CBN: Kò sí owó tó sọnù ní banki àpapọ̀ Naijiria

Oríṣun àwòrán, WIKIPEDIA
Banki apapọ lorilẹede Naijiria, CBN ti sọ wi pe ko si owo to sọnu ni banki apapọ, lẹyin ti fọnran kan gbe e jade wi pe wọn ji ẹẹdẹgbẹta bilioọu Naira ni apo ijọba.
CBN lori ẹrọ ikansiraẹni Twitter wọn bu ẹnu atẹ lu fọnran naa wi pe ko si owo to sọnu ni apo banki apapọ Naijiria.
Amọ, fọnran naa gbe jade wi pe Gomina CBN, Godwin Emefiele pẹlu igbakeji ati adari eto isuna ni ẹka banki apapọ lori ọna ti wọn yoo gba fi di owo ti wọn ji ni apo ijọba ti ko ni fi ba eto ọrọ aje orilẹede Naijiria jẹ.









