Ìdìbò ọdún 2019: Atiku Abubakar kò yóju síbi ìpàdé àjùmọse àláfíà

Buhari àti àwọn èèkàn ìlú

Oríṣun àwòrán, FGofficial

Àkọlé àwòrán, Ààrẹ Buhari tọ́wọ́bọ̀wé àláfìà

Ààrẹ Muhammadu Buhari, ti balẹ̀ sí International Conference Centre (ICC) Abuja ní bi ti ètò ìgbìmọ àpàpọ̀ lórí àlàfíà lórí ìdìbò àpapọ̀ ọdún 2019.

Ètò àpérò ọ̀hún ló mu àkójọpọ̀ gbogbo ẹgbẹ òṣèlú pàdé lójú kan náà níbi ti àwọn olùdíje ipò ààrẹ yóò ti ìfọwọ́sí ìwé àdéhùn àláfíà.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Ètò Atiku ló bá èròngbà Yorùbá mu
Buhari àti àwọn èèkàn ìlú

Oríṣun àwòrán, FGofficial

Àkọlé àwòrán, Ààrẹ Buhari tọ́wọ́bọ̀wé àláfìà

Olùdíjé lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP Atiku Abubakar kò yọjú níbi ìfọwọ́wọ́sí àjùmọ̀se àláfíà náà bákan náàni olóri égbé òṣèlú PDP Uche Secondus.

Ọ̀rọ̀ náà kò yé, idí ti Atiku àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP ṣe kọ̀ láti yọjú níbí ayẹyẹ náà

Ìfọwọ́sí ìwé àjùmọse àláfíà yìí jẹ ohu ti ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà kan rí Abdulsalami Abubakar gbé kalẹ̀ láti ríi dájú pé olùdíje àti ẹgbẹ́ òṣèlú wọn kò sọ̀rọ̀ tako ẹ̀sìn, àti ẹya tò fi mọ lílo èdè tó le dá rògbòdiyàn sílẹ̀.

Bákan náà, ìwé àdéhùn alafíà yìí yóò tun mú ìrẹ́pọ̀ wáyé láàrin àwọn olùdíje sípò ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ríi dájú pé kò sí ìwà ipá tàbí jàgídíjàgan lásìkò ìpolongo, lásìkò ìdìbò àtí tí ìdìbò ọdún 2019 bá kẹ́sẹjári tan.

àwọn ori ade ati ààrẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, FGofficial

Àkọlé àwòrán, Ìdìbò dún 2019: Àwọn ààrẹ tọwọ́bọ̀wé àdéhùn àláfíà

Lọ́dun 2015, irú ìwé àdehun yìí náà wáye tí spọ̀ sì gbàgba pé ó kún ìdí ti ohun gbogbo ṣe lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀ lẹ́yín ìdìbò tí ààrẹ ìgbà náà tí Goodluck Jonathan gbà pé òun fìdi rẹmi.

Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, FGofficial

Àkọlé àwòrán, Ìdìbò dún 2019: Àwọn ààrẹ tọwọ́bọ̀wé àdéhùn àláfíà

Ẹ̀wẹ̀, ààrẹ Nàìjíríà nígbà kan rí Abdusalami Abubakar sọ pé àìwá ọ̀kan gbòógì nínú àwọn olúdíje sí ipò ààrẹ kò mú ìdíwọ́ kankan dáni sí fún àjùmọse àláfíà.