2019 Election: Èmi kìí se alárùn ọpọlọ, n kò lọ tọ́jú ara ní Gbagada

Babajide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu

Àkọlé àwòrán, Babajide Sanwo-Olu ni ṣaka lara oun dá

Olùdíje fún ipò gómìnà fẹ́gbẹ́ òṣèlú APC ní Ìpínlẹ̀ Eko Babajide Sanwo-Olu ti ṣojú abẹ ní kòó lórí ọ̀rọ̀ pé ó ti lọ fún ìtọ́jú ààrun ọpọlọ ni ilé ìwòsàn Ìpínlẹ̀ Eki tó wà ní Gbagada.

Sanwo-Olu ṣàlàyé pé, òun lọ sí ilé ìwòsàn ní Gbagada láti ran àwọn aláìní lọ́wọ́ ni, kìí ṣe wí pé òun lọ tọ́jú ara òun níbẹ̀.

O fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ lórí ètò kan láàrọ́ọ̀ Ọjọ́rú lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán ní ìlú Eko.

Ẹ rántí pé, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Eko Akinwunmi Ambode nígbà tó bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ nínú oṣù kẹsàn án sọ pé, Sanwo-Olu ti lọ ṣètọ́jú ara rẹ̀ rí ní ilé ìwòsàn náà nítorí ó láárùn ọpọlọ rí.

Olùdíje ẹgbẹ́ òsèlú APC àti PDP ń sòkò ọ̀rọ̀ síra wọn

Ojú rèé ìran rèé nílù Èkó bí àwọn olùdíje gbòógì fún gómìnà méjèèjì ṣe ń sòkò ọ̀rọ̀ sí àrà wọn lórí àtẹ̀jíṣẹ́ twitter.

Àkọlé fídíò, Femi Hamzat yẹ̀bá fún Sanwo-Olu ní ìdìbò abẹ̀lẹ̀ APC

Nínú ọ̀rọ̀ Jìmí Agbaje, ó ní nínú gbogbo ìfọ̀rọ̀wánilẹnuwò tí ó tí ṣe láti ọjọ́ yìí, Babajide Sanwo-Olu kìí gbórí yìn fú àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Eko bíkòse kíí ò máá dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tó ń pe ni asujú ẹgbẹ́ tó ó sì máa ń dúpẹ́ fún àànfaní ti wọn fún òun. O fí kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé Sanwo-Olu ò tó bẹ́ẹ̀ láti jade dupò gómìnà ìpínlẹ̀ Eko tíì baa ṣe pe wọn gbe lé àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Eko lórí.

Sanwo-Olu àti Jimi Agbaje

Oríṣun àwòrán, Babjide Sanwo-Olu

Àkọlé àwòrán, Olùdíje ẹgbẹ́ òsèlú APC àti PDP ń sòkò ọ̀rọ̀

Lẹ́yọọ ò sọka náà ní Babajíde ti dálohun , ó ké gbàjare sí àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Eko pe alátako òhún Jimi Agbaje ń gbìyanjú láti dóju ọ̀rọ̀ rú tí ó sì ń gbìyànjú láti fa ọ̀rọ̀ ti kò ní ìtumọ pẹ̀lú lóri ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwo ti òun ṣe níle iṣẹ́ amóhùnmáwòrán kan láàrọ̀ ànàá.