2019 Election: Atiku buwọ́lu àjùmọ̀se àdéhùn àlááfíà

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, other

Igbakeji aarẹ Naijiria nigba kan, to tun jẹ oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Atiku Abubakar ti bu ọwọ lu iwe adehun alaafia fun awọn oludije fun ipo aarẹ l'ọdun 2019.

Atiku ti ko lọ si ibi ti awọn alatako rẹ to jọ fẹ du ipo aarẹ ti bu ọwọ lu iwe adehun naa lọjọ Iṣẹgun nilu Abuja, lo ti buwọlu iwe naa bayi nibi eto kan ti igbimọ alaafia gbogboogbo ṣe ni Kukah Centre l'Abuja.

Lọgan to han si gbogbo eniyan pe Atiku ko kopa nibi eto akọkọ tawọn alatako rẹ ti buwọlu iwe adehun naa, ni awọn eniyan ti bẹrẹ si ni bu ẹnu ẹtẹ lu u fun kikọ lati kopa ninu eto pataki ọhun to wa lati ri i daju pe alaafia jọba lasiko eto idibo ọdun 2019.

Ẹgbẹ oṣelu rẹ, PDP, ni ifesi si aikopa Atiku di ẹbi ru awọn alakoso eto naa pe, wọn ko ranṣẹ si awọn, ṣugbọn ti alaga igbimọ naa, to tun jẹ Aarẹ ologun nigba kan fun Naijiria, Abdulsalami Abubakar, si sọ pe irọ ni, pe ' ko si oludije ti wọn ko fi iwe ipe ransẹ si.''