TCN, ní kò s'óhun tí yóò ṣe iná mànàmáná ní Nàìjíríà lóní

Ajọ to n pin ina ọba lorilẹede Naijiria, TCN ti ṣalaye fun BBC News pe iroyin ti awọn kan n gbe kiri pe ina ọba yoo lọ kaakiri orilẹede Naijiria lọjọ aje, ọjọ kẹtala oṣu karun ko lee waye.
Ileeṣẹ TCN ṣalaye ọrọ yii lasiko to n fesi si ihalẹ awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC ti wọn ni awọn yoo da họwuhọwu silẹ laggo ipese ina ọba nitori ẹsun ti wọn fi kan ileeṣẹ TCN pe o n fi iya jẹ awọn oṣiṣẹ rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Alukoro fun ileeṣẹ to n pin ina ọba lorilẹede Naijiria, TCN, Ndidi Mbah ni awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC lapapọ lo n ṣe kokari ifẹhonu han naa,eleyi to ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣiṣẹ naa to wa ni ileeṣẹ to n pin ina ọba, TCN gangan ti ọrọ naa gbe ru gbọn-gbọn-gbọn ko fara mọ.
O ni lootọ ni iwọọde naa n lọ lọwọ lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ ṣugbọn awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa to jẹ ọmọ ẹgbẹ ileeṣẹ to n pin ina ọba lorilẹede Naijiria ko jade lati kopa ninu iwọde ọhun.

"awọn oṣiṣẹ ni ileeṣẹ yii ko fara mọ apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ naa lori ifẹhonu han wọn naa. Koda, iwọde naa ko tu irun kan lara ijafafa iṣẹ ni ileeṣẹ yii nitori naa ko si ohun to jọ pe ina ọba yoo lọ kale-n-kako lorilẹede Naijiria loni."
Ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC to jẹ agbarijọpọ ẹgbẹ oṣiṣẹ n lọ kaakiri lati ti ilẹkun awọn ileeṣẹ to n pin ina mọnamọna lorilẹede Naijiria, TCN kaakiri orilẹede Naijiria lori ẹsun pe o n fi iya jẹ awọn oṣiṣẹ rẹ.













