Ondo Election 2020: Eyitayo Jegede bu ẹnu àtẹ́ bí Akeredolu ṣe ń ṣejọba lọ́wọ́lọ́wọ́

Àkọlé fídíò, Ojú àwọn èèyàn Ondo ti là pé ìnira ni ẹgbẹ́ APC mú wá - Jegede PDP

Eyitayo Jegede ni oludije dupo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ninu idibo sipo gomina ti yoo waye ni ipinlẹ Ondo ni Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Kẹwaa, ọdun 2020.

O ṣalaye idi ti o fi yẹ ki awọn eeyan yọwọ ẹgbẹ oṣelu APC lawo iṣejọba Ondo lasiko yii.

O ni lati igba ijọba ti oun ṣiṣẹ fun gẹgẹ bii amofin agba titi to fi dori ijọba Olusegun Mimiko to gbeṣẹ le Rotimi Akeredolu to wa nibẹ bayii lọwọ lawọn ti sọ pe owo ileewe ko gbudọ ga ju N35,000 si N45,000 lọ.

"A fẹ ki awọn ọmọ mẹkunu, atawọn ọmọ to ba wu atawọn ti ko tilẹ ki n ṣe ọmọ Ondo ni anfani lati lọ ileewe giga fasiti".

O bu ẹnu atẹ lu bi ijọba Akeredolu ṣe n ṣe ọrọ eto ẹkọ, eto ilera atawọn ẹka mii lasiko yii eyi to fi ẹkọ we eto ẹkọ to nira fun awọn ọmọ ati iwosan olowo gọbọi.

O ni wọn bẹgi dina irọrun ẹkọ fawọn ọmọ toripe awọn ọmọ tiwọn o si ni ileewe kankan ni ipinlẹ Ondo.