Sotitobire: Àwọn ọmọ ìjọ yarí, wọ́n ní ejò lọ́wọ́ nínú lórí ìdájọ́ tí wọ́n dá fún Alfa Babatunde

Alfa Babatunde ati awọn ọmọ ijọ rẹ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọrọ ko tii tan lori idajọ ẹwọn gbere ti ileẹjọ giga niluu Akure da fun pasitọ ijọ Sotitobire Praising Chapel, Alfa Babatunde lẹyin tawọn ọmọ ijọ rẹ tako idajọ naa.

Adajọ Olusegun Odusola ni Babatunde jẹbi ẹsun igbimọ pọ lati ji Kolawole Gold, ọmọ ọdun kan to di awati nile ijọsin naa niluu Akure lọdun 2019.

Awọn ọmọ ijọ Sotitobire to ba BBC sọrọ sọ pe inuni-bini wolii ijọ Sotitobore tawọn eeyan kan n ṣe lo jẹ ileẹjọ dajọ ẹwọn gbere fun un.

Wọn ni Wolii Babatunde ko mọwọ ko mẹsẹ nipa ọrọ to ṣẹlẹ ọhun, koda wọn ni ko si ninu ile ijọsin naa nigba ti iṣẹlẹ naa sẹlẹ.

''Wọn lọ si ile rẹ lati wa bo ya ọmọ naa wa nibẹ, koda wọn wo pata obinrin ti wọn nile rẹ, ṣugbọn wọn ko ri nkankan, idajọ yii kudiẹ kaato,'' ọmọ ijọ Sotitobire kan lo sọ bẹẹ.

Elomiiran to tun jẹ ọmọ ijọ naa sọ pe ọpọ eeyan lo yabo ṣọọṣi Sotitobire lẹyin ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ tan, o ni awọn eeyan naa sọ ina ṣọọṣi wọn si ba ṣọọṣi naa jẹ.

Wọn ni ko si ẹni to le fidi ẹsun ijọmọgbe ti wọn kan alufaa Babatunde mulẹ, wọn ni awọn mii tiẹ sọ pe pasitọ ọhun ri ọmọ naa mọlẹ laaye ni.

Amọ wọn ni ko si ẹni to ni ẹri to daju to le fihan pe alufaa Babatunde jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Alufaa Babatunde atawọn ọmọ ijọ marrun un mii ni adajọ Odusola dajọ ẹwọn gbere fun un lọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹfa oṣu kẹwaa ọdun 2020.

Ìdájọ́ ẹ̀wòn gbére kò ní kí Wòlíì Sotitobire má lọ sí ilèẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn - Agbẹjọ́rò Pásítọ̀ Alfa Babatunde

Skip Facebook post, 1

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post, 1

Alfa Babatunde
Skip Facebook post, 2

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post, 2

Agbẹjọro to n ti n gba waju gba ẹyin fun Pasitọ Alfa Babatunde ti ijọ Sotitobire Praising Chapel, Akinyemi Omoware ti ṣalaye ọrọ fun araye gbọ pe onibara oun ṣi lanfani ati gbà ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ lẹyin idajọ.

Ṣaaju nigbati igbẹjọ naa ṣẹṣẹ bẹrẹ lowurọ ọjọ Iṣẹgun ni adajọ ti yọnda fun agbẹjọro naa ko ṣe gaafara fun awọn ninu ile ẹjọ nigba tọrọ fẹ di aawọ laarin oun atirẹ.

Idi ni wipe agbẹjọro Sotitobi rẹ ke pe adajọ pe ko sun igbẹjọ naa siwaju eyi to ti waye lọpọlọpọ igba tawọn eeyan si ti n reti idajọ ikẹyin'

Ni adajọ ba ni lai lai, oun ko ni sun ẹjọ siwaju mọ. Lẹyin eyi agbẹjọro Sotitobire bọ ẹwu ofin to si jade nile ẹjọ.

Ẹwẹ, nigbati adajọ si ti da ẹjọ ẹwọn gbere fun un tan, agbẹjọro rẹ nigbati BBC Yorba fi ọrọ wa a lẹnu wo jẹ ko di mimọ pe, ìdájọ́ ẹ̀wòn gbére kò ní kí Wòlíì Sotitobire má lọ sí ilèẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.

Àkọlé fídíò, Ondo Elections 2020: Ọgọ́rùn-ún ọdún tí a máa lò lórí oyè l'Ondo, ẹ ó rí àrà - Ojon YPP
Àkọlé fídíò, Àwọn kan ṣónú bí wọ́n bá di gómìnà, ẹ fún wa láyè láti wá parí iṣẹ́ táa bẹ̀rẹ̀ - Akeredolu

Adájọ́ sọ wòlíì Sotitobire àtàwọn márùn-ún míì sẹ́wọ̀n gbére!

Adajọ Olusegun Odusola, tile ẹjọ giga ilu Akure ti kede pe asaaju ijọ Sotitobire, Wolii Alfa Babatunde jẹbi ẹsun ijọmọgbe.

Bakan naa lo ni awọn eeyan marun yoku ti wọn n jẹjọ pẹlu rẹ, naa jẹbi sise onigbọwọ jiji ọmọ ọdun kan naa, Gold Kolawole gbe, ni ọdun to kọja.

Nigba to n gbe idajọ oniwakati marun ati abọ rẹ kalẹ, lori ẹsun ijọmọgbe onikoko mẹfa, adajọ Odusola ni ijọ Sotitobire ko kọbi ara si isẹlẹ bi ọmọ naa, se di awati lasiko ijọsin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, 'N500 dé fún gbogbo ọmọ tuntun lóṣooṣù bí mo bá di gómìnà Ondo - Adeleye AAC

Adajọ ni se ni ijọ naa n tẹ siwaju lati maa ba isin ọjọ isinmi wọn lọ titi di aago marun irọlẹ lẹyin ti wọn ti ji ọmọdekunrin, ọmọ ọdun kan naa lọ lati ọwọ ọsan.

Alfa Babatunde ati awọn afurasi miran ninu ile ẹjọ

Adajọ wa gbe idajọ kalẹ pe, awọn olujẹjọ kinni de ikẹfa ninu ẹjọ naa, jẹbi ẹsun iditẹ lati ji ọmọ gbe ti wọn fi kan wọn.

Bẹẹ ba si gbagbe, Wolii Alfa Babatunde, tii se adari ijọ Sotitobire ni afurasi ati olujẹjọ akọkọ ninu ẹjọ ọhun.

Adajọ tẹsiwaju pe awọn ọlọpaa gan ni ọwọ wọn ko mọ lori isẹlẹ yii, ti a ba wo ọwọ ti wọn fi mu isẹlẹ naa, to si bu ẹnu atẹ lu bi wọn se na iya iya ọmọ ti wọn n wa naa, ti wọn si tun ti mọle, lai jẹ pe wọn gbe wa sile ẹjọ.

Alfa Babatunde ati awọn afurasi miran

Nigba to n gbe idajọ kalẹ lori ẹsun sise onigbọwọ lati ji ọmọ gbe, adajọ Odusola ni awọn olujẹjọ kinni de ikẹfa jẹbi ẹsun naa

Nigba to n yiiri ẹsun kẹta wo, tii se biba awọn ẹri to se koko nipa ẹjọ naa jẹ, adajọ ni ki olujẹjọ keje, Peter Anjorin maa lọ sile ni alaafia, tori ko jẹbi gbogbo awọn ẹsun ti wọn fi kan rara.

Wọ́n ń ka ìdájọ́ Wòlíì Sotitobire lọ́wọ́ báyìí nílé ẹjọ́ l'Akure

Ni yajo yajo bo ṣe n tẹ wa lọwọ lati ipinl Ondo ni pe agbẹjro Alfa Babatunde Sotitobire iyẹn Bayo Ayenakin ni oun yọ ọwọ ninu igbẹjọro to yẹ ko waye lonii.

O fẹrẹẹ dabii fa ki n fa laarin oun ati adajọ. O ni oun ko ni le maa farahan siwaju sii lori ẹjọ naa tori wipe adajọ kọ lati sun ẹjọ naa siwaju.

Sotitobire

Agbẹjọro kọkọ pe fun ki wọn sun ẹjọ naa siwaju lonii lori oun to pe ni aridaju mẹrindinlogun ṣugbọn adajọ faake kọri to si fagile ipẹjọ rẹ.

O ti wa fun adajọ Ayenakin ni gaafara lati bọ ẹwu rẹ ko si kuro nile ẹjọ niwọn igba ti ọrọ ko ti wọ.

Ile ẹjọ Akure

Yoruba ni bi a ba da ọjọ, ọjọ a pe, bi a ba da osu, osu a ko, bo pẹ titi, ogun ọdun n bọ wa ku ọla

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu igbẹjọ Wolii Alfa Babatunde, ti ijọ Sotitobire nilu Akure, ẹni to n koju ẹsun ijinigbe lati ọdun kan ati osu diẹ sẹyin.

Àkọlé fídíò, 'N500 dé fún gbogbo ọmọ tuntun lóṣooṣù bí mo bá di gómìnà Ondo - Adeleye AAC

Iroyin to wa n tẹ BBC Yoruba lọwọ ni yajoyajo ni pe, ọjọ Kẹfa osu Kẹwaa ọdun 2020, ni wolii naa yoo mọ ibi ti ori n ba ẹsẹ rẹ ree.

Awọn agbẹjọro ti ji de ile ẹjọ bẹẹ si ni ile ẹjọ ti kun fọfọ.

Idi ni pe lọla ode yii ni idajọ yoo waye nile ẹjọ giga ilu Akure lori ẹsun ijọmọgbe ti wọn fi kan Alfa Babatunde ati ọmọ ijọ rẹ mẹfa miran.

Alfa Babatunde ati awọn afurasi miran n jade kuron inu ile ẹjọ lọ

Kọmisana feto idajọ ati agbẹjọro agba nipinlẹ Ondo, Adekola Olawoye lo fidi ọrọ yii mulẹ fawọn akọroyin pẹlu afikun pe lọla ọde yii ni Adajọ Olusegun Odusola, to n gbọ jọ Sotitobire yoo gbe idajọ rẹ kalẹ.

Olawoye ni aago mẹsan owurọ, lọjọ Isẹgun ni idajọ naa yoo maa waye nile ẹjọ giga ilu Akure.

Ọkan lara awọn agbẹjọro

Bẹẹ ba gbagbe, lọdun to kọja ni iroyin gba ilẹ kan nilu Akure pe ọmọ ọdun kan, Gold Babatunde di awati lasiko to wa ni ijọ awọn ọmọde inu ijọ Sotitobire nilu Akure.

Alfa Babatunde ati awọn afurasi miran n wọ inu ile ẹjọ lọ

Gbogbo igbiyanju lati sawari ọmọdekunrin naa si lo ja si pabo, ti awọn agbofinro si mu wolii naa, atawọn ọmọ ijọ rẹ mẹfa lori ẹsun ijọmọgbe

Bi igbẹjọ ba se n waye lọjọ Isẹgun, ni BBC Yoruba yoo maa mu wa fun yin.

Awọn adajọ