Sotitobire: Ìdájọ́ òdòdò ló fẹsẹ̀ múlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Pásítọ̀ Sotitobire - Agbẹjọ́rò fún ìjọba

Àkọlé fídíò, Ìdájọ́ òdòdò ló fẹsẹ̀ múlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Pásítọ̀ Sotitobire - Agbẹjọ́rò fún ìjọba

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 ni ile ẹjọ giga ti ijọba ipinlẹ Ondo dajọ ẹwọn gbere fun Alfa Babatunde, to jẹ oludasilẹ ijọ Sotitobire Praising Chapel, ati awọn ọmọ ijọ rẹ marun, ti wọn fi ẹsun kan pe wọn lọwọ si bi ọmọ ọdun kan, Gold Kolawole ṣe di awati ninu ijọ naa ni ọdun 2019.

Bo tilẹ jẹ pe agbẹjọro fun ijọba ipinlẹ Ondo lori ẹjọ naa, Adekola Olawoye, sọ pe idajọ ododo lo waye lori ọrọ naa, nitori pe "bi irọ ba lọ logun ọdun, ọjọ kan ni otitọ yoo ba".

Amọ agbẹjọro to ṣoju awọn olujẹjọ, Akinyemi Omoware, sọ fun BBC pe awọn yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ ile ẹjọ giga ọhun.