Sowore: Èmi ṣì ni alága ẹgbẹ́, kò sẹ́ni tó yọ mí lóyè

Oríṣun àwòrán, omoyele
Ẹgbẹ oṣelu AAC ti le akọwe apapọ ẹgbẹ oṣelu naa, Leonard Ezenwa kuro lẹyin ti wọn ni o ṣiwaju igbesẹ yiyọ alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu naa, Ọmọyẹle Ṣoworẹ ninu ẹgbẹ naa.
Ninu atẹjade kan ti Ṣoworẹ fi sita ni ọjọ aje, o ni ẹgbẹ oṣelu naa ti kọkọ paṣẹ lọ rọọ kun nile naa fun ọgbẹni Leonard Ezenwa lori awọn ẹsun to rọ mọ ṣiṣe owo ẹgbẹ baṣubaṣu atawọn ẹsun ṣiṣe lodi si eto ẹgbẹ oṣelu naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
"Awọn ọmọ ẹgbẹ wọnyii, ti Leonard Ezenwa , akọwe apapọ ẹgbẹ yii tẹlẹ ti wọn paṣẹ lọ rọọ kun nile fun lori awọn ẹsun to rọ mọ ṣiṣe owo ẹgbẹ baṣubaṣu , ko sodi ti fihan pe awọn ko ni ipin ninu awọn ilana ati ohun ti ẹgbẹ oselu African Action Congress duro le.
"Nipasẹ bẹẹ, a ti le Leonard Ezenwa kuro ẹgbẹ oṣelu yii, gbogbo awọn kọlọransi ọmọ ẹgbẹ to kopa ninu ipade to waye nilu Abuja naa ni a ti paṣẹ lọ rọọkun nile titi di igba ti iwadi ba pari lori ipa ti koowa wọn ko."
Ni owurọ ọjọ aje ni Ezenwa kede lori mohunmaworan pe wọn ti yọ Ṣoworẹ nipo gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ oṣelu naa. O fi ẹsun kan Ṣoworẹ pe o kuna lati ṣeto ipade oloṣu mẹta-mẹta igbimọ adari ẹgbẹ oṣelu naa pẹlu ẹsun ṣiṣe owo ẹgbẹ baṣubaṣu.
Omoyele Sowore tii ṣe oludije fun ipo aarẹ ati alaga igbimọ ẹgbẹ oṣelu African Action Congress (AAC) fesi pé òun ṣi ni alaga ẹgbẹ oṣelu AAC.
Eyi jẹ idahun rẹ si iroyin to n ta kalẹ pe ẹgbẹ jawe lọ sinmi fun un.
Ẹwẹ, nigba ti BBC Yoruba kan si Sowore, o ni oun ṣẹṣẹ n gunlẹ lati irinajo kan ni pe oun yoo tun ba BBC sọ ẹkúnrẹrẹ ọrọ laipẹ ṣugbọn ni toun, oun ṣi ni alaga ẹgbẹ.
Laipẹ ni iroyin jade pe igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu AAC ti jawe lọ simi fun Omoyele Sowore to jẹ alaga wọn.
Gẹgẹ bi igbimọ alaṣẹ ṣe sọ ọ, wọn ni ki Sowore lọ simi latari ẹsun ṣiṣe ohun to lodi si ofin ẹgbẹ, ṣiṣe owo baṣu baṣu ati pe o kuna lati pe ipade igbimọ.
Ni kia mọṣa si ni wọn ti yan adele alaga, Leonard Nzewanu ti wn si ti bura wọle fun un.
Bakan naa, ẹgbẹ oṣelu AAC kede pe siso iṣẹ Sowore gẹgẹ bi alaga atawọn ọmọ ẹgbẹ mii rọ bẹrẹ lati ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹta ọdun yii ti yoo si wa fun oṣu mẹfa ayafi ti ipade apero gbogbo ti ẹgbẹ ba ṣasugbaa iyipada rẹ.















