Ìwé àdéhùn: Àwa olùdíje jẹ́ẹ̀jẹ́ láti se ìpolongo ìbò láì lọ́wọ́ ẹ̀sìn àti ẹ̀yà nínú

Oríṣun àwòrán, @MBuhari
Ajọ eleto alaafia nilẹ wa (National Peace Commission) NPC, ti gbe iwe adehun kalẹ fun awọn oludije ipo aarẹ ninu idibo ọdun 2019 lati fọwọsi.
Aarẹ Muhammadu Buhari ati awọn oludije kan fun ipo aarẹ ni wọn ti tọwọbọ iwe adehun naa bayii eyi to wa lati gba alaafia laye lasiko ibo.
Ninu iwe adehun naa lo ti foju han pe, igbimọ eleto alaafia nilẹ wa ti se ipade apero pẹlu awọn oludije fun ipo aarẹ naa, ti yoo waye losu keji ọdun yii.
Awọn ohun to jẹyọ ninu iwe adehun ti wọn fọwọsi:
- Awa oludije fun ipo aarẹ labẹ awọn ẹgbẹ oselu seto ipade apero ọlọjs kan eyi ti igbimọ eleto alaafia nilẹ wa se kokari rẹ.
- A tẹti, taa si jiroro papọ lori idi to fi yẹ kawa oloselu pese ayika to dara fun eto idibo ti ko ni lọwọ magomago ninu lọdun 2019
- A fẹnu ko lati tẹwọgba awọn ilana ti wọn fi se atọna eto idibo 2015 to fi gun rege, ta si fi ara wa jin fun awọn nkan wọnyii:
Awọn ohun tawọn oludije fẹnu ko le lori ninu iwe adehun ti wọn fọwọsi:
- A o gbe ipolongo ibo wa lori awọn ọrọ to se koko labẹ ijọba apapọ, ijọba ipinlẹ ati ijọba ibilẹ
- A ko ni fi ọrọ ẹsin, ẹya tabi ede sinu awọn ipolongo ibo wa, boya eyi ta se funra wa ni abi eyi ti awọn aseju wa se ni orukọ wa
- A o takete sawọn ọrọ, to lee sokunfa iwa jagidi-jagan, ka to seto idibo, lasiko idibo ati lẹyin rẹ, gẹgẹ bo se kan awọn ọrọ taa maa sọ ni ita gbangba, ikede ta ba n se, ati awọn ọrọ apilẹkọ wa
- A yoo ri pe awa ati ẹgbẹ oselu ta ti wa mu eto adehun ta fọwọsi yii lọkunkundun, eyi ti awọn ẹni ọwọ to jẹ eekan ilu lọkunrin, lobinrin gbe kalẹ, to fi ms awọn ọba alaye ati asaaju ẹsin to wa ninu igbimọeleto alaafia
- A se atilẹyin fawọn ileesẹ ijọba, to fi mọ ajọ eleto idibo atawọn ileesk agbofinro, ta ri pe wsn ko segbe sibikan
- Lati maa fọhun jade fi tako awọn ọrọ to lee bi ni ninu, ka si tun tako awọn iwa ipa lasiko ibo boya lati ọwọ awọn alatilẹyin wa ni abi lati ọdọ awọn ọmọ ẹgbẹ alatako.








