẹ́yìn ọgọ́ta ọdún
- Ohùn ìjálá lásán ni mo fi ń pa ẹran nínú igbó - Ọdẹ Oníjàálá
- Mo fẹ́ ọkọ mi torí bó se ń kọrin, kìí se torí owó - Ìyàwó Aràrá
- Mo fẹ́ kí àyẹyẹ ìgbeyàwó mi dùn ni mo se bú sẹ́kún - Ọkọ ìyàwó ẹlẹ́kún
- Samuel Ladoke Akintọla jẹ́ Agbẹjọ́rò àti Akọ̀ròyìn tí ọ̀rọ̀ dá lẹ́nu rẹ̀
O ni pe 'botilẹ jẹ wi pe oun ko ni gbe oludije kan le wọn lori, imọran ti oun yoo gba awọn ọmọ Naijiria ni pe, ẹni ti yoo mu idagbasoke ati ayipada ba igbe aye wọn ju boṣe wa bayii lọ, ni ki wọn dibo fun."
Kẹhinde sọ pe, ọrọ ti Ọbasanjọ sọ yii ko tumọ si pe ko mọ iha ẹni to wa, bi ko ṣe pe 'ọdẹ tabi omugọ eniyan nikan ni ko ni mọ ibi to n lọ lasiko ti aijafafa, iwa ibajẹ, ailafojusun, aibọwọ f'ofin ati ṣiṣe ègbè n ba orilẹede rẹ jẹ.''
Ọbasanjọ, to ti fi atilẹyin rẹ han fun oludije fẹgbẹ́ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Atiku Abubakar sọ pe, ohun ti yoo ṣe awọn ọmọ Naijiria ni anfaani ni oun faramọ.
"O si daju wi pe bi iṣakoso Naijiria ṣe n lọ bayii kii ṣe oun to ṣanfaani fun awọn ọmọ Naijiria.''

Oríṣun àwòrán, @Atiku
Aarẹ nigba kan ri ọhun sọ pe, oun rọ awọn ọmọ Naijiria to ti ṣe sababi ohun to n bẹ nita lasiko yii, lati bọ sita, ki wọn si wa ayipada ti yoo ṣe wọn loore.
''Ṣugbọn ayipada yii ko le waye bi wọn ko ba ṣe n kankan, ti wọn si gba ki awọn ọta Naijiria maa tan wọn.
Ati pe bi wọn ko ba wa ayipada si iṣakoso to wa lasiko yii, ohun ti yoo ṣẹlẹ si Naijiria si lẹyin rẹ yoo buru ju boṣe wa lọ."













